Ìbẹ̀rù bojo gbalẹ̀ lẹ́yìn táwọn jàndùkú ajínigbé tún jí èèyàn mẹ́fà gbé lọ ní Kwara

Oríṣun àwòrán, Kwara Police
Ibẹru bojo ti gbalẹ ni ilu Ijara Isin,ni ijọba ibilẹ Isin ipinlẹ Kwara latari iṣẹlẹ ijinigbe to waye nibẹ.
Laaarọ ọjọ Aje, ọjọ kẹẹdogun oṣu Kejila yii lawọn ajinigbe ya wọ Gaa awọn Fulani ilu naa ti wọn si ji eeyan mẹfa gbe lọ.
Ọgbẹni Usman ẹni ti iṣẹlẹ naa soju rẹ sọ fun BBC Yoruba pe ṣadeede ni awọn ajinigbe naa ya wọle ni nnkan bi ago marun un idaji ọjọ Aje.
Ọgbẹni Usman sọ pe nise ni ibọn n ro lakọlakọ ni idaji lasiko ti wọn kọlu Gaa naa.
O fidi rẹ mulẹ pe eeyan mẹfa lawọn kọlọnbiti ẹda naa ji gbe lọ ni Ijara Isin.
Ọkan lara ọmọbibi ilu naa to ba BBC Yoruba sọrọ lori ikọlu naa, Ọgbẹni Ṣẹgun sọ pe, Gaa awọn Fúlàní naa ko jinna si ilu Ijara Isin wọn si ti wa ni agbegbe naa ti pẹ.
O fikun ọrọ rẹ pe ni nnkan bi ago marun un idaji lawọn ṣadeede ri awọn eeyan to n sa bọ lati Gaa tọrọ si di bo o lọ ya n mi lagbegbe naa ti onikaluku si sa kuro ni ile lagbegbe naa.
Ọmọ ilu naa mii to ba BBC Yoruba sọrọ Ọgbẹni Kunle sọ pe awọn ọdẹ ati awọn fijilante ti wọ inú igbo lọ bayii lati doola awọn ti wọn ji gbe.
O ni iṣẹlẹ naa ti ko ipaya ba awọn eeyan ilu ọhun ti gbogbo ara ilu si kaya soke.
O salaye pe iṣẹlẹ ijinigbe naa ko jẹ kawọn eeyan o raye lọ soko mọ ni ijọba ibilẹ naa lati ṣiṣẹ eto ọgbin wọn.
Ninu atejade kan ti ọba ilu naa Ọba Ademọla Ajibọla fi sita, kabiyesi naa rọ awọn eeyan ilu naa lati lọ f'ọkan balẹ.
O tẹsiwaju pe ko ni si ewu kankan ni ilu naa tori oun n ṣiṣẹ pọ pẹlu awọn ẹṣọ eleto abo lati ri pe eto abo fẹsẹ mulẹ nibẹ.
Ọba Ajibola ṣalaye siwaju si pe awọn ti wọn ji gbe lọ naa yoo pada de ni alaafia pẹlu bawọn ọdẹ atawọn ẹṣọ eleto aabo ti n ṣiṣẹ lati daabo bo awọn ara ilu ti wọn sì tun gbiyanju lati doola awọn ti wọn ji gbe lọ.















