Ọlọ́pàá fi kélé òfin gbé Peller, fi sí àtìmọ́lé lórí ìgbìyànjú láti wa ara rẹ̀ pa

Oríṣun àwòrán, Peller
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko ti fi ṣikun ofin mu alawada ori TikTok, Habeeb Hamzat ti ọpọ mọ si Peller, wọn si ti fi si atimọle.
Eyii ko ṣẹyin bo ṣe gbiyanju lati wa ara rẹ pa loju ọna marosẹ Lekki si Epe niluu Eko lọjọ Aiku.
Ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ ileeṣẹ naa, Abimbola Adebisi buwọlu, o ni awọn mu ọdọkunrin ọhun lẹyin ti fidio bo ṣe gbiyanju lati gbẹmi ara rẹ fa ori ayelujra ya.
Ọlọpaa ni ohun ti Peller ṣe ni pe o fẹ gbẹmi ara rẹ, o si fi awọn eeyan mii to n lo oju popo sinu ewu nla.
Atẹjade naa sọ pe "Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko ti mu Habeeb Hamzat, ti inagijẹ rẹ n jẹ 'Peller', wọn si ti fi si ahamọ fun iwadii lẹyin fidio rẹ to milẹ titi lori ayelujara lọjọ Aiku, ọjọ kẹrinla, oṣu Kejila, ọdun 2025 ninu eyii to ti wa ọkọ ni iwakuwa ko to sọ ori rẹ mọ igi lasiko to n ṣe fidio lori ayelujara.
"Iwa to hu fi han pe o fẹ pa ara rẹ, o tun n fi ẹmi awọn eeyan mii loju popo sinu ewu."
Kọmiṣọna ọlọpaa ipinlẹ Eko, Olohundare Jimoh, naa tun kilọ fun awọn gbajumọ ori ayelujara ki wọn ṣọra ninu lilo oju opo ayelujara wọn fun nnkan to lewu.
O ni "Ọlọpaa ko ni faaye gba irufẹ itapa sofin bẹẹ, ẹnikẹni to ba ṣe iru rẹ yoo si jẹ iyan rẹ niṣu."
Ẹwẹ, ajọ to n ri si aabo oju popo, FRSC naa ti ke si ijọba ko ba Peller ṣe ẹjọ lori iwakuwa rẹ loju popo.
Wayi o, lẹyin iṣẹlẹ naa ni Peller dero ile iwosan amọ o ṣoro lati mọ ipo ti ilera rẹ wa bayii.
Ọpọ araalu lo ti bẹrẹ si n fi erongba wọn lede loju ayelujara lori iṣẹlẹ naa.
Peller yóò fojú balé ẹjọ́ fún bó ṣe fẹ́ wa ara rẹ̀ pa-FRSC

Oríṣun àwòrán, Habeeb Hamzat (Peller)/Facebook
Latari bi gbajumọ sọrọsọrọ ori TikTok, Habeeb Hamzat tawọn eeyan mọ si Peller ṣe fẹ wa ara rẹ pa lanaa ode yii, ajọ to n ri si aabo loju popo, FRSC, ti ni oun yoo pe e lẹjọ.
Aṣẹ ipẹjọ naa waye lati ọwọ ọga agba FRSC, Shehu Mohammed, ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ ajọ naa, Olusegun Ogungbemide, buwọ lu.
Ọga agba FRSC paṣẹ, pe ẹka ajọ naa fun ipinlẹ Eko gbọdọ bẹrẹ igbesẹ ipejọ yii lẹyẹ o sọka.
O ṣapejuwe iwa ti Peller hu bi aṣa kan to ti n gbilẹ laaarin awọn adanilaraya lori ayelujara, eyi to lodi sofin to si tun lewu.
FRSC sọ pe iwa aibikita ti Peller hu loju popo marosẹ Lekki le fa iku ọpọ eeyan mi-in loju popo naa, yatọ si ti oun funra rẹ to fi ẹmi ara rẹ wewu.
"Ki eyi maa jẹ iranti, pe jijẹ gbajumọ ko tumọ si pe eeyan kọja ofin, bẹẹ ni ko sọ pe ki eeyan huwa to lewu loju ọna ti gbogbo eeyan n rin.
"Siṣe fidio lojukoroju, kika aworan silẹ tabi ṣiṣe ohunkohun to le mu ki ọkan awakọ kuro nibi ọkọ to n wa, jẹ iwa to lodi si ofin irinna, o si tun le ṣokunfa ijamba fun awakọ ati awọn eeyan mi-in lojuu popo.
Bẹẹ ni atẹjade ajọ FRSC naa wi.
Wọn fi kun un pe lilo foonu lasiko ti awakọ n wa ọkọ lọwọ lodi sofin, ati pe ajọ naa ko ni i wo oju ẹni yowu to ba lufin yii, dandan ni ko foju bale ẹjọ.
Wọn ko ṣai rọ ajọ Actor's Guild to n ri si ọrọ awọn oṣere ati amuludun, lati fi ewe ọ̀mọ̀ mọ́ awọn eeyan wọn leti, ki wọn dẹkun iwa to le ṣi awon eeyan to n wo wọn lawokọṣe lọna, nitori ẹni ti a n wo ki i woran.
Bakan naa ni FRSC kilọ, pe ki awọn to n fi ayelujara pa owo lọ mọ, pe ko si 'kọntẹnti' to to ki ẹmi eeyan sọnu.
Ajọ naa sọ pe ẹni to n bẹ laye lo le ri nnkan gbe sori ayelujara.
Bi ẹnikẹni ba waa kẹẹfin ẹnikan to n tori ohun to fẹ gbe sori ayelujara, to n huwa to le fa ijamba ọkọ fun araalu, to n ṣe fidio tabi huwa to le fa ijamba si ara rẹ tabi ara yoku lọrun, FRSC ni ki ẹ ma ṣe dakẹ.
Ẹ tete fi to ẹka to yẹ leti, ka le jọ dẹkun ijamba ọkọ loju opo wa bi wọn ṣe sọ.
Kí ló mú Peller tó fi fẹ́ wa ara rẹ̀ pa?

Oríṣun àwòrán, Peller/X/RDapsychoo
Alawada ori TikTok, Habeeb Hamzat, ti ọpọ mọ si Peller ti dero ile iwosan lẹyin to mọọmọ fi ori ọkọ rẹ sọgi niluu Eko lọjọ Aiku.
Oju ọna marosẹ Lekki-Epe lo ti mọọmọ fi ọkọ naa sọ igi lasiko to n ba awọ eeyan sọrọ lori ayelujra.
Peller wa ọkọ ayọkẹlẹ Mercedes-Benz rẹ pa lẹyin to ba ẹnikan sọrọ lori ẹrọ ilewọ to si sọ pe inu oun bajẹ gidi.
Awọn eeyan ni ọrẹbinrin rẹ lori ayelujra, Jarvis lo ba sọrọ ṣaaju igbesẹ naa.
A gbọ pe eredi igbeseẹ lati pa ara rẹ ọhun ko ṣẹyin bi tirela ṣe gba aarin oun ti Jarvis kọja.
Lasiko to n ba awọn ololufẹ rẹ naa sọrọ lori ayelujara ṣaaju iṣẹlẹ ọhun, o ni "mo maa wa ọkọ yii pa lọwọlọwọ bayii," lẹyin naa lo bẹrẹ si n pariwo "ẹru n ba mi, ẹru n ba mi."
Ninu ọrọ to n ba awọn ololufẹ rẹ naa sọ lo tun ti sọ pe "ti o ba kọ mi silẹ, awọn eeyan yoo fi mi ṣe ẹlẹya… mo maa pa ara mi."
Bo ṣe n sọrọ naa lọwọ lo mọọmọ wa ọkọ rẹ to si lọ fi ori ọkọ naa sọ okuta kan, eyii to ba iwaju ọkọ naa jẹ.
Ninu fidio mii ti a fogu ganni ni awọn eeyan to wa layika ibi to ti mọọmọ ni ijamba naa ti n saajo rẹ ti wọn si n gbiyanju lati doola rẹ.
A ko tii le sọ bi ọdọkunrin naa ṣe ṣeṣe to lasiko ti a n ko iroyin yii jọ amọ awọn aworan ti a ri ṣafihan bi ọkọ ọhun ṣe bajẹ to.
Ki ni idi ti peller fi fẹ wa ara rẹ pa?

Oríṣun àwòrán, peller
Iroyin to n lọ ni igboro ni pe igbesẹ Peller yii ko ṣẹyin bi oun ati ololufẹ rẹ , Javis ṣe pin gaari.
Ṣaaju ki wọn to tuka lawọn mejeji ti maa n ja lori ayelujara amọ nigba mii awọn eeyan yoo sọ pe eremọde 'criuse' lasan ni.
Wayi o, ọpọ araalu lo ti n fi erongba wọn lede nipa iṣẹlẹ naa.
Bi awọn kan ṣe n fi oko ọrọ ranṣẹ si ọdọkunrin naa lawọn mii n sọ pe ọrọ obinrin ko to nnkan ti eeyan n pa ara rẹ si.
Bẹẹ lawọn miran ni Peller gbọdọ foju wina ofin latari bo ṣe fẹ gbẹmi ara rẹ nitori o lodi si ofin ki eeyan gbẹmi ara rẹ ni Naijiria.















