Atiku, Obi àtàwọn ẹgbẹ́ ajàfẹ́tọ̀ọ́ yarí, pè fún ìdádúró òfin owó ori tuntun lórí ẹ̀sùn títọwọ́bọ òfin náà, iléeṣẹ́ ààrẹ fèsì

Oríṣun àwòrán, Nigerian Presidency
Igbakeji aarẹ Naijiria tẹlẹ, Atiku Abubakar, ti pe fun iwadii lori ẹsun wi pe ijọba apapọ ṣe ayipada ofin owo ori tuntun ti yoo gberasọ lati ọjọ kinni oṣu Kinni ọdun 2026.
Atiku ni iwadii kikun gbọdọ waye lati mọ nnkan to ṣẹlẹ gan an lori ẹsun ayipada ofin owo ori naa, ki ijọba si ṣe ohun to yẹ lori ọrọ naa.
Igbakeji aarẹ Naijiria tẹlẹ wa pe fun idaduro ofin owo ori tuntun naa titi ti iwadii yoo fi pari lori ẹsun aṣemaṣe tawọn eeyan kan fi kan ijọba apapọ lori ofin naa.
Atiku to sọrọ nipasẹ oludamọran lori eto iroyin rẹ, Paul Ibe, sọ pe idaduro ofin owo ori tuntun naa yoo fawọn aṣofin lanfaani lati ṣe iwadii finifini lori ọrọ naa.
''Nkan kan kudiẹ kaato pẹlu orilẹede yii, o si lagbara gan an.
Iyalẹnu lo jẹ wi pe awọn kan lọ ṣe ayipada ofin ti ijọba ti ṣe tan.
Iwe yiyi ni wọn maa n pe eleyii, iwa ọdaran si ni, ibeere to yẹ kawọn eeyan maa beere ni pe ki ni awọn nnkan mii ti wọn tun ti yii bayii?
Eleyii lewu gan an, o si fidi nnkan ti a ti sọ tẹlẹ nipa iṣejọba to wa lode mulẹ,'''Atiku lo sọ bẹẹ.
Atiku tun sọ pe ayipada ti bawọn nnkan ti ko niṣe pẹlu iwa ọdaran tẹlẹ ninu ofin owo ori naa lati di iwa ọdaran bayii lati le fi mu awọn oloṣelu kan.
Ewu n bẹ loko Longẹ lọrọ aṣiri ayipada ofin owo ori tuntun to lu sita – Obi
Ninu ọrọ tiẹ, oludije sipo aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Labour Party (LP) ninu eto idibo aarẹ ọdun 2023, Peter Obi, sọ pe aṣiri ayipada ofin owo ori to lu sita lewu fun orilẹede Naijiria.
Obi ni ọrọ ijọba APC bẹrẹ pẹlu eto iṣejọba ti ko dara to, ko to debi titapa sofin Naijiria bayii.
O ni ẹsun ayipada ofin owo ori Naijiria tawọn eeyan n sọ nipa rẹ mu ewu dani fun iwe ofin Naijiria.
Obi to ṣakiyesi pe igbẹkẹle ati igboya awọn araalu ninu ijọba n dinku sii, ṣo pe ijọba ko le maa di ẹru owo ori nla le awọn araalu lori nigba ti ijọba gan an n fi ọpọ nnkan pamọ.
Ninu ọrọ to fi lede loju opo X rẹ, gomina ipinlẹ Anambra tẹlẹ, ṣalaye pe ẹsun ṣiṣe ayipada ofin owo ori n ṣafihan bi nnkan ṣe bajẹ to ni Naijiria ninu eto iṣejọba.
''Jibiti pẹlu eto iṣuna ni a n sọ tẹlẹ, ofin yiyi ni a tun n gbọ bayii, awọn ayipada ofin yii yoo si ipa ni lori ẹtọ awọn araalu to n san owo ori.
Nnkan to tun buru ni ofin fifi ipa mawọn eeyan lori ọrọ owo ori sisan, eyi ti ile aṣoju-ṣofin buwọlu.
Ofin naa sọ pe ẹni tọrọ kan gbọdọ san ida 20% owo sapo ijọba na ki ẹjọ kotẹmilọrun to le waye nile ẹjọ, tita dukia awọn eeyan lai ti lọ ile ẹjọ ati fifi ṣinkun mawọn lori ọrọ owo ori.
Ta lo ṣe awọn ayipada yii? Gbogbo araalu lo gbọdọ mọ eleyii.
Awọn ọmọ Naijiria gbọdọ mọ ofin owo ori ti ile aṣofin ṣe agbekalẹ rẹ ati eyi ti aarẹ buwọlu gan an, ki wọn si mọ eyi to w ani akọsilẹ.
A o le maa sọ pe kawọn araalu maa san owo ori lọ, nigba ti igbẹkele awọn eeya ninu ijọba n dinku si,'' Obi ṣalaye.
Ẹgbẹ oṣelu ADC atawọn ẹgbẹ ajafẹtọọ pe fun idaduro ofin owo ori tuntun, wọn ni ofin amunisin ni
Ẹwẹ, ẹgbẹ oṣelu ADC ti ṣapujuwe ofin owo ori tuntun gẹgẹ bi ofin amunisin.
Ẹgbẹ ADC naa n pe fun idaduro ofin naa ki ile aṣofin agba le lanfaani lati mọ iru ayipada tawọn kan ti ṣe sori ofin ọhun, ki atunṣe to yẹ le waye lori rẹ.
ADC fidi ọrọ yii mulẹ ninu atẹjade kan akọwe iroyin ẹgbẹ naa, Mallam Bolaji Abdullahi, fi sita.
Ẹgbẹ ADC kilọ pe ṣiṣe ayipada ofin owo ori tuntun lẹyin ti ile aṣofin ti buwọ lu u tan fi han pe Aarẹ Bola Tinubu fẹ ki gbogbo agbara wa lọwọ rẹ.
ADC tun pe fun iwadii ohun to ṣẹlẹ gan an lori ayipada ofin ti ile ti buwọlu tan, ki awọn to wa nidii ọrọ naa si foju wina ofin.
Ẹgbẹ Take-It-Back Movement naa ṣapejuwe ofin owo ori tuntun gẹgẹ bii eyi tako araalu ti o si lodi sofin.
Adari ẹgbẹ naa, Juwon Sanyaolu, to ba iwe iroyin Punch sọrọ ṣalaye pe ayipade ofin owo ori tuntun n ṣafihan iwa ta ni yoo mu mi ti ijọba Tinubu.
Ọgbẹni Sanyaolu ni ijọba gbe ofin yii kalẹ lati fiya jẹ araalu ni.
'Ofin owo ori tuntun wa lati fiya jẹ ọmọ Naijiria ni, o kere ida 90% ọmọ Naijiria ni ofin yii yoo fiya jẹ.
Atunṣe ofin owo ori yii yoo ṣakoba fawọn agbanisiṣẹ, awọn to n ṣiṣẹ ara wọn, awọn ọdọ, awọn to n ṣe fidio lori ayelujara atawọn to n ta oniruuru ọja ti wọn ko ṣiṣẹ ọfiisi.
Eyi buru jai tori ijọba funra rẹ ti kuna lati ṣe ojuṣe rẹ fun araalu,'' Sanyaolu ṣalaye.
Ileeṣẹ aarẹ fesi lori ẹsun ayipada ofin owo ori tuntun
Ẹwẹ, ileeṣẹ aarẹ ti sọrọ lori awuyewuye to n lọ lori ofin owo ori tuntun tawọn eeyan kan fẹsun kan ijọba apapọ pe o ti ṣe ayipada ofin naa lẹyin ti ile aṣofin buwọlu u tan.
Ileeṣẹ aarẹ sọrọ lẹyin ti Atiku, Obu atawọn ẹgbẹ ajafẹtọọ pe fun idaduro ofin naa ki iwadii to peye le waye lori rẹ.
Ọmọ ile aṣoju-ṣofin kan, Abdulsamad Dasuki, lo ṣakiyesi laipẹ yii pe kudiẹ-kudiẹ kan wa ninu ẹda ofin owo ori tuntun ti ile buwọlu ati eyi ti awọn eeyan n ri kaakiri.
Dasuki ni awọn eeyan kan ti tọwọ bọ iṣẹ ti ile aṣofin ṣe lori ofin owo ori tuntun naa, tori ofin owo ori tawọn eeyan n gbe kiri yatọ si eyi ti ile ṣiṣẹ lori rẹ.
Amọ, ninu ọrọ rẹ, alaga igbimọ ileeṣẹ aarẹ to ṣiṣẹ lori ofin owo ori truntun naa, Taiwo Oyedele, sọ pe iroyin ofege lawọn eeyan n gbe kiri lori ofin owo ori tuntun.
Oyedele ni ẹda ofin owo ori tuntun ti akọwe ile igbimọ aṣofin agba l'Abuja buwọlu to si fi ranṣẹ si aarẹ lati fontẹ lu nikan loun mọ.
O ni awọn aṣofin nikan lo le ṣo nipa ofin ti ileeṣẹ aarẹ fi ranṣẹ si wọn fun ibuwọlu.
''Ofin owo ori to w ani eyi ti ile igbimọ aṣoju-ṣofin buwọlu, ati eyi ti akọwe ile aṣofin jẹrii si.
Ẹda ofin ti wọn fi ranṣẹ si aarẹ lati buwọlu ni emi gan an ni lọwọ,'' Oyedele lo sọ bẹẹ.
Oyedele ni abala 41(8) ofin owo ori to ni eeyan gbọdọ san ida 20% owo fun ijọba ko tii si ninu ẹda ofin naa to wa ni akọsile bayii.
Amọ, o ni iyalẹnu lo jẹ wi pe awọn eeyan ti n gbe abala yii kaakiri.
O fikun ọrọ rọ wi pe iroyin tawọn eeyan n gbe kiri kii ṣe nnkan to wa ninu nnkan ti igbimọ ile aṣofin ṣiṣẹ le lori.
Oyedele ni oun naa faramọ pe ki ile ṣe iwadii kikun lori ọrọ naa daadaa.
Aarẹ Tinubu buwọlu ofin owo ori tuntun eyi ti imuṣẹ rẹ yoo gberasọ lọjọ kinni oṣu Kinni ọdun 2026.
Ijọba ni ofin yii yoo ṣe akojọpọ gbogbo owo ori ti araalu ti maa n san kele kele tẹlẹ soju kan, ati pe yoo si tun maa jẹ ki ijọba apapọ, ti ipinlẹ ati ijọba ibilẹ maa le gba owo ori lọna igbalode.















