Ìdí táwọn èèyàn fi ń pè fún ìyọnípò mínísítà abẹ́nú fún ètò ààbò, Bello Matawalle?

Oríṣun àwòrán, Bello Matawalle/X
Ọpọ ọmọ Naijiria lo ti n pe fun iyọnipo minisita abẹnu fun eto aabo ni Naijiria, Bello Matawalle.
Idi abajọ ni pe wọn ni Matawalle ni ajọṣepọ pẹlu awọn janduku agbebọn to n ṣọṣẹ lapa ariwa orilẹede Naijiria.
Koda, awọn kan tiẹ sọ pe ki Matawalle kọwe fipo rẹ silẹ, ki ijọba si ṣewadii awọn ẹsun ti wọn fi kan an.
Amọ, Metawalle ni awọn to n fẹsun kan oun ti tọwọ oṣelu bọ ọrọ naa, ati pe irọ nla lẹsun ti wọn ka soun lọrun.
O ni ọjọ ti pẹ tawọn kan lagbo oṣelu ti wọn n wa iṣubu oun ti maa sọ oriṣiiriṣii nnkan to jẹ irọ nipa oun.
Ọrọ yii tun jẹ jade lẹyin ti oludamọran Matawalle tẹlẹ, Musa Muhammad Kamarawa, ṣe fidio kan ninu eyi to ti fẹsun kan an wi pe o maa n fawọn janduku agbebọn lowo, koda o ni Matawalle tun ra ọkọ, ile, nnkan ọsin atawọn nnkan mii fawọn janduku agbebọn.
Idi niyi tawọn agbẹjọro kan fi kepe minisita abẹnu fun eto aabo lati kọwe fipo rẹ silẹ ki ijọba le ṣewadii rẹ.
''Ti Matawalle ko ba kọwe fipo silẹ, a o gbe e lọ sile ẹjọ''
Adari awọn amofin naa, Hamza Nuhu Dantani, sọ fun BBC wi pe ''Matawalle ni lati kọwe fipo silẹ kawọn agbofinro si fọrọ wa a lẹnu wo.
Ti ko ba si ṣe eleyii, a o gbe e lọ si ile ẹjọ funra wa.''
Ẹwẹ, kọmiṣọna fun eto iroyin nigba ti Matawalle fi jẹ gomina ipinlẹ Zamfara, Ibrahim Dosara, sọ pe ẹsun ti wọn fi kan Matawalle kii ṣe tuntun rara.
''O ti pẹ tawọn eeyan ti maa n sọrọ yii lati igba ti Matawalle ti ṣe ifọrọwerọ pẹlu awọn agbebọn ni ipinlẹ Zamfara ki alaafia le jọba nibẹ.
Matawalle n wa gbogbo ọna ti alaafia fi le jọba nipinlẹ Zamfara nigba naa ni, latari bawọn janduku naa ṣe n fẹmi awọn eeyan ṣofo.
Ẹsun ti wọn fi kan Matawalle ko lẹsẹ nlẹ rara, nitori eto idibo ọdun 2027 to n bọ lawọn eeyan to n sọrọ naa fi n ṣe bẹẹ.
Ẹru n bawọn wi pe o le ṣewadii wọn pẹlu ipo to wa, o si le fiya jẹ wọn,'' Dosara lo sọ bẹẹ.















