Ọwọ́ EFCC tẹ afurasí babaláwo márùn-ún, ká ayédèrú owó $3.4m àti €280,000 mọ́ wọn lọ́wọ́ ní ìpínlẹ̀ Osun àti Eko

Owo ilẹ okeere dọla ati Yuro nilẹ atawọn afurasi babalawo ti EFCC fọwọ ofin mu

Oríṣun àwòrán, EFCC/X

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ajọ to n gbogun ti iwa ajẹbanu ati si se owo ilu ni mokumoku, "Economic and Financial Crimes Commission" (EFCC), ẹka ti ilu Ibadan, ti sawajade awọn ayederu owo tabua kan to jẹ ti ilẹ okere.

Gẹgẹ bi o se wa lori itakun ayelujara X to jẹ ti ajọ naa, ni akata awọn onisegun marun-un kan ti wọn jọ n sisẹ papọ ni wọn ti ba awọn ayederu owo yii to to $3, 430, 000 ati €280, 000 ni iye.

Ajọ naa fọwọ sinkun ofin gbe awọn afurasi ọdaran wọn yii fun gbigba arabinrin kan, Halima Sanni ni owo ti o to N26, 550, 000.

Awọn onisegun yi jẹ ọkunrin mẹrin pẹlu obinrin kan, orukọ wọn si ni: Akingbola Omotayo, Adeola Funsho Ogunrinde, Yahaya Amodu, Kubratu Babalola Olaitan (obinrin) ati Familola Sunday Olaitan.

Itakun X naa sọ wi pe, wọn mu wọn ni ọjọ keje ati ọjọ kẹjọ osu kejila ọdun ti a wa yii ni awọn ile orisha wọn to wa ni Ipinlẹ Osun ati Eko lẹyin iwadii to peye lori iwa laabi ọwọ wọn.

Iwadii fihan pe, awọn afurasi wọn yii ma n lu awọn eeyan ti wọn o fura ni jibiti owo oogun wọn labẹ ẹtan pe wọn yoo ba wọn ṣe afọmọ, ati wi wo oniruuru aisan.

Wọn tun fẹsun kan wọn pe, wọn ma n fi da awọn ti wọn ba ko si wọn lọwọ loju pe, awọn lagbara lati pe orisisi owo jade, sugbọn ti wọn gbọdọ se etutu sii lati fọọ mọ ko to di nina.

Wọn ṣe eleyi lati ra awọn onibara wọn niye, ki wọn baa le pese owo fun etutu naa.

Awọn nnkan mii ti wọn gba lọwọ wọn jẹ ọkọ ayọkẹlẹ meji ati awọn ẹrọ ibanisọrọ.

Gẹgẹ bii itakun X EFCC ṣe gbee kalẹ, awọn afurasi naa yoo foju bale ẹjọ lọgan ti iwadii ba ti pari lori wọn.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post