Èyí ni bí Bàbá àtọmọ ṣe yìnbọn pa èèyàn mẹ́ẹ̀ẹ́dógún létíkun Australia

Ahmed al Ahmed, akọni to gba ibọn lọwọ baba to n yinbọn, Sajid Akram, ree lori ibusun nileewosan, Chris Minns, Olootu ẹkun Wales to ṣabẹwo si i lo jokoo niwaju rẹ.

Oríṣun àwòrán, Facebook/Chris Minns

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 7

Ipaniyan to waye lalẹ ọjọ Aiku ana lorilẹede Australia ni iwadii ti fidi ẹ mulẹ, pe baba ati ọmọ ni awọn eeyan meji naa ti wọn yinbọn pa awọn eeyan leti okun Bondi.

Ko din ni eeyan mẹẹẹdogun ti won ti di oloogbe nipaṣe ibọn ti baba kan , Sajid Akram; ẹni aadọta ọdun (50) ati ọmọ rẹ, Naveed, ẹni ọdun mẹrinlelogun (24) yin lu awọn eeyan letikun naa.

Nigba ti yoo fi di aarọ ọjọ Aje oni, ọjọ kẹẹẹdogun oṣu Kejila, eeyan to to ogoji ni wọn wa nileewosan, ti wọn n gba itọju latari ifarapa nibi ibọn to ba wọn.

Ṣaaju ni awọn ọlọpaa orilẹede naa ti fidi ẹ mulẹ, pe Sajid, baba to yinbọn nibi ikọlu naa ti ku ni tiẹ, nigba ti akọni kan, Ahmed al Ahmed, koju rẹ to si le e titi to fi gba ibọn naa lọwọ rẹ.

Naveed, ọmọ baba to yinbọn paapaa pada ko tirẹ loju ija naa, bo tilẹ jẹ pe ko ku, ṣugbọn oun naa ṣi wa nileewosan.

Ọpọ eeyan lo ti n fi ẹjẹ silẹ fun awọn to padanu ẹjẹ ninu ikọlu yii ni Australia, bẹẹ ni wọn n dawo fun Ahmed al Ahmed, akọni ti ko jẹ ki ikọlu naa le ju bẹẹ lọ.

Ahmed naa ṣi wa nileewosan lasiko ti a n kọ iroyin yii, Olootu ẹkun South Wales, Chris Minns, si ti ṣabẹwo si I nibẹ, o ṣapejuwe rẹ bii akọni gidi.

Awọn won ni wọn tori ẹ bẹrẹ si i yinbọn gan-an?

Awọn Jew to n tan abẹla lẹyin ikọlu naa

Oríṣun àwòrán, TESA WONG/BBC

Gẹgẹ bi iwadii BBC, awọn Jew kan ti wọn n ṣe ayẹyẹ wọn ti a mọ si Hanukkah, letikun naa ni awọn agbebọn meji ọhun tori rẹ bẹrẹ rogbodiyan.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

A gbọ pe baba atọmọ to yinbọn naa ti ṣeleri fun ijọ ẹlẹsin Islam ilu naa pe awọn yoo koju awọn Jew.

Iroyin sọ pe ikọlu naa ni i ṣe pẹlu ọrọ ẹsin, bo tilẹ jẹ pe awọn eeyan ti ko ṣẹ wọn lẹṣẹ kan ni wọn sọ di oloogbe lojiji.

Koda, ọmọ kekere ti ọjọ ori rẹ ko ju mẹwaa lọ wa ninu awọn to ku, bẹẹ si ni awọn alagbalagba ati awọn mi-in ti wọn ti di ogbó naa ku lati ara ọta ibọn to ba wọn.

Bi ko ba si ti Ahmed al Ahmed, akọni to koju awọn agbebọn naa, awọn eeyan ti ko ba di oku ko ba pọju bẹẹ lọ bi awọn eeyan ilu naa ṣe sọ.

Ẹẹmẹrin si ẹẹmarun-un ni wọn yinbọn mọ Ahmed naa lejika bi awọn obi rẹ ṣe sọ.

Nigba to n sọrọ nipa lilo ibọn ni ilu naa, Olootu ijọba Australia, Anthony Albanese, sọ pe oun yoo ri i pe ofin to de ibọn lilo lagbara si i bayii.

O ni eyi ṣe pataki lati dena aṣilo ibọn.

Ni ti Sajid Akram, baba toun ati ọmọ rẹ yinbọn yii, o ni iwe aṣẹ lati lo ibọn naa fun ṣiṣe ṣọdẹ etile, ki i ṣe lati fi pa alaiṣẹ tabi da wahala silẹ bi eyi.

Awọn alaṣẹ ti kede pe ile ẹkọ kan to wa nitosi okun Bondi naa yoo ṣi wa ni titipa na, pẹlu bo ṣe sunmọ ibi ti iṣẹlẹ naa ti waye.

Wọ́n rí asia orilẹede Islam meji ninu ọkọ awọn agbebọn naa

Ọkan lara awọn ọkọ ti wọn gbe kuro nibi iṣẹlẹ naa ni aarọ Monde oni

Oríṣun àwòrán, AP

Gẹgẹ bi ọkan lara awọn oṣiṣẹ to n ri si iṣẹlẹ yii ṣe ṣalaye fun ileeṣẹ iroyin Australia, ABC News, o ni asia meji to jẹ ti orilẹede Islam ni awọn ba ninu ọkọ awọn agbebọn naa.

O ni asia kan wa niwaju ọkọ naa.

Naveed Akram, ọmọ to yinbọn, ni iwadii ti kọkọ fidi ẹ mulẹ pe alajọṣe ni pẹlu awọn ikọ alakatakiti ẹsin Islam kan ti wọn wa ni Sydney.

Olootu ijọba Australia, Anthony Albanese, sọ pe oṣu Kẹwaa ọdun 2019 ni awọn alaṣẹ kọkọ gbọ nipa Akram, ṣugbọn wọn ko fidi rogbodiyan kankan nipa rẹ mulẹ nigba yẹn.

Bakan naa ni ikọ iroyin ABC ṣalaye pe ẹka to n ri si igbesunmọmi nileeṣẹ ọlọpaa Australia, gbagbọ pe Naveed ati baba rẹ, Sajid, ni nnkan pọ pẹlu awọn ẹgbẹ agbesunmọmi IS.

'A ti wa lẹnu ẹ tipẹ, imọlẹ ni yoo maa leke lọjọ gbogbo-Awọn Jew'

Kete lẹyin ikọlu naa, awọn Jew kan kora jọ, wọn tan abẹla yẹẹ-yẹẹ-yẹẹ lẹgbẹ etikun Bondi, lati fi kede pe ikọlu kan ko ni i bori awon.

Wọn kede pe oju awọn ti ri ọpọ idaamu ri, ṣugbọn awọn bori rẹ.

Wọn ni eyi to ṣẹlẹ yii naa ko ni i ki awọn ma ṣe Jew mọ, nitori imọlẹ ni yoo maa leke lọjọkọjọ.

Awọn Jew naa sọ pe awọn n tan abẹla lalẹ ikọlu naa, ni ibamu pẹlu ọdun Hanukkah tawọn maa n ṣe.

Ati pe abẹla titan ti alẹ ana yii wa fun iranti awọn to ba ikọlu naa lọ ni.

"A n pe awọn eeyan lati gba imọlẹ laaye, ki wọn jẹ olufẹ alaafia ati igbamọra. A ti leke fun ẹgbẹrun ọdun, imọlẹ ni yoo maa leke lọjọ gbogbo"

Bẹẹ ni ọkan ninu awọn Jew naa wi.

Bi wọn ṣe tan abẹla naa ni wọn kọrin Jew, awọn mi-in si n sunkun kikoro ni iranti awon to di oloogbe.

Bẹẹ ni wọn ṣe titi ki wọn too maa kọrin orilẹede Australia ati awọn orin Jew miran.

Eeyan meji lo ti w ani ahamọ ọlọpaa lori iṣẹlẹ yii bi ileeṣẹ ọlọpaa Australia ṣe wi, a o maa mu itẹsiwaju iroyin yii wa bo ṣe n ṣẹlẹ ni Australia.

Agbébọn ṣíná ìbọn fún àwọn tó ń ṣe fàájì létí òkun Australia, èèyàn méjìlá jáde láyé

Awọn ọlọpaa Australia

Oríṣun àwòrán, Getty Images

O kere tan, eeyan mejila lo ti jade laye lẹyin ti ọkunrin meji ṣina ibọn bolẹ fun awọn eeyan to n ṣe faaji leti okun Bondi, lorileẹde Australia.

Atẹjade lati ọọfisi ọlọpaa New South Wales sọ pe awon ti n wa awọn agbebọn naa.

Ọlọpaa ni "a le fidi rẹ mulẹ pe eeyan mẹjila lo ti jade laye, ti a si gbagbọ pe ọkan ninu wọn jẹ ọkan ninu awọn to ṣiṣẹ naa.

"Lọwọ yii, eeyan mọkanla ni a mọ to farapa, ti meji ninu wọn si jẹ ọkunrin."

Ileeṣẹ ọlọpaa fi kun pe awọn ti n ṣe ayẹwo awọn nnkan ti funra si pe o le ran iwadii awọn lọwọ nibẹ.

Olootu ijọba Anthony Albanese ti juwe iṣẹlẹ naa gẹgẹ bii eyii to buru jọjọ.

O ni "Awọn ọlọpa atawọn adoola ẹmi ti wa ni ikalẹ lati bojuto iṣẹlẹ naa, mo si ba gbogbo awọn ti ọrọ naa kan kẹdun."

Awọn aworan kan lori ayelujara ṣafihan bi ọkan lara awọn eeyan to wa leti okun naa ṣe n ba ọkan ninu awọn agbebọn naa figagbaga to si gba ibọn ọwọ rẹ.

Ninu inu fidio kan naa ni ẹlomiran ti n yin ibọn si apa ibi ti ọkunrin to gba ibọn naa wa.

Ọkan lara awọn ti iṣẹlẹ naa ṣoju wọn, Camilo Diaz, to jẹ ọmọ orilẹede Chile sọ pe niṣe loun kan n gbọ iro ibọn lerealera.

O sọ fun ileeṣẹ iroyin AFP pe oun gbọ iro ibọn kikankikan fun nnkan bii iṣẹju mẹwaa.

Ileeṣẹ iroyin Australia, Australian Broadcasting Corporation (ABC) sọ pe awọn kan n ṣajọyọ ọdun Hanukkah lẹba eti okun naa ṣaaju iṣẹlẹ ọhun.

Ẹwẹ, awọn eeyan kaakiri agbaye lo ti bẹrẹ si n bu ẹnu atẹ lu ikọlu naa bayii.

Lara wọn ni Aarẹ Israel, Isaac Herzog, to sọ pe awọn to n ṣe ọdun Hanukkah gan ni ikọlu naa dojukọ.

Ẹgbẹ awọn Musulumi ni Australia, Australian National Imams Council, naa tun bu ẹnu atẹ lu ikọlu ọhun.