"Ìtẹ́ Aláàfin ló máa ń pàṣẹ fún gbogbo ilẹ̀ Yorùbá, torí náà, èmi nìkan lọba alayé tó lè fi èèyàn jẹ oyè fún ilẹ̀ Yorùbá"

Alaafin tilu Oyo, Ọba Abimbola Akeem Owoade ati Olori rẹ, Abiwunmi, wọ asọ oke Alaari toke tilẹ, Ọmọ aarẹ, Seyi Tinubu kunlẹ siwaju wọn, ti Alaafin si n gbe ade Ọkanlọmọ tilẹ Yoruba le lori
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 6

Alaafin Oyo, Ọba Abimbola Akeem Owoade Kinni, ti sọ pe ọba to ba wa lori itẹ Alaafin nikan lo laṣẹ lati fi eeyan jẹ oye gbogbo ilẹ Yoruba.

Alaafin Owoade fidi ọrọ yii mulẹ nigba to n fi Sẹnẹtọ Abdul-Aziz Yari jẹ oye Obaloyin ilẹ Yoruba niluu Oyo.

Lasiko yii kan naa ni Kabiyesi Owoade fi Seyi Tinubu, ọmọkunrin Aarẹ Bola Tinubu, jẹ oye Okanlomo ilẹ Yoruba lanaa ọjọ Aiku ọjọ kọkanlelogun oṣu Kejila yii niluu Oyo.

Alaafin Owoade ni fifi eeyan joye wa ninu aṣa Yoruba kii ṣe ojuṣaaju rara, o ni oye jijẹ tumọ si pe ẹni to ba joye niṣẹ lati ṣe e.

Ọba Owoade ṣalaye pe itẹ Alaafin lo maa n paṣẹ fun gbogbo ilẹ Yoruba lati igba iwasẹ.

O ni awọn ijọba akonilẹru Ilẹ Gẹẹsi ati ijọba Naijiria lẹyin ominira ọdun 1960 naa mọ nipa eyi.

Kabiyesi sọ pe gbogbo oye to ba ni ilẹ Yoruba lo n ṣoju gbogbo ẹya Yoruba patapata, idi si niyi ti ẹni to ba wa lori itẹ Alaafin fi gbọdọ fawọn eeyan jẹ iru oye bẹẹ.

''Oniruuru iṣẹ iwadii ati ile ẹjọ to ga julọ ni Naijiria lo fontẹ lu Alaafin nikan lati fawọn eeyan joye gbogbo ilẹ Yoruba''

Alaafin fikun ọrọ rẹ pe oniruuru iṣẹ iwadii to fi mọ ile ẹjọ to ga julọ lorilẹede Naijiria lo fontẹ lu ipo Alaafin lati fawọn eeyan joye gbogbo ilẹ Yoruba.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ọba Owoade ṣapejuwe oye to fi Seyi ati Sẹnẹtọ Yari jẹ gẹgẹ bi eyi to ni i ṣe pẹlu igboya, ifọkansin ati iṣẹ fawọn eeyan ilẹ Yoruba.

Alaafin ni oye toun fi dawọn eeyan lọla yoo jẹ ki iru awọn bẹẹ le maa ṣe igbelarugẹ aṣa ati iṣe Yoruba.

O rọ awọn to ṣẹṣẹ fi joye lati ṣe pẹlẹ, ki wọn si maa ṣe igbelarugẹ aṣa ati iṣe ilẹ Yoruba.

''Ipejọ wa lonii ju wi pe a kan pejọ lati ṣe ajọyọ lasan an lọ, a wa nibi lati fidi itan mulẹ.

Oye jijẹ wa ninu aṣa wa, kii ṣe pe a n ṣegbe lẹyin ẹnikan.

Iṣẹ la n ṣe, a maa n ṣe leyii nigba ti itan, aṣa ati iṣẹ ba pade ara wọn

Itẹ Alaafin Oyo ti pẹ ninu itan gẹgẹ bii itẹ alaṣẹ, koda, ijọba amunisin ilẹ Gẹẹsi gan an ba itẹ Alaafin nibẹ ni.

Ni ọdun 1914, ẹkun Oyo ni ẹkun lo tobi julọ ni apa guusu orilẹede Naijiria.

Ijọba Oyo paala pẹlu Ilorin ati Kontagora lapa ila oorun, nigba ti o paala pẹlu Ondo ati Ijebu lapa guusu; bakan naa ni Oyo tun paala pẹlu Dahomey,'' Alaafin ṣalaye.

O ni oun ko maa sọrọ yii ko le di ariyanjiyan, ṣugbọn oun n sọ ọ lati fidi itan mulẹ fawọn ti ko ba mọ ni.

Aláàfin Owoade fi Seyi Tinubu, Abdul Aziz Yari, jẹ oyè Ọkanlọmọ àti Ọbaloyin ilẹ̀ Yorùbá ‎

Aworan ifinijoye awon oloye mejeeji, Senetọ Abdul Aziz Yari lati Zamfara to jẹ Ọbaloyin ilẹ Yoruba, ati ọmọ Aarẹ ilẹ wa, Seyi Tinubu ti Alaafin Owoade fi joye Okanlọmọ ilẹ Yoruba.
Àkọlé àwòrán, Aworan ifinijoye awon oloye mejeeji, Senetọ Abdul Aziz Yari lati Zamfara to jẹ Ọbaloyin ilẹ Yoruba, ati ọmọ Aarẹ ilẹ wa, Seyi Tinubu ti Alaafin Owoade fi joye Okanlọmọ ilẹ Yoruba.

Alaafin ilu Oyo, Ọba Akeem Abimbọla Ọwọade, ti fi Seyi Tinubu, ọmọ Aarẹ Orilẹ-ede Naijiria, Bọla Tinubu, jẹ oye Ọkanlọmọ ilẹ Yoruba lonii ojọ Aiku, ọjọ kọkanlelogun oṣu Kejila ọdun 2025.

‎Bakan naa ni ‎Alaafin tun nawọ oye si Sẹnetọ to n ṣoju ẹkun Iwọ-Oorun ipinlẹ Zamfara, Sẹnetọ Abdul'Aziz Abubakar Yari, pẹlu oye Ọbalọyin ti ilẹ Yoruba to fi da a lọla.

Nibi ayẹyẹ naa ni ilu Oyo ti gba alejo awọn ọtọkulu, awọn oloselu ati awọn lọbalọba lati origun mẹrin gbogbo ilẹ Yoruba.‎

‎Nigba to n fi ẹmi imoore han ni gbongan iwẹjẹ-wẹmu, Sẹnetọ Yari dupẹ lọwọ Alaafin Ọyọ lorukọ rẹ ati ti Seyi Tinubu, fun bi wọn se ka wọn yẹ fun oye naa.

Yari to ti fi igba kan ri jẹ Gomina ipinlẹ Zamfara, sọ pe kaakiri gbogbo ẹkun mẹfẹẹfa orilẹ-ede Naijiria ni wọn yoo ti duro ti Aarẹ Bola Tinubu, ti yoo fi wọle saa keji.

Ọbaloyin sọ pe nigba ti igun Arewa fa Oloogbe Muhammadu Buhari kalẹ fun ipo Aarẹ, ẹkun Guusu-Iwọ-Oorun, paapaa julọ, Asiwaju Bọla Tinubu, sisẹ ribiribi, o si na ọpọlọpọ owo lati gbe ti Buhari de ipo naa ni ọdun 2015.

Kete lẹyin igba to ja ewe oye le wọn lori, Alaafin Abimbọla Ọwọade gbadura fun awọn oloye titun mejeeji, bẹẹ lo ki gbogbo awọn lẹgbẹlẹgbẹ lọgbalọgba to wa nibi ayẹyẹ naa.

Ayeye ifinijoye yii lo waye lẹyin bii ọṣẹ meji ti Ọọni Ile Ife, Ọba Adeyeye Ẹnitan Ogunwusi, fi Onisowo ọmọ ilu Ibadan kan, Oloye Dọtun Sanusi, jẹ Ọkanlọmọ Oodua, ti awuyewuye si waye lori ọba to ni aṣẹ lati fi eeyan joye to ni i ṣe pẹlu gbogbo ilẹ Yoruba.

Seneto Yari to jẹ Obaloyin ree laaarin
Àkọlé àwòrán, Seneto Yari to jẹ Obaloyin ree laaarin
Seyi Tinubu to jẹ Ọkanlọmọ ree pẹlu awon eeyan rẹ
Seyi Tinubu ati iyawo rẹ
Alaafin Abimbola Owoade ati Olori Abiwumi Owoade
Diẹ lara awọn oriade nibi ayẹyẹ naa.
Diẹ lara awọn oriade ati oloye to wa nikalẹ
Àkọlé àwòrán, Diẹ lara awọn oriade ati oloye

Lara awọn gbajumọ to wa nibi ayeye ijoye naa ni Gomina ipinlẹ Sokoto; Aliyu Sokoto, Minisita fun eto ọrọ aje; Wale Edun, Minisita fun eto ọrọ ina mọnamọna, Adebayọ Adelabu, Olori Ile Igbimọ-Asofin ipinlẹ Oyo, Adebo Ogundoyin, Gomina nigba kan ri nipinle Ogun; Ọtunba Gbenga Daniel ati bẹẹ bẹẹ lọ.

‎Ayẹyẹ ọhun tun ṣoju awọn lọbalọba nilẹẹ Yoruba, ti wọn wa lati yẹ Alaafin Owoade si.

‎Lara awọn ọba to wa nibi ayẹyẹ naa ni: Olugbọn Orile-igbọn; Ọba Francis Alao, Oluwo ti Ilu Iwo; Ọba Rasheed Akanbi, Timi ilu Ẹdẹ; Ọba Muniru Lawal, Olọfa Ilu Ofa; Ọba Mufutau Gbadamọsi, Eleruwa ti ilu Eruwa; Ọba Adegbọla, Aseyin ti ilu Isẹyin ati bẹẹ bẹẹ lọ.

‎ ‎Bakan naa si ni awọn ẹṣọ alaabo ilu duro wamu lati pese aabo nibi ayẹyẹ naa.

Ọpọ oloselu, paapaa julọ lati ile igbimo asofin agba, ati tawọn Aṣoju-ṣofin ko si gbẹyin pẹlu.