Ìdí táwọn Mogaji Ibadan àti ẹgbẹ́ CCII fi jáwé ìkìlọ̀ fún Alaafin Akeem Owoade

Awọn Mogaji ilẹ Ibadan, ẹgbẹ awọn ọmọ ilu Ibadan CCII, awọn lọba lọba, baalẹ ati gbogbo ọmọbibi ilu Ibadan lọkunrin lobinrin ti kilọ fun Alaafin Oyo, Ọba Akeem Abimbola Owoade, wi pe ko ye tabuku Olubadan ilẹ Ibadan, Ọba Rashidi Ladoja mọ.
Wọn ni awọn o ni faramọ ki Alaafin maa naka abuku si Ọba Ladoja tabi si itẹ Olubadan.
Ikilọ yii ko ṣẹyin awuyewuye to jẹyọ lori ibi ti Olubadan ati aṣoju Alaafin fẹ jokoo si nibi apero lori ọrọ eto aabo to waye laipẹ yii niluu Ibadan.
Ninu atẹjade kan ti aarẹ awọn Mogaji ilẹ Ibadan, Mogaji Asimiyu Ariori ati alakoso igbimo ICPI to n ri si alaafia agboole n'Ibadan, Ọmọwe Nurudeen Akinade, buwọlu ni wọn ti sọ pe ki Alaafin ye wo Olubadan bi ipo ọba to wa labẹ ilu Oyo tabi ilu kankan nilẹ Yoruba.
Wọn sọ ninu atẹjade naa wi pe Ibadan mọ iwọn ara wọn, ati pe awọn ọmọ ilu Ibadan kii tabuku aṣa Yoruba rara.
Awọn Mogaji ilẹ Ibadan atawọn ọmọ Ibadan tun wa kepe awọn agbaagba ilẹ Yoruba lati ba Alaafin sọrọ pe ko ma huwa arifin si Olubadan mọ.
Bakan naa ni wọn tun sọ pe ọrọ ede-ai-yede to ṣẹlẹ ninu igbimọ lọba lọba ipinlẹ Oyo ti niyanju, wi pe ki Alaafin ma ṣe hu ọrọ naa jade mọ.
Awọn Mogaji ilẹ Ibadan tun sọ pe Ọba Ladoja kii ṣe eeyan yẹpẹrẹ tori o ti awọn ipo nla nla bii ipo sẹnẹtọ ati gomina mu, o si tun jẹ oniṣowo to gbajumọ.
''Ibadan ko le ṣẹru ẹnikan kan lailai, Ibadan mesi, wọn o gọ.
Ibadan nilo apọnle, a o ni gba fun ẹnikẹni to ba fẹ tabuku itẹ Olubadan.
Awọn ọmọ ilu Ibadan ṣetan lati daabo bo aṣa ati iṣe wọn,'' awọn Mogaji ilẹ Ibadan lo sọ bẹẹ.
Ṣaaju lawọn Mọgaji Ibadan ati ẹgbẹ CCII ti tako igbesẹ lati sọ Alaafin di alaga igbimọ lọbalọba Oyo
Ti ẹ o ba gbegbe, loṣu Karun un ọdun 2025 yii lawọn ẹgbẹ gbogbo ọmọ bibi ilẹ Ibadan CCII, Mogaji ilẹ Ibadan, Baalẹ ati Ọba dide tako igbesẹ ijọba ipinlẹ Oyo lati sọ Alaafin ti ilu Oyo di alaga laelae fun igbimọ lọbalọba nipinlẹ Oyo.
Bakan naa ni ẹgbẹ ọmọ Ibadan tun ṣe ikilọ fun ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Oyo pe, ki wọn mase da rogbodiyan silẹ, ti wọn si tẹnu mọ pe ipo alaga igbimọ lọbalọba jẹ ipo ti wọn ma n pin jẹ, ki ṣe fun eeyan kan ṣosọ.
Ninu atẹjade ti Aarẹ Mogaji ilẹ Ibadan, Mogaji Nurudeen Akinade fisita, Ibadan ko fi igba kankan jẹ igbakeji si Oyo ṣugbọn o wa fun aabo gbogbo ilẹ Yoruba.
Akinade ni igbala Ibadan tobi, to si ti gba ilẹ Yoruba silẹ ni ọpọ igba.
O tẹsiwaju pe ti Ibadan ko ba ṣe idaduro fun awọn Fulani lasiko ogun Fulani, ọpọ ilẹ Yoruba ni yoo jẹ pe Emir ni yoo maa jẹ ni ilu wọn.
"Oloye Obafemi Awolowo ko le di olori ijọba iwọ oorun Naijiria ti ki i ba ṣe ti awọn ọmọ Ibadan to fọwọsowọpọ pẹlu ẹgbẹ oṣelu Action Group (AG) lati koju NCNC ti Nnamdi Azikwe.
"Ibadan ti n gba ilẹ Yoruba silẹ fun ọjọ pipẹ, ko si igba kankan ti a jẹ ipo keji si Oyo tabi ilu kankan nilẹ Yoruba, koda Ibadan lo yẹ ko jẹ alaga laelae fun igbimọ lọbalọba.
"Nitori a ko sọrọ ko tumọ si pe a ya oponu rara.
Nigba ti Ibadan ko ja fun ipo Alaga laelae, ki lo de ti Oyo fi fẹ ṣe bẹẹ? Ile igbimọ aṣofin yoo da ara wọn ni ẹbi ti abadofin yii ba di ofin.
"Gomina nigba kan ri, Christopher Alao Akala lo bu wọlu ki ipo alaga lọbalọba jẹ pinpin lasiko iṣejọba rẹ.
Oba Samuel Odulana Odugbade, si lo jẹ alaga fun igbimọ lọbalọba nipinlẹ Oyo.
Ibadan ko ni tẹwọgba aba yii rara nitori awa ni a maa n siwaju ninu gbogbo nnkan."















