Ohun tí a mọ̀ nípa àwọn agbébọn tó ní 'ìjọba Ilorin' ló fún àwọn ní AK-47 rèé

Awọn agbebọn naa lẹyin ti ọwọ tẹ wọn tan

Oríṣun àwòrán, sahara reporters

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Ẹnu ti bẹrẹ si n kun ijọba ipinlẹ Kwara bayii lori ayelujara lẹyin ti awọn afurasi agbesunmọmi kan sọ pe ijọba Ilorin lo ha ibọn AK-47 le awọn lọwọ.

Gẹgẹ bii ohun ti a gbọ, ọrọ yii lo jẹyọ lẹyin ti awọn ologun mu awọn afurasi naa ninu ọkọ ijọba kan lagbagbe ijọba ibilẹ Ifelodun, nipinlẹ naa.

Asiko ti awọn ologun naa n yika agbagbe ọhun ni wọn ṣalabapade awọn afurasi naa pẹlu AK-47 lọwọ wọn.

Ninu fidio awọn afurasi naa ti BBC Yoruba foju ri ni wọn ti da awọn afurasi ọhun dọbalẹ ti wọn si fi okun de ọwọ wọn sẹyin ti wọn si n ka boroboro.

Nigba ti wọn n fi ọrọ wa awọn afurasi naa lẹnu wo, ẹnikan ninu wọn to n sọ ede Hausa ati Pidgin sọ pe ijọba Ilorin lo fun awọn ni ọkọ ti wọn n wa ati ibọn AK-47 ọwọ wọn.

Ohun ti awọn afuras naa sọ ni pato

Gẹgẹ bii wọn ṣe jẹwọ, o ti ọjọ mẹta kan ti wọn ti n ṣọṣẹ lagbegbe naa labẹ asia pe awọn n kaakiri agbegbe ọhun lorukọ ijọba Kwara.

Ẹni to gbẹnu wọn sọrọ sọ pe "o ti ṣe diẹ ti a ti wa nibi, ọkọ naa ni a fi n kaakiri agbagbe. Walahi, ootọ ni mo n sọ fun yin.

"Ijọba Ilorin lo fun wa ni ọkọ ati ibọn ti a n lo. Awọn lo fun wa ni awọn ibọn ti a n lo."

Afurasi ọhun sọ siwaju si pe kii ṣe ohun gangan lo gba ibọn naa amọ ọga awọn lo gba awọn ibọn ọhun lọwọ ijọba.

Awọn afurasi naa tẹnumọ pe kii ṣe awọn lo ni ibọn amọ ijọba lo fun awọn.

Ijọba Kwara sọrọ soke

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Wayi o, ijọba Kwara ti sọ pe ọwọ sinku ofin awọn soja ko tẹ awọn agbebọn kankan ni ijọba ibilẹ Ifelodun, tabi ijọba ibilẹ mii ni ipinlẹ awọn.

Ijọba naa sọ eyi di mimọ ninu atẹjade kan ti kọmiṣọna to n ri si ọrọ iroyin, Bolanle Olukoju fi lede.

Atẹjade naa sọ pe "Ni akọkọ, awọn soja ko nawọ gan agbebọn kankan ni ibi kankan ni ijọba ibilẹ Ifelodun.

"A ti wo fọnran naa daadaa nibi ti awọn kan ti sọ pe, "ijọba Ilorin" lo fun awọn ni ọkọ, ti awọn si gba ohun ija lati Abuja.

"Nigba ti awọn ọrọ inu fọnran naa ati awọn ohun to rọ mọ ṣi wa labẹ iwadii, o ṣe pataki lati yannana ẹ pe, ijọba ibilẹ Ifelodun kọ ni wọn ti mu awọn afurasi naa, kii si se ibi kankan ni Kwara."

Kọmiṣọa tẹsiwaju pe ilu Auchi, nipinlẹ Edo, ni ọwọ ti tẹ awọn afurasi naa.

O ni ko si ijọba ipinlẹ kankan to lagbara lati fun ẹnikẹni ni ibọn AK-47 ati pe awọn eeyan naa ko sọ pe ijọba Kwara lo fun awọn ni ibọn bo tilẹ jẹ pe wọn darukọ ijọba Ilorin.

Atẹjade naa wa rọ gbogbo awọn agbofinro lati ṣisẹ papọ ki wọn le bori ija pẹlu awọn agbebọn.

Bi awọn agbofinro ṣe n se iwadii lọ lori iṣẹlẹ naa, o tun rọ awọn to n gbe iroyin lori ayelujara lati jina si awọn iroyin ẹlẹjẹ to le da omi alafia ilu ru.

Ohun ti iwadii fi han

Ninu iwadii ti BBC Yoruba ṣe, eeyan kan ni ile ijọba Kwara to ni ki a ma darukọ ohun sọ pe awọn afurasi ti wọn mu ni ilu Auchi naa jẹ ara awọn ẹṣọ alaabo ti ileesẹ to n gba Aarẹ nimọran lori eto aabo, NSA, ko lọ ipinlẹ Kwara.

O ni lootọ ni ijọba Kwara fun wọn ni ọkọ lati sisẹ eto abo ti wọn ba de ibẹ, ṣugbọn wọn o da ọkọ naa pada nigba ti wọn n lọ.

O fi kun-un pe, awọn afurasi naa ko jẹwọ pe ijọba Kwara lo fun awọn ni ibọn gẹgẹ bi awọn kan se n gbe kiri.

O ni ohun ti wọn sọ ni pe, ijọba Ilorin lo fun awọn ni ọkọ.

Nibo ni ijọba Ifelodun wa ni Kwara?

Ọkan lara awọn ijọba ibilẹ ni Ifelodun jẹ nipinlẹ Kwara, ti olu ilu rẹ si jẹ Share.

Pupọ ninu awọn eeyan to n gbe ni ijọba ibilẹ naa lo jẹ ẹya Yoruba, ti awọn mii ninu wọn jẹ Igbomina ti orisun wọn wa lati Ile Ife, Oyo ati Ketu.

Gẹgẹ bii itan ṣe sọ pupọ ninu agbegbe ijọba ibilẹ naa ni wọn gba lasiko Afonja ati Alimi lọpọ ọdun sẹyin.

O le ni ẹgbẹrun lọna igba eeyan to n gbe ni ijọba ibilẹ Ifelodun gẹgẹ bii akọsilẹ eto ikaniyan ọdun 2006.