Ṣé lóòótọ́ làwọn kan ṣe pàṣípààrọ̀ òfin owó orí tuntun tíjọba Nàìjíríà fẹ́ bẹ̀rẹ̀ lọ́dún 2026?

Oríṣun àwòrán, Bayo Onanuga
Awọn ọmọ Naiijiria ti bẹrẹ si n fi erongba wọn lede lori iroyin to ni wọn ti ṣatunsẹ si ofin owo ori tuntun ti yoo bẹrẹ lọjọ kinni, oṣu Kinni, ọdun to n bọ.
Ṣaaju ni aṣofin to n ṣoju ẹkun kan nipinlẹ Sokoto, Abdulsammad Dasuki, ke gbajare pe ohun to wa ninu abadofin ti awọn buwọlu nile igbimọ aṣofin yatọ si ohun to wa ninu ofin ti ijọba tẹ jade.
Ninu oṣu Kẹfa ọdun 2025 ni Aarẹ Bola Tinubu buwọlu ofin mẹrin tuntun nipa owo ori ni Naijiria, eyii to da lori bi araalu ṣe n an owo ori.
Ijọba ni ofin naa yoo mu ki ọrọ owo ori rọrun, yoo tun gbe ẹru wuwo kuro lori araalu yatọ si awọn anfani mii.
Amọ ṣa, ọrọ ti sẹnetọ yii sọ ti n mu ki awọn araalu ṣe iyemeji nipa igbagbọ ninu ijọba lori ofin owo ori tuntun ọhun.
Ki ni ohun ti Dasuki sọ ni pato?
Abdulsammad Dasuki sọ pe ohun ti awọn aṣofin jiroro le lori ti wọn si fi fohun si yatọ si ohun ti ijọba pada gbe jade lẹyin-o-rẹyin.
O ni ẹtọ ohun ni lati sọrọ naa gẹgẹ bii ọmọ ile igbimọ aṣọfn kekere.
Gẹgẹ bo ṣe sọ, odidi ọjọ mẹta gbako loun fi ṣe agbeyẹwo ofin naa ti oun si le fidi rẹ mulẹ pe lootọ ni wọn ṣayipada si.
Ṣe lootọ ni wọn yi ohun to wa ninu ofin naa pada?
Aṣofin kan nile igbimọ aṣojuṣofin to wa lati ipinlẹ Kano, Kabir Alhassan Rurum, sọ pe iwadii nikan lo le ṣalaye ohun to ṣẹlẹ ni pato.
O fi kun pe awọn aṣofin ọhun ti gbe igbimọ kan kalẹ ti yoo ri si ọrọ naa.
O ni "A ko ni sọ pe ootọ ni, bẹẹ a ko ni sọ pe irọ n.
Ile ti gbe igbimọ ti yoo ṣe iwadii ọrọ naa kalẹ lati bojuto."
Ẹwẹ, ileeṣẹ to n ri si ọrọ owo ori ni Naijiria, FIRS ti sọ pe oun ko fọwọ kan ofin naa, bẹẹ naa loun ko ṣe atunṣe kankan si.
Wayi o, ọpọ awọn ọmọ Naijiria ti n bere fun iwadii lori ọrọ ọhun.















