Agbébọn tún kọlu ṣọ́ọ̀ṣì ní Kogi, pa èèyàn, jí ọ̀pọ̀ míràn gbé

Oríṣun àwòrán, Nigerian army
Ko din ni eeyan kan to tun padanu ẹmi rẹ ti ọpọlọpọ miran si tun ko sinu ahamọ awọn agbebọn lasiko ti awọn agbebọn tun kọlu ile ijọsin kan ni ipinlẹ Kogi, lẹkun aringbungbun ariwa orilẹede NAijiria.
Gẹgẹbi awọn alaṣẹ ṣe sọ, ikọlu naa waye lowurọ ọjọ Aiku ni ẹka ijọ Evangelical Church Winning All (ECWA) to w ani ileto Àaaaz-Kiri ni agbegbe ijọba ibilẹ Kabba/Bunu .
Oṣiṣẹ ijọba ipinlẹ Kogi kan to ba BBC News Sọrọ ṣugbọn ti ko fẹ ka darukọ oun nitori pe ko laṣẹ lati ba akọroyin sọrọ ṣalaye pe awọn agbebọn naa yawọ ile ijọsin naa lasiko ti iṣẹ isin n lọ lọwọ ti wọn si ṣina ibọn bolẹ nibẹ ki wọn to ko lara awọn olujọsin nibẹ lọ.
Awọn ileeṣẹ iroyin abẹle tig be iroyin irufẹ ikọlu bayii to waye lawọn agbegbe kan ni ipinlẹ naa sita ṣaaju akoko yii bi o tilẹ jẹ wi pe awọn alaṣẹ ko fi idi wọn mulẹ.
igba keji niyi laarin ọsẹ meji ti awọn agbebọn yoo maa ṣọṣẹ lagbegbe naa. Lọsẹ meji sẹyin awọn agbebọn y abo ile ijọsin kan ni ilu Ejiba nibi ti wọn ti ji pasitọ kan, iyawo rẹ atawọn ọmọ ijọ gbe lọ, wọn ko tii ri itusilẹ titi di akoko ti a n kọ iroyin yii pẹlupẹlu gbogbo akitiyan awọn ileeṣẹ agbofinro atawọn olugbe ibẹ.
Bi o tilẹ jẹ wi pe ijọba orilẹede Naijiria n lọgun pe awọn n sa ipa lati dẹkun gulegule abo to mẹhẹ sibẹ iṣẹlẹ yii n tan ina sidi bi ọrọ abo ti ṣe di eyi to n ko araalu laya soke.








