Gamboli tó ń ta egbòogi olóró fáwọn agbébọn wọ gbaga NDLEA nipinlẹ Niger

Sani Mohammed (Gamboli) ree to gbe patako ẹsun ti wọn fi kan an dani. Awọn egboogi oloro ti wọn ba nile rẹ lo wa ninu apo lẹyin rẹ yẹn

Oríṣun àwòrán, NDLEA/X

Àkọlé àwòrán, Sani Mohammed (Gamboli) ree to gbe patako ẹsun ti wọn fi kan an dani
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ajọ National Drug Law Enforcement Agency (NDLEA) to n gbogun ti gbigbe egboogi oloro lorilẹede yii ti kede pe ọwọ awọn ti ba ọkunrin kan, Mohammed Sani tawọn eeyan mọ si Gamboli, ẹni to maa n ta egboogi oloro fun awọn agbebọn nipinlẹ Niger.

Ninu atẹjade ti Femi Babafemi, Adari ikede fun NDLEA fi sita lanaa ọjọ Aiku lo ti ṣalaye, pe lẹyin ọsẹ kẹta ti ajọ naa ti fẹ mu Gamboli ṣugbọn to n sa mọ wọn lọwọ ni ọwọ ṣẹṣe ba a.

Atẹjade naa sọ pe ogunjọ oṣu Kọkanla ni NDLEA ti kọkọ lọ tu ile Gamboli to wa ni Anguwan Makera, Kuta,nipinlẹ Niger wo, ṣugbọn wọn ko ri oun funra rẹ mu lọjọ naa.

Egboogi oloro kan ti wọn n pe ni skunk ti iwọn rẹ jẹ 471.8 kg ni wọn ri gbe ninu ile naa bi ajọ yii ṣe fidi ẹ mulẹ.

Báwo ni wọ́n ṣe padà rí Gamboli mu?

Alaye ajọ NDLEA ni pe olobo ti ta awọn ṣaaju, pe Gamboli n wọle wọde pẹlu awọn agbebọn kan nijọba ibilẹ Shiroro, nipinlẹ Niger, ati pe oun lo n ba wọn wa oogun oloro ti wọn n mu.

Eyi lo jẹ ki wọn maa dọdẹ rẹ, ti wọn si fi lọ yẹ ile rẹ wo loṣu kọkanla, ṣugbọn ti wọn ko ri i mu.

Adari ikede NDLEA ṣalaye pe ikọ awọn dọdẹ Gamboli titi tọwọ fi ba a ni ọkan lara awọn ibi to n ta ọja to lodi sofin naa si, iyẹn ni Anguwan Fadama, Kuta, ipinlẹ Niger.

O ni nibẹ ni awọn si ti fi ọwọ ofin mu un lọjọ kọkanla, oṣu Kejila ọdun 2025 yii.

Igbagbọ wa pe lara irinṣẹ awọn agbebọn ni oogun oloro mimu naa wa, nitori oju lasan ko ṣee ṣe iṣẹ aburu ti wọn n ṣe.

Eyi ni wọn ṣe maa n mu awọn eroja ti yoo fun wọn ni agbara òdì naa, paapaa bi wọn ba fẹ lọ kọlu awọn ilu ti wọn yoo tun palẹkun.

Egboogi naa lo maa n jẹ ki oju wọn yipada, ti wọn yoo fi da ọpọ ẹmi lẹgbodo, gbe awọn miran wo igbo lọ lai ṣaanu ẹnikẹni.

Ọkan lara awon ipinle Oke Oya ti awọn agbesunmọmi n da laamu si ni ipinlẹ Niger naa jẹ.

Ẹni ọdun mẹtalelọgbọn (33) ni Gamboli to n ta a fun wọn yii bi NDLEA ṣe sọ.