Kí ló dé tí ìjọba Amẹ́ríkà pàṣẹ fún 'Ambassador' rẹ̀ ní Nàìjíríà láti padà sílé?

Oríṣun àwòrán, Collage
Ààrẹ Donald Trump tilẹ̀ Amẹ́ríkà ránṣẹ́ pé aṣojú orílẹ̀èdè náà to wa nílẹ̀ Nàìjíríà, Richard Mills, pé ko ko aasa rẹ kúrò nílẹ̀ Nàìjíríà, kò sì padà sílè.
Igbesẹ náà sì lo jẹ ara isiporọpo nla to n waye lọ́wọ́ nílẹ̀ Amẹ́ríkà.
Ìròyìn náà ni ó lè ní orílẹ̀èdè bíi mẹ́rìnlélógún tí isiporọpo náà kan àmọ́ ọ̀pọ̀ wọn lo wa nílẹ̀ Áfríkà.
Àwọn orílẹ̀èdè tí isipopada náà kan ni agbaye ree
Bákan náà, Naijiria wa lara orilẹede mẹ́ẹ̀dógún ni Afrika tí Amẹ́ríkà ni káwọn aṣojú rẹ to wa làwọn orílẹ̀èdè rẹ máa bọ wale.
Àwọn orílẹ̀èdè yókù ni Algeria, Burundi, Cameroon, Cape Verde, Gabon, Côte d'Ivoire, Egypt, Madagascar, Mauritius, Niger, Rwanda, Senegal, Somalia àti Uganda.
Ni agbegbe Asia, àwọn orílẹ̀èdè bíi Fiji, Laos, the Marshall Islands, Papua New Guinea, Philippines àti Vietnam ni ìṣẹ̀lẹ̀ yìí kan.
Ní agbègbè Europe, àwọn orílẹ̀èdè bíi Armenia, Macedonia, Montenegro àti Slovakia ni ìṣẹ̀lẹ̀ yìí kan.
Bákan náà, ní agbègbè Western Hemisphere, orilẹede Guatemala àti Suriname ni ìṣẹ̀lẹ̀ yìí kan, táwọn asoju Amerika làwọn orílẹ̀èdè náà sì ti padà sílè.
Asiko ijọba ààrẹ Joe Biden làwọn asoju Amẹ́ríkà làwọn ilẹ̀ òkèèrè náà tí gba ipò wọn
Awọn òṣìṣẹ́ to wa fọrọ abẹ́lé ni Amẹ́ríkà ṣàlàyé pé wọn tí fi ọrọ naa to olórí ẹka to n ṣàkóso àwọn asoju orílẹ̀èdè náà làwọn ilẹ̀ òkèèrè létí.
Láti ọ̀sẹ̀ to kọjá sí ní wọ́n ti tẹ ẹ mọ wọn létí pé àkókò wọn làwọn orílẹ̀èdè náà yóò tàn losu kinni ọdún 2026.
Ìròyìn ni asiko ijọba ààrẹ Joe Biden làwọn asoju Amẹ́ríkà làwọn ilẹ̀ òkèèrè náà tí gba ipò wọn.
Àmọ́ orí ko wọn yọ nínú isiporọpo to wáyé ní ìbẹ̀rẹ̀ ìjọba ṣáá kejì ààrẹ Trump, èyí tí wọn ṣe fáwọn olóṣèlú to gba ipò.
Àlàyé rèé lórí bí bàálù Amẹ́ríkà ṣe ń pàráàáro òfurufú Nàìjíríà lẹ́yìn ìdúnkookò ààrẹ Trump

Oríṣun àwòrán, U.S Airforce
Orílẹ̀èdè Amẹ́ríkà tí bẹ̀rẹ̀ si gbe àwọn bàálù rẹ paraaro yíká orílẹ̀èdè Nàìjíríà, láti oṣù kọkànlá to lọ.
Àfojúsùn iparaaro náà ni lati ko ìròyìn jọ nípa eto aabo àti àwọn ikọ̀ afẹ̀jẹ̀wẹ̀ to ń pa ọ̀pọ̀ èèyàn ni Naijiria.
Gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ nípa bí bàálù ṣe ń fò àti ohun tí òṣìṣẹ́ Amẹ́ríkà to wa lẹ́nu ìṣẹ àti àwọn tó ti feyinti ṣe wí, èyí tí ìwé ìròyìn Reuters gbé síta.
Ìgbésẹ̀ náà ń ṣe àfihàn pé ifọwọsowọpọ wá laarin orílẹ̀èdè Nàìjíríà àti Amẹ́ríkà láti ṣẹgun ìwà ìgbésùnmọ̀mí.
Àmọ́ kò sì ẹni tó tíì lè fìdí rẹ mulẹ nípa àwọn ìròyìn eto aabo nípa Naijiria táwọn bàálù Amẹ́ríkà náà tí kò jọ.
Àwọn bàálù náà sì lọ ń fò lẹ́yìn oṣù díẹ̀ tí àwọn agbébọn jí awakọ̀ bàálù kan tó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Amẹ́ríkà gbé, ẹni tó ń ṣiṣẹ́ fún ikọ̀ ajíyìnrere, ní agbègbè kan tó sún mọ́ orílẹ̀èdè Niger.
Bẹẹ bá gbàgbé, ààrẹ Amẹ́ríkà, Donald Trump ló ti kéde losu kọkànlá to kọjá pé òun yóò dá sí eto aabo Naijiria torí bí ijoba ṣe kùnà láti fòpin sí ìkọlù táwọn agbébọn ń ṣe sáwọn Kristẹni.
"Bàálù tó ń fò lo n ṣíṣẹ́ pẹlu ologun Amẹ́ríkà láti pápákọ̀ òfurufú kan nilu Accra, níbi tí iléeṣẹ́ ológun Amẹ́ríkà ni ibujoko sì"
Iroyin naa àkọsílẹ̀ bí bàálù ṣe ń fò lagbaye fihan pe bàálù Amerika náà lo ń gbéra láti orílẹ̀èdè Ghana, láti wá fò fún ìtọ̀pinpin nipa ílẹ̀ Nàíjíríà, tí yóò sì tún padà silu Accra nílẹ̀ Ghana.
Àkọsílẹ̀ náà ni bàálù yìí, lo n ṣíṣẹ́ pẹlu awọn ologun Amẹ́ríkà láti pápákọ̀ òfurufú kan nilu Accra, níbi tí iléeṣẹ́ ológun Amẹ́ríkà ni ibujoko sì.
Liam Karr, tíí ṣe aṣáájú ikọ̀ to ń mojuto àwọn iṣẹ́ to ń dùn koko mọ ilẹ̀ adúláwọ̀ ṣàlàyé pé ìgbésẹ̀ náà ṣe àfihàn àmì pé Amẹ́ríkà tí ń sagbara lẹ́kùn ìwọ oòrùn Áfíríkà leyin ti orílẹ̀èdè Niger pàṣẹ pé káwọn ológun Amẹ́ríkà kúrò ní orílẹ̀èdè òun.
"Bàálù tó ń fò náà yóò ṣe àwárí awakọ̀ bàálù ọmọ Amẹ́ríkà tí wọn ji gbe àti akojọ ìròyìn nípa ikọ̀ afẹ̀jẹ̀wẹ̀ Boko Haram áti ISIS"
Òṣìṣẹ́ feyinti kan nílẹ̀ Amẹ́ríkà ṣàlàyé pé bàálù to ń fò yíká Nàìjíríà náà wà lára àwọn dúkìá Amẹ́ríkà tí ìjọba Trump kò wá silu Accra nílẹ̀ Ghana losu kọkànlá to kọjá yìí.
Àmọ́ kò dájú nípa iye bàálù Amẹ́ríkà tó wà nilu Accra àmọ́ Òṣìṣẹ́ feyinti náà ni lára ojúṣe isẹ náà ni lati se àwárí awakọ̀ bàálù ọmọ Amẹ́ríkà tí agbébọn jí gbé lọ.
Bákan náà, bàálù tó ń fò náà yóò tún kó ìròyìn jọ nípa ikọ̀ afẹ̀jẹ̀wẹ̀ Boko Haram pẹlu awọn akẹẹgbẹ́ rẹ bíi ISIS àtàwọn miran to ń ṣọṣẹ́ nílẹ̀ Nàìjíríà.
Kí ló ti wáyé sẹ́yìn nípa eto aabo Nàìjíríà laarin ààrẹ Amẹ́ríkà àti ti Nàìjíríà?
Ààrẹ orílẹ̀èdè Nàìjíríà, Bola Tinubu tí kéde pé eto aabo Nàìjíríà kò fararọ losu kọkànlá to kọjá.
Kété lọ sí pe ìpàdé pajawiri laarin rẹ atáwọn aṣáájú iléeṣẹ́ agbófinró.
O wa pàṣẹ fáwọn ológun àti ọlọ́pàá láti bẹ̀rẹ̀ si gbà awọn eeyan sẹnu iṣẹ lọ́nà àti mú àdínkù bá eto aabo to mẹhẹ jákèjádò orílẹ̀èdè Nàìjíríà.
Igbesẹ náà sì lọ tẹ́le onírúurú ìkọlù to wáyé yíká Nàìjíríà tori báwọn agbébọn náà ṣe ń pa àwọn èèyàn ń ìpakúpa, tí wọn sì ń jí àwọn aráàlú gbé ní ọgọọrọ.
Kódà, wọn ji àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó lè ní àádọ́ta gbé ní ìpínlẹ̀ Adamawa, tí wọn sì tún kó akẹ́kọ̀ọ́ bíi ọọdúnrún lọ nílẹ̀ ẹ̀kọ́ St. Mary to WA nilu Papiri nipinlẹ Niger.
Àmọ́ ìjọba ilẹ̀ Amẹ́ríkà tí kéde pé òun yóò gbẹ̀san lára ijoba Nàìjíríà torí bo se kùnà láti dáàbò bo àwọn Kristẹni.
Ààrẹ Amẹ́ríkà wá fi orúkọ Naijiria sì ara àwọn àkọsílẹ̀ orúkọ àwọn orílẹ̀èdè to tàpá sì òfin òmìnira láti ṣe ẹṣin tó bá wù onikaluku.
Bakan naa, nínú oṣù Kejìlá yìí, ìjọba Amẹ́ríkà to kéde ilẹ̀ Nàìjíríà bíi ara àwọn orílẹ̀èdè tí yóò nira fún láti wọ orílẹ̀èdè náà, tó sì fi òfin àti gbèdéke tí irinajo àwọn ọmọ Nàìjíríà sì Amẹ́ríkà nìdí.
Aarẹ Trump sì ti kede ṣáájú pé káwọn ológun Amẹ́ríkà gbaradi láti ṣe ìkọlù ológun silẹ Nàìjíríà, tí orílẹ̀èdè náà bá fi kùnà láti dẹkùn eto aabo tó mẹhẹ.
Lọ́wọ́ lọ́wọ́ báyìí, ilẹ Naijiria ati Amẹ́ríkà tí ṣe Ágbékalẹ̀ Ìgbìmọ̀ alajumose tí yóo ṣiṣẹ lẹ́ka eto aabo.
Riley Moore, tíí ṣe asoju ẹgbẹ́ òṣèlú Republican nílẹ̀ Amẹ́ríkà, to ṣẹ̀ṣẹ̀ rìnrìn àjò wa silẹ Nàìjíríà, lo kéde bẹẹ.















