Kí ló dé tí ìkọlù àwọn agbébọn peléke si lẹ́yìn ìdúnkokò Trump?

Àwọn agbébọn tó gbé ìbọn séjìká, ọta ìbọn kọ́rùn

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Lẹ́yìn tí ààrẹ Amẹ́ríkà, Donald Trump dúnkokò láti ṣèkọlù sí Nàìjíríà lórí ẹ̀sùn pé ìpanirun ń wáyé sáwọn ọmọlẹ́yìn Kristi ní Nàìjíríà ni onírúurú ìkọlù ọ̀tun tún ń wáyé. pàápàá láwọn ilé ìjọ́sìn.

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìjọba Nàìjíríà jiyàn ẹ̀sùn pé àwọn Kristẹni nìkan ni wọ́n ń ṣekúpa, wọ́n gbà pé ìpèníjà ààbò tó lágbára ń bá Nàìjìríà fínra àti pé àwọn ń sa gbogbo ipá àwọn láti ri dájú pé ìpèníjà náà di ohun ìgbàgbé.

Ààrẹ Bola Tinubu kéde àwọn ìgbésẹ̀ pàjáwìrì láti kojú ìpèníjà ààbò tó fi mọ́ gbígba àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò kún àwọn tó wà nílẹ̀ tẹ́lẹ̀.

Síbẹ̀, níṣe ni ìkọlù àwọn agbébọn kò dáwọ́ dúró, kódà, níṣe ni àwọn ìkọlù náà tún ń wáyé lákọ̀tun pàápàá sáwọn ilé ẹ̀kọ́ àtàwọn ilé ìjọ́sìn.

Àwọn kan gbàgbọ́ pé ohun tó ń ṣokùnfà àlékún ìkọlù àwọn agbébọn yìí kò ṣẹ̀yìn bí àwọn agbébọn náà ṣe ń rí owó gbà lẹ́yìn tí wọ́n bá jí àwọn èèyàn gbé tán.

Kí ló ń fa ìkọlù lemọ́lemọ́ yìí?

Ìbéèrè tó gbẹnu ọ̀pọ̀ èèyàn ni pé kí ló dé tí ìkọlù yìí fi ń wáyé lẹ́yìn ìdúnkokò Trump.

Akin Adeyi, onímọ̀ nípa ètò ààbò ní Nàìjíríà sọ pé nǹkan táwọn èèyàn tó ń da omi àlááfíà orílẹ̀ èdè Nàìjíríà rú ń wá ni pé kí àwọn olórí orílẹ̀ èdè àgbáyé ri pé Nàìjíríà kò tòrò.

Ó ní nítorí náà ni wọ́n ṣe gba ọ̀nà pé ìpanirun àwọn Kristẹni ń wáyé lójúnà àti lè tètè pe àkíyèsí wọn sí Nàìjíríà.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

"Èrò tí wọ́n fẹ́ kí gbogbo àgbáyé máa rò ni pé kò sí àlááfíà ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà, ní èyí tó padà rí àkíyèsí Ààrẹ Donlad Trump."

Adeyi ṣàlàyé pé láti lè jẹ́ kí ìgbàgbọ́ wà pé ohun tí wọ́n ń sọ jẹ́ òótọ́ ni wọ́n ṣe tẹ̀síwájú pẹ̀lú ìkọlù náà.

Ó ní èyí ló fà á tó fi jẹ́ pé wọ́n ń ṣe ìkọlù sáwọn ilé ìjọ́sìn àtàwọn ilé ẹ̀kọ́ tó jẹ́ ti Kristẹni lójúnà àti lè fẹ́ fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé òótọ́ ni àwọn ń sọ pé omi àlááfíà Nàìjíríà kò tòrò.

Ní ọ̀nà kejì ẹ̀wẹ̀, onímọ̀ nípa ètò ààbò náà ní pé ó ti fẹ́ di àṣà ní Nàìjíríà lásìkò tí ètò ìdìbò bá ti ń súnmọ́ kí àwọn èèyàn kan máa ṣe ìkọlù tàbí da ètò ààbò ìlú rú kó fi le dàbí pé ìjọba tó wà lóde kò kájú òṣùwọ̀n.

"Tí a bá ti fẹ́ dìbò, àwọn kan máa ń rò ó pé àǹfàní ló máa ń jẹ́ fún ìjọba tó bá wà lóde tí gbogbo orílẹ̀ èdè bá tòrò, tó tùbà, tùṣẹ.

"Láti lè ba ìjọba lórúkọ jẹ́, àwọn kan máa bẹ̀rẹ̀ ìkọlù nítorí wọ́n mọ̀ pé ohun tó lè gbé ọkàn àwọn ọmọ Nàìjíríà kúrò lọ́dọ̀ ẹni tó bá wà lórí ipò nìyẹn."

Adeyi wòye pé ìjọba Nàìjíríà gbọdọ̀ ti kẹ́kọ̀ọ́ látara ìṣẹ̀lẹ̀ àtàwọn ìkọlù yìí láti ri dájú pé wọ́n kò fi ọ̀rọ̀ ààbò falẹ̀, kí wọ́n sì máa ṣe ohun tó bá tọ́ lásìkò tó yẹ.

Àkójọpọ̀ àwọn ìkọlù gbòógì tó ti wáyé lẹ́yìn ìdúnkokò Trump

  • Ìkọlù ṣọ́ọ̀ṣì Kogi

Ní ọjọ́ Àìkú, ọjọ́ Kẹrìnlá, oṣù Kejìlá, ọdún 2025 láwọn agbébọn yabo ilé ìjọ́sìn Evangelical Church Winning All tó wà ní Aaaaz-Kiri ní agbègbè ìjọba ìbílẹ̀ Kabba/Bunu, ìpínlẹ̀ Kogi lásìkò tí ìjọ́sìn ń ló lọ́wọ́ tí wọ́n sì ṣíná ìbọn bolẹ̀.

Èèyàn mẹ́tàlá láwọn agbébọn náà jí gbé lọ, táwọn míì sì farapa nínú ìkọlù náà.

Kọmíṣánnà fétò ìròyìn ìpínlẹ̀ Kogi, Kingsley Fanwo ṣàlàyé pé agbébọm márùn-ún ló jáde láyé lásìkò ìkọlù ṣùgbọ́n àwọn yòókù wọn móríbọ́ bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n fara gbọta.

Ìgbà kejì rèé tí irúfẹ́ ìkọlù báyìí yóò wáyé láàárín ọ̀sẹ̀ méjì.

Ní ọ̀sẹ̀ méjì sẹ́yìn láwọn agbébọn ti kọ́kọ́ yabo ṣọ́ọ̀ṣì kan ní ìlú Ejiba, ìpínlẹ̀ Kogi kan náà, tí wọ́n sì jí pásítọ̀ kan, ìyàwó rẹ̀, àtàwọn ọmọ ìjọ míì gbé lọ.

Títí di àsìkò tí à ń kó ìròyìn yìí jọ, àwọn èèyàn tó wà ní àhámọ́ àwọn ajínigbé náà kò ì tíì gba ìtúsílẹ̀.

  • Ìkọlù sílé ẹ̀kọ́ St Mary Catholic School

Òru ọjọ́ Kọkànlélógún, oṣù Kọkànlá láwọn agbébọn yawọ ilé ẹ̀kọ́ St Mary's Catholic Schools, Papiri, ìpínlẹ̀ Niger tí wọ́n sì jí ọ̀pọ̀ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ àti olùkọ́ gbé lọ.

Alága ẹgbẹ́ àwọn ọmọlẹ́yìn Kristẹni, Christian Association of Nigeria, CAN tẹ̀ka ìpínlẹ̀ Niger, Ẹni ọ̀wọ̀ Bulus Dauwa Yohanna sọ pé èèyàn 315, tó fi mọ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ àtàwọn olùkọ́ láwọn ajínigbé náà gbé lọ.

Ṣùgbọ́n èyí fa awuyewuye láàárín CAN àti ìjọba ÌPÍNLẹ̀ Niger báwọn aláṣẹ ṣe sọ pé àwọn èèyàn tí ajínigbé gbé lọ kò tó bẹ́ẹ̀.

Ó sọ pé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ kan móríbọ́ lásìkò ìkọlù ọ̀hún, tí àwọn òbí sì ti ń lọ mú àwọn ọmọ wọn nítorí wọ́n máa ti ilé ẹ̀kọ́ náà pa fún ìgbà kan ná.

Ọjọ́ Keje, oṣù Kejìlá ni ìjọba kéde pé àwọn ti gba ìtúsílẹ̀ ọgọ́rùn-ún akẹ́kọ̀ọ́ nínú àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó wà ní àhámọ́ náà, tí àwọn yòókù sì wà ní àhámọ́ àwọn ajínigbé títí tí a fi ń kó ìròyìn jọ.

  • Ìkọlù ilé ìjọ́sìn CAC, Kwara

Ọjọ́ Ìṣẹ́gun, ọjọ́ Kejìdínlógún, oṣù Kọkànlá láwọn agbébọn yawọ ilé ìjọ́sìn CAC ti ìlú Eruku, ìpínlẹ̀ Kwara tí wọ́n sì ṣíná ìbọn bolẹ̀.

Èèyàn mẹ́ta ló pàdánù ẹ̀mí wọn lásìkò ìkọlù náà, tí àwọn agbébọn sì jí èèyàn méjìdínlógójì gbé lọ.

Ní ọjọ́ Kẹtàlélógún, oṣù Kọkànlá ni Ààrẹ Bola Tinubu kéde pé àwọn ti gba ìtúsílẹ̀ gbogbo àwọn èèyàn táwọn ajínigbé náà gbé lọ.

  • Ìkọlù sílé ẹ̀kọ́ ní Kebbi

Lásìkò tí ìdúnkokò Ààrẹ Donald Trump ń gbilẹ̀ làwọn agbébọn lọ ṣe ìkọlù sí ilé ẹ̀kọ́ kan ní ìpínlẹ̀ Kebbi, tí wọ́n sì jí àwọn èèyàn mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n gbé lọ.

Àwọn agbébọn náà jí olùkọ́ méjì àtàwọn akẹ́kọ̀ọ́ már]undínlọ́gbọ̀n gbé lọ ṣùgbọ́n tí ẹnìkan nínú àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà padà sá ma àwọn agbébọn náà lọ́wọ́.

Ọjọ́ Kẹtàdínlógún, oṣù Kọkànlá ni ìkọlù náà wáyé àmọ́ tí ìjọba kéde gbígba ìtúsílẹ̀ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ náà.

Gbogbo àwọn ìkọlù tó ń wáyé yìí ti ń mú kí àwọn èèyàn máa kọminú lórí ìpèníjà ààbò tó ń bá Nàìjíríà fínra.