Èèyàn méjì jáde láyé, àwọn mẹ́sàn-án farapa bí agbébọn ṣe ṣèkọlù sílé ẹ̀kọ́ gíga

Ọkùnrin àti obìnrin kan tó dì mọ́ra wọn

Oríṣun àwòrán, Reuters

    • Author, Jessica Murphy
    • Author, Ottilie Mitchell
  • Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ní orílẹ̀èdè Amẹ́ríkà ti bẹ̀rẹ̀ ìwádìí láti ṣàwárí ọkùnrin kan tó ṣekúpa àwọn akẹ́kọ̀ọ́ méjì táwọn mẹ́sàn-án míì sì farapa bó ṣe ṣíná ìbọn bolẹ̀ fún wọn nílé ẹ̀kọ́ gíga Brown University, Providence, Rhode Island.

Ní nǹkan bíi aago mẹ́rin ìrọ́lẹ́ ọjọ́ Àbámẹ́ta ni ìṣẹ̀lẹ̀ náà wáyé lásìkò tí ètò ìdánwò àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ọ̀hún ń wáyé.

Ilé ẹ̀kọ́ gíga fásitì náà tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ilé ẹ̀kọ́ tó ti pẹ́ jùlọ ní Amẹ́ríkà ni wọ́n ti tìpa báyìí, táwọn ọlọ́pàá sì ń wá ọkùnrin tó ṣe ìkọlù náà, ẹni tó tin a pápá bora.

Àwọn aláṣẹ ní káwọn akẹ́kọ̀ọ́ wá ibi forí pamọ́ sí títí tí àwọn ọlọ́pàá fi ma le sìn wọ́n kúrò nínú ọgbà ilé ẹ̀kọ́ náà.

Àwọn aláṣẹ ilé ìwòsàn Rhode Island Hospital sọ pé ọ̀pọ̀ àwọn tó farapa náà ló ṣèṣè gidi àmọ́ tí ara wọn ti ń balẹ̀.

Àwọn aláṣẹ kò ì tíì fi orúkọ àwọn tó jáde láyé àtàwọn tó farapa léde.

Ààrẹ ilé ẹ̀kọ́ Brown University, Christina Paxson nínú àtẹ̀jáde kan sọ pé ìṣẹ̀lẹ̀ náà jẹ́ ọjọ́ mánigbàgbé fún àwọn nítorí àwọn kò lérò pé irúfẹ́ ìṣẹ̀lẹ̀ bẹ́ẹ̀ lé wáyé ní ilé ẹ̀kọ́ àwọn.

Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ní àwọn furasi pé ọkùnrin ni ẹni náà àmọ́ wọn ò lè sọ bóyá ó ní àjọṣepọ̀ kankan pẹ̀lú ilé ẹ̀kọ́ ọ̀hún.

Àwòrán CCTV ṣàfihàn bí afurasí náà ṣe ń jáde nínú ilé náà lẹ́yìn ìkọlù náà ṣùgbọ́n ojú rẹ̀ kò hàn.

Igbákejì ọ̀gá ọlọ́pàá, Tim O'Hara sọ pé afurasi náà wọ aṣọ dúdú, tó sì daẹ̀kú bo ojú. Wọ́n ní àwọn kò lè sọ irúfẹ́ ohun ìjà ogun tó wà lọ́wọ́ rẹ̀ nítorí wọn kò ì tíì ri gbà lọ́wọ́ rẹ̀.

"À ń lo gbogbo ohun tó yẹ láti ṣàwárí afurasí yìí," ó fi kun pé àwọn ti kó ọ̀pọ̀ àwọn ọlọ́pàá sí agbègbè náà láti wá gbogbo ibẹ̀.

Ní ilé Barus àti Holley, tó jẹ́ lára yàrá ìkẹ́kọ̀ọ́ ìmọ̀ ẹ̀rọ ni ìkọlù náà ti wáyé.

Ọ̀jọ̀gbọ́n nípa ìmọ̀ ètò ọrọ̀ ajé sọ fún iléeṣẹ́ ìròyìn Ocean State Radio sọ pé ìpànìyàn náà wáyé lásìkò tó ń ṣe àyẹ̀wò ètò ìkẹ́kọ̀ọ́ lọ́wọ́.

Àkọlé fídíò,
Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Rachel Friedberg ní afurasí náà wọlé tó sì pariwo ohun tí òun kò rántí mọ́, tó sì bẹ̀rẹ̀ sí ní yìnbọn.

"Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ bẹ̀rẹ̀ sí ní sá àsálà fún ẹ̀mí ara wọn láti má fara gbọta, tí wọ́n sì sábẹ́ ìjókòó ní pápá ìṣeré ṣùgbọ́n síbẹ̀ àwọn èèyàn ṣì fara gbọta.

Àwọn aláṣẹ ní àwọn ti gbọn gbogbo ilé ẹ̀kọ́ náà yẹ́bẹ́yẹ́bẹ́ síbẹ̀ wọn ò rí afurasí náà tàbí ìbọn tàbí ohun ìjà olóró míì.

Àwọn aláṣẹ sọ fún àwọn olùgbé ní agbègbè Brown University láti wà nínú ilé títí tí wọ́n fi máa sọ fáwọn èèyàn láti máa jáde.

Steph Machado, akọ̀ròyìn iléeṣẹ́ ìròyìn Boston Globe sọ fún BBC News pé gbogbo àwọn ilé oúnjẹ tó wà ní agbègbè ilé ẹ̀kọ́ náà ni wọ́n ti ní kó wà ní títìpa.

Ṣáájú ni wọ́n kọ́kọ́ sọ pé ọwọ́ ti tẹ afurasí kan ṣùgbọ́n wọ́n tètè sọ pé ẹni náà kò lọ́wọ́ nínú ìkọlù náà.

Mari Camara, ẹni ogún ọdún, tó jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ Brown University sọ fún Associated Press pé òun ń kúrò ní yàrá ìkàwé ni ìṣẹ̀lẹ̀ náà wáyé, tí òun sì sáré wọ ilé oúnjẹ kan lọ láti sá àsálà fún ẹ̀mí òun.

"Níṣe ni ẹ̀rù ń ba gbogbo èèyàn bíi èmi náà, pé irú ìṣẹ̀lẹ̀ báyìí le wáyé."

Àwọn aláṣẹ ti wọ́gilé ètò ìdánwò tó yẹ kó wáyé lọ́jọ́ Àbámẹ́ta gẹ́gẹ́ bí Frank Doyle ṣe sọ.

Ààrẹ Donald Trump nígbà tó ń bá àwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀ sọ pé ìṣẹ̀lẹ̀ tó burú gbá à ni ìkọlù náà jẹ́.

Trump ní ohun tí àwọn lè máa ṣe báyìí ni láti gbàdúrà fáwọn tó forí sọgbà ìkọlù náà.

Gómìnà Rhode Island, Dan McKee sọ nínú àtẹ̀jáde kan pé ìkọlù ńlá wáyé ní olú ìlú náà tó sì ní ọkàn àwọn sì wà pẹ̀lú àwọn èèyàn Providence àtàwọn tí ọ̀rọ̀ náà kàn.

Ìkọlù sí ilé ẹ̀kọ́ yìí jẹ́ kí ìṣẹ̀lẹ̀ ìpànìyàn ní US di 389 lọ́dún yìí nìkan gẹ́gẹ́ bí ìtàkùn ayélujára Gun Violence Archive, GVA ṣe sọ.

Ó júwe ìpànìyàn ọlọ́pọ̀ èrò bíi tí èèyàn mẹ́rin tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ bá pàdánù ẹ̀mí wọn tàbí farapa níbi ìkọlù náà tó fi mọ́ ẹni tó ṣèkọlù.