Ìdí tí KWAM 1 fi gbé Gómìnà Dapo Abiodun lọ ilé ẹjọ́ lórí ọ̀rọ̀ yíyan Awujale Ijebu tuntun

Oríṣun àwòrán, Prince Dapo Abiodun/X/K1 De Ultimate/Instagram
Gbajugbaja akọrin Fuji, Wasiu Ayinde ti ọpọ mọ si KWAM 1 ti gbe Gomina Dapo Abiodun lọ sile ẹjọ lori ọrọ oye Awujale ilẹ Ijebu.
KWAM 1 n beere lọwọ ile ẹjọ giga to wa ni ilu Ijebu Ode lati paṣẹ fun Gomina Abiodun atawọn marun un mii wi pe ki wọn ma le gbe igbesẹ kankan lori ẹni ti yoo jẹ Awujale Ijebu lọwọ yii.
Awọn mii ti ẹjọ naa kan ni alaga ijọba ibilẹ Ijebu Ode, kọmiṣọna ijọba ibilẹ ati ọrọ oye nipinlẹ Ogun, akọwe ijọba ibilẹ Ijebu Ode, alaga igbimọ to n ri si ọrọ to niṣe pẹlu Awujale ati alaga idile ọba Fusengbuwa.
Ti ẹ o ba gbagbe, KWAM 1 wa lara awọn eeyan to ti fi erongba wọn han lati jẹ Awujale ilẹ Ijebu lẹyin iku Ọba Sikiru Adetona.
Idile Jadiara to tan mọ idile ọba Fusengbuwa ni agbaọjẹ akọrin Fuji naa loun ti wa.
Amọ, idile naa lawọn o mọ ọ ri, wọn ni Olori Ọmọba Ilẹ Ijebu ko tan mọ awọn rara.
Ninu ẹjọ ti o pe pẹlu nọmba HC3/238/2025, K1 ni ẹjọ naa wa ni ibamu pẹlu aṣẹ 38 abala kẹrin ati aṣẹ 39 abala kinni ile ẹjọ giga Ijebu Ode ati abala kérindinlogoji iwe ofin oriẹlede Naijiria.
Gbajugbaja olorin Fuji naa sọ pe ki ile ẹjọ paṣẹ pe ki gbogbo eeyan to lọwọ ninu yiyan Awujale Ijebu tuntun duro na titi ti ile ẹjọ yoo fi gbẹjọ oun tan.
O ni ile ẹjọ ni lati lo agbara rẹ lori awọn to fẹ yan Awujale mii ki wọn ma ba ṣe nnkan ti yoo ṣakoba fun oun.
Ile ẹjọ giga Ijebu Ode ko tii kede ọjọ ti igbẹjọ yoo bẹrẹ.















