Wo òfin mẹ́ta tuntun tí ìjọba Tinubu yóò fi kí aráàlú káàbọ̀ sínú ọdún 2026

Aarẹ Tinubu ati minisita fun eto abo

Oríṣun àwòrán, Bayo Onanuga

    • Author, Olumide Owaduge
  • Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 6

Bẹrẹ lati ọjọ kinni, oṣu Kinni, ọdun 2026 ni ijọba Aarẹ Bola Tinubu yoo bẹrẹ si n ṣe amulo awọn ofin tuntun kan.

Awọn ofin naa ti ijọba yoo fi ki awọn araalu kaabọ sinu ọdun tuntun ni ijọba sọ pe o ṣe pataki fun ilọsiwaju Naijiria ati fun aabo araalu.

Lara awọn amulo ofin tuntun naa yoo gba owo kuro lapọ awọn araalu kan nigba ti yoo tun mu irọrun ba awọn araalu mii.

Pupọ ninu awọn ofin naa ni ijọba gbe kalẹ lati ọdun to kọja to si ti fun awọn araalu ni akoko to yẹ lati murasilẹ fun amulo rẹ lọdun to n bọ.

Iwọnyi ni awọn ofin tuntun ti ijọba yoo bẹrẹ amulo rẹ lọdun 2026.

1. Ofin owo ori tuntun

Ninu oṣu kẹwaa, ọdun 2024 ni Aarẹ Bola Tinubu gbe aba ofin atunṣe si owo ori Naijiria lọ ile igbimọ aṣofin.

O sọ lọjọ naa pe aba ofin naa yoo tun Naijiria ṣe, yoo si mu atunṣe ba ilana sisan owo ori ni Naijiria.

Amọ ṣa, ọpọ ariyanjiyan lo waye lẹyin ti Aarẹ mẹnuba abadofin naa.

Bi awọn kan ṣe n sọ pe ofin owo ori tuntun ọhun yoo fa ifasẹyin ba awọn ẹkun kan, ni awọn miran n sọ pe ofin naa gan-an ni Naijiria nilo lasiko yii.

Awọn miran ni ti wọn n gboriyin fun Aarẹ Tinubu pe, iṣẹ takuntakun lo ṣe nipasẹ igbimọ to ṣe atunsẹ ofin owo ori ti Naijiria n lo lati ọpọlọpọ ọdun.

Amọ ijọba apapọ ti ni ki awọn ọmọ Naijiria lọ fi ọkan wọn balẹ nitori awọn ọlọrọ nikan ni ofin owo ori tuntun naa yoo pa lara, ti yoo si ṣe anfani fun awọn ti owo oṣu wọn ko to nnkan.

Koda, ijọba ṣeleri pe awọn kan ko tilẹ ni san owo ori mọ paapaa.

Wo fidio isalẹ yii fun alaye ni kikun.

Àkọlé fídíò, Àtúpalẹ̀ àti àlàyé lórí àwọn àríyànjiyàn tó n wáyé lórí òfin owó orí tuntun ní Naijiria

Gbigbẹsẹle ọti pẹlẹbẹ inu ọra

Ọti pẹlẹbẹ inu ọra

Oríṣun àwòrán, thecableng/X

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ṣaaju ni ile igbimọ aṣofin ti kọkọ paṣẹ fun ajọ to n ri si oogun ati ounjẹ ni Naijiria, NAFDAC, atawọn ajọ mii lati ri daju pe ẹnikẹni ko ta ọti inu ọra ni Naijiria mọ bẹrẹ lati inu oṣu Kejila ọdun 2025 yii.

Awọn aṣofin naa tun fẹnuko pe wọn ko ni fun awọn to n ta ọta ni aye mii lẹyin aṣẹ ti wọn pa yii.

Amọ nigba to ya wọn sun ofin ọhun siwaju pe yoo bẹrẹ si n fẹsẹ mulẹ lati ibẹrẹ ọdun 2026.

Eyii ko ṣẹyin bi awọn to n pese atawọn to n ta pẹlẹbẹ ṣe rawọ ẹbẹ si ijọba pe ko jẹ ki awọn ta awọn ọja to wa nilẹ tan.

Inu ọdun 2018 ni oniruru ajọ bii NAFDAC, Federal Competition and Consumer Protection Commission (FCCPC), Association of Food, Beverage & Tobacco Employers (AFBTE) ati Distillers and Blenders Association of Nigeria (DIBAN) tọwọ bọwe adehun ọlọdun maun un lori kiko ọti ọhun kuro nilẹ.

Adehun naa ni lati maa ko awọn ọti ọhun kuro nilẹ diẹdiẹ latari ewu to wa ninu mimu rẹ faraalu ati bo ṣe rọun fun awọn eeyan lati ra, paapaa awọn ọdọmọde.

Iwọnyin lawọn igba ti ijọba ti gbẹsẹle ọti inu ọra ni Naijiria

  • Oṣu kejila ọdun 2018 - Ọdun naa ni igba akọkọ ti ijọba atawọn oniruru ajọ buwọlu adehun latin fopin si pipo ọti ninu ọra, paapaa awọn ọti ti iwọn rẹ ko ju 200ml.
  • Ọjọ kinni, oṣu Keji, ọdun 2024 – NAFDAC bẹrẹ si n ko awọn ọti naa lori igba lati le mu aṣẹ iwe adehun naa ṣe.
  • Oṣu keji si oṣu Kẹfa ọdun 2024 – Ile igbimọ aṣofin da si ọrọ naa wọn si rọ NAFDAC lati dawọ kiko rẹ kuro lori igba duro latari awọn ti yoo padanu owo ati iṣẹ wọn, paapaa ipa ti igbesẹ naa yoo ni lori ọrọ aje araalu to n ta a.
  • Oṣu Karun un, ọdun 2024 – NAFDAC gbẹsẹ kuro lori aṣẹ naa fun igba diẹ titi di ipari ọdun 2025 ki wọn le ṣe ipade pẹlu gbogbo awọn ti rọrọ naa kan.
  • Oṣu Kọkanla, ọdun 2025 – ile igbimọ aṣofin kan an nipa fun NAFDAC ko bẹrẹ aṣẹ naa ko si gbẹsẹle ọti inu ọra ni Naijiria lai fun awọn to n po o atawọn to n ta a n afikun gbendeke mii mọ.

Aṣẹ 'tinted permit' fun awọn onimọto

Awakọ ti ọlọpaa da duro loji popo

Oríṣun àwòrán, Getty Images

O ti pẹ ti ọrọ yii ti n da wahala silẹ laarin ọlọpaa ati araalu ni Naijiria.

Lawọn igba kan, ọga agba ileeṣẹ ọlọpaa ni ki awọn ọlọpaa ma beer iwe ẹri 'tint' naa lọwọ araalu mọ, amọ nigba to ọga agba ileeṣẹ ọlọpaa tuntun de, o ni ki wọn maa beere.

Ọpọ araalu lo bu ẹnu atẹ lu igbese naa, paapaa lori bi wọn ṣe ni araalu gbọdọ maa san owo iwe ọhun lọdọdun.

Eyii lo mu ki ẹgbẹ awọn agbofinro ni Naijiria gbe ileeṣẹ ọlọpaa lọ sile ẹjọ lori ọrọ naa.

Nigba ti yoo di ọjọ ọjọ kọkanla, oṣu Kẹjọ, ọdun 2025 yii, ileeṣẹ ọlọpaa kede pe oun fun gbogbo awọn onimọto laanfani di ọjọ keji, oṣu Kẹwaa ọdun 2025 lati lọ gba iwe naa.

Wayi o, ileeṣẹ ọhun ti wa kede pe gbogbo awọn ti gilaasi mọto wọn ba ni ọra dudu gbọgọ lọ gba iwe ẹri naa ko to di ọjọ keji, oṣu Kinni, ọdun 2026, bi bẹẹ wọn yoo foju wina ofin.

Gẹgẹ bii ohun ti ọlọpaa sọ, igbesẹ naa ṣe pataki lati daabo araalu lọwọ awọn ajinigbe.

Ọlọpaa ni ko yẹ ki araalu kanka fi ọra dudu bo gilaasi ọkọ rẹ ki wọn le maa ri ẹni to wa ninu rẹ, amọ ti ọra ọhun ba tẹlẹ mọtọ naa wa lati oke okun, ẹni to ni ọkọ gbọdọ forukọ rẹ silẹ ko si gba iwe ẹri naa.