Ta a ni ojúlówó olùdíje sípò Gómìnà fẹ́gbẹ́ Accord ní ìpínlẹ̀ Osun? INEC sàlàyé

Oríṣun àwòrán, Senator Nuredeen Jackson Adeleke/Facebook
Lẹyin ti ẹgbẹ oṣelu Accord kede Gomina Ademola Adeleke gẹgẹ bi oludije sipo gomina fẹgbẹ naa lọsẹ to kọja, igun miran ninu ẹgbẹ Accord tun kede Clement Bamigbola gẹgẹ bi oludije sipo gomina fẹgbẹ kan naa lanaa ọjọ kẹrinla oṣu Kejila ọdun yii.
Igun ẹgbẹ Accord to ṣe agbatẹru eto idibo abẹnu lọjọ Aiku sọ pe eto idibo to gbe Adeleke wọle lodi si ofin ẹgbẹ naa.
Lati igba ti iroyin yii ti jade lọpọ eeyan ti n sọ ero wọn papaa julọ awọn eeyan ipinlẹ Osun.
Amọ, alaga ẹgbẹ Accord nipinlẹ Osun, Babalola Akande, ti sọ pe ẹgbẹ ti da awọn to ṣagbatẹru eto idibo abẹnu fun ipo gomina to waye lọjọ Aiku niluu Osogbo duro.
''Mo n fi da gbogbo eeyan loju wi pe gbogbo awọn to wa nidi awada kẹri kẹri ti wọn pe ni idibo abenu to waye lọjọ Aiku l'Osogbo ni wọn kii ṣe ọmọ ẹgbẹ Accord mọ.
Ati Ọgbẹni Fanibe to fi mọ Bamigbola ti wọn lo wọle eto idibo abẹnu naa, gbogbo wọn ni ẹgbẹ ti da duro.
Lati ọdun 2018 ni ẹgbẹ ti ni ki Fanibe lọ rọkun nile, tori naa, iru eeyan bayii ko lagbara kankan lori ẹgbẹ mọ lati ṣeto idibo kankan,'' Ọgbẹni Akande lo sọ bẹẹ.
Alaga ẹgbẹ Accord ni oun ko foya rara lori eto idibo ti wọn lawọn ṣe lọjo Aiku niluu Osogbo.
Amọ, o ni oun fẹ kawọn eeyan mọ pe ẹgbẹ oṣelu APC lo n lo awọn eeyan yii lati ṣe ipalara fun Gomina Adeleke.
O ni ko si ani ani nibi wi pe Adeleke ni oludije kan ṣoso ti yoo ṣoju ẹgbẹ oṣelu Accord ninu idibo gomina ipinlẹ Osun lọdun 2026.
Alaga ẹgbẹ Accord ni mimi kan ko le mi gomina Adeleke lati ma le dije fun ipo gomina labẹ asia ẹgbẹ Accord lọdun to n bọ.
Adeleke nikan ni a mọ gẹgẹ bii oludije sipo gomina fẹgbẹ Accord l'Osun - INEC
Ẹwẹ, ajọ eleto idibo INEC ti sọ pe Gomina Adeleke nikan lawọn mọ gẹgẹ bii oludije sipo gomina fẹgbẹ oṣelu Accord nipinlẹ Osun.
INEC sọ pe oun o gbọ nipa eto idibo abẹnu mii tabi ẹlomiran to wọle nibi eto idibo ọhun yatọ si Adeleke.
Ṣaaju ni Bamigbola ti wọn lo jawe olubori gẹgẹ bi oludije ibo abẹnu to waye lọjo Aiku niluu Osogbo ti sọ pe loootọ ni eto idibo ọhun waye, ati pe oun nikan lawọn aṣoju ẹgbẹ dibo yan nibi idibo naa.
Ṣugbọn ọga agba ajọ INEC nipinlẹ Osun ati agbenusọ fun ajọ naa, Musa Olurode, sọ pe INEC o mọ ohunkohun nipa eto idibo abẹnu to waye lọjọ Aiku.
Ọgbẹni Olurode ṣalaye pe INEC wa nibi eto idibo abẹnu nibi ti Adeleke ti wọle laarin ọsẹ to kọja.
O fikun ọrọ rẹ pe ajọ naa ko mọ nipa ẹlomiran gẹgẹ bii oludije sipo gomina fẹgbẹ oṣelu Accord mọ.















