Gbogbo ìgbà ni wọ́n ń jí àwọn òṣìṣẹ́ gbé, ọkàn wa kò balẹ̀ mọ́ – NLC

Ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ ni Naijiria, NLC ti ṣe iwọde tako eto abo to mẹyẹ laarin ilu niluu Abuja.
Lara àwọn ti wọn ti wọn wa ni Labour House fun iwọdee ni Ààrẹ ẹgbẹ́ ọhun. Joe Ajaero, ajafẹtọọmọniyan, Omoyele Sowore atawọn ọmọ ẹgbẹ Revolution Now Movement.
Bákan náà ní àwọn òṣìṣẹ́ eto ààbò bii ọlọpaa, civil defence ati DSS naa ko gbẹyin.
Nibi iwọde naa ni Ajaero ti fi ẹdun ọkàn rẹ han lori àìní eto aabo to peye ni Naijiria.
O ni dukiẹkudiẹ eto abo naa n ṣakoba fun eto ọ̀rọ̀ ajé orílẹ̀ èdè Nàìjíríà, o tun n fa owọ aago awọn ileeṣẹ abẹle sẹyin.
Gẹ́gẹ́ bo ṣe sọ, iwọde ti wọn ṣe naa yoo jẹ́ kí ìjọba jí giri si ojúṣe rẹ láti dáàbò bo gbogbo ọmọ Nàìjíríà tilè toko.
Ajaero tẹsiwaju pe "púpọ̀ nínú àwọn oṣiṣẹ ni wọn kò fi ẹdọ lori oronro wọn bi àwọn ajinigbe ṣe n jí wọn gbe lojoojumọ lẹ́nu iṣẹ́ wọn . Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì tún ń pa àwọn oṣiṣẹ.
"Fun àpẹẹrẹ, ni ìpínlẹ̀ Kebbi nibi ti won ti pa olùkọ́ kan. Wọn tún ń jí àwọn ọmọ oṣiṣẹ gbé. Nítorí náà, ojúṣe ìjọba ni lati wa àwọn ọ̀daràn yìí rí kí wọn sì fi ọwọ òfin mú wọn."
Àwọn òṣìṣẹ̀ ti bẹ̀rẹ̀ ìwọ́de nílùú Abuja, àtàwọn ìpínlẹ̀ kan ní Nàìjíríà

Ìwọde ẹgbẹ oṣiṣẹ NLC lorilẹede Naijiria ti gbinaya kaakiri awọn ipinlẹ lorilẹede Naijiria ati ilu Abuja tii ṣe olu ilu Naijiria.
Iroyin ti o n tẹ BBC News Yoruba lọwọ kaakiri latawọn ipinlẹn fihan pe lati idaji ọjọru lawọn oṣiṣẹ atawọn ajafẹtọ ọmọniyan ti jade sita latikopa ninu iwọde naa.

Ohun ti awọn ẹgbẹ oṣiṣẹ n ja a fun naa ni pipe akiyesi ijọba lẹkajẹka gbogbo si gulegule eto abo to mẹhẹ lorilẹede Naijiria, to sijẹ wi pe ko jọ bi ẹni pe o n wawọ lọ silẹ rara.
Awọn aṣaaju ẹgbẹ oṣiṣẹ NLC ji jade lowurọ lẹyin ipade ti wọn ṣe pẹlu aarẹ orilẹede Naijiria, Bọla Ahmed Tinubu laṣalẹ ọjọ Iṣẹgun, eyi to da bi ẹni wi pe ko so eso rere pẹlu bo ṣe jẹ wi pe iwọde naa tẹsiwaju.
Awọn ẹgbẹ oṣiṣẹ pẹlu lawọn ipinlẹ bii Kwara ati Ekiti nibi ti awọn akọroyin BBC News Yoruba ti fidirẹ mulẹ pe iwọde ti bẹrẹ nibẹ; awọn oṣiṣẹ si ti tu jade lati ṣe iwọde naa.
Bawo lo ṣe n lọ lolu ileeṣẹ awọn oṣiṣẹ NLC nilu Abuja?

Lara awọn ti wọn ti wa ni Labour House naani Ààrẹ ẹgbẹ́ àwọn òṣìṣẹ́ lorilẹ-ede Naijiria , NLC, Joe Ajaero, Omoyele Sowore.
Bákan náà, ní àwọn ẹṣọ alààbò, ọlọpaa, civil defence, àti DSS pẹlu wa nibẹ.
Ajaero fi ẹdun ọkàn rẹ han lori àìní eto aabo to peye , ti eléyìí sí ń ko ba eto ọ̀rọ̀ ajé orílẹ̀ èdè Nàìjíríà àti bí àìní ètò ààbò náà ṣe ńkọ́ bá àwọn ilé iṣẹ́ lorilẹ-ede yìí.

Gẹ́gẹ́ bi Ààrẹ ẹgbẹ́ oṣiṣẹ se sọ, ó ní ètò ìwọlé yii yoo jẹ́ kí ìjọba jí fún ojúṣe rẹ láti dáàbò bo gbogbo ọmọ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà tilè toko
Ààrẹ tún tesiwaju bí àìní ètò ààbò yìí ṣe ńṣe àkóbá fún àwọn òṣìṣẹ́ " púpọ̀ nínú àwọn oṣiṣẹ ni wọ́n kó fu ẹdọ lè orí òróṅro wọn bù àwọn àdíngbẹ seń jí wọn gbe lojoojumọ lẹ́nu iṣẹ́ wọn . Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì tún ń pa àwọn oṣiṣẹ. Fun àpẹẹrẹ ni Ìpínlẹ̀ Kebbi nibi ti won ti pa olùkọ́ kan. " wọn tún ń jí àwọn ọmọ osise gbé. Nítorí náà, ojúṣe ìjọba ni lati wa àwọn ọ̀daràn yìí rí kí wọn sì fi ọwọ òfin mú wọn."

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Apapọ ẹgbẹ oṣiṣẹ NLC yari wi pe awọn yoo ṣewọde kaakiri orilẹede Naijiria lọla Ọjọru ọjọ kẹtadinlogun oṣu Kejila yii.
NLC ni awọn fẹ ṣe iwọde naa tako bi eto aabo ṣe n buru sii lojoojumọ pẹlu bii iṣẹlẹ ijinigbe ati ipaniyan ṣe n ṣẹlẹ kaakiri Naijiria.
Ẹgbẹ naa sọ nibi ipade ti wọn ṣe niluu Eko wi pe asiko ti to fun ijọba lati foju awọn to wa nidi eto aabo to mẹhẹ han.
Wọn ni awọn ko le maa wo kawọn janduku ajinigbe atawọn agbesunmomi maa ṣọṣẹ kaakiri Naijiria lai ṣe nkankan lori rẹ.
Aarẹ ẹgbẹ NLC, Joe Ajaero, sọ pe awọn yoo lo iwọde yii lati kepe ijọba wi pe ko wa ojutuu si eto aabo to ti doju ru ni Naijiria tori gbogbo eeyan lọrọ naa kan.
Ajaero ni iwa ijinigbe pawo atawọn agbebọn to n pawọn eeyan kaakiri kii ṣe aṣa Naijiria.
Aarẹ NLC ni eto aabo to mẹhẹ n ṣakoba nla fun eto ọrọ aje, ati pe o tun n le awọn olokowo to fẹ dokowo ni Naijiria jina.
O ni nnkan tawọn fẹ fi iwọde naa ṣe ni lati jẹ ki ijọba mọ ipa ti eto aabo to mẹhẹ ni lori awọn olokowo atawọn oṣiṣẹ tawọn ajinigbe n ji gbe ti wọn si n ṣeku pa nigba mii.
''Fun apẹẹrẹ, awọn janduku agbebọn pa olukọ kan, wọn si ji ọpọ akẹkọọ atawọn oṣiṣẹ mii gbe lọ nile ẹkọ nibi iṣẹlẹ to waye nipinlẹ Kebbi.
Ijọba gbọdọ mọ pe awọn ni lati wa ojutuu si eto aabo to n buri sii lojoojumọ,'' Ajaero lo sọ bẹẹ.
''Ẹgbẹ oṣiṣẹ ko ni ibọn, a ko ni ada ti le fi kọju ija sawọn ọdaran yii, iwọde nikan ni agbara ti a ni''
Ajaero tun kepe gbogbo araalu lati ko ipa wọn lori ọna ati dẹkun iṣẹlẹ ijinigbe ati ipaniyan to n ṣakoba fun awujọ.
Aarẹ ẹgbẹ oṣiṣẹ sọ pe ọpọ awọn oṣiṣẹ to ti bọ sọwọ awọn ajinigbe ni kii saba lowo itusilẹ ti wọn maa n beere fun lati san.
O ni iru awọn oṣiṣẹ bẹẹ saba maa n ya owo kaakiri ni lati san owo itusilẹ tawọn ajinigbe n beere fun.
Ajọ NLC ti wa kọwe si gbogbo ẹka ẹgbẹ oṣiṣẹ to wa kaakiri awọn ipinlẹ lati darapọ mọ iwọde naa l'Ọjọru.
Ajaero ni ẹgbẹ oṣiṣẹ fẹ ki ijọba kede awọn to n ṣiṣẹ laabi yii lorilẹede Naijiria.
''O ṣe pataki fun gbogbo oṣiṣẹ lati darapọ mọ iwọde Ọjọru, ayafi awọn to ba fẹ ki ijọba maa fun wa lowo ajẹmọnu ti a le maa fi san owo itusilẹ fawọn ajinigbe.
A o ni ibọn, a o si ni ada ti a le fi kọju ija sawọn ọdaran yii, iwọde nikan ni agbara ti a ni lati fi ja ti gbogbo agbaye si maa gbọ wa,'' Ajaero lo sọ bẹẹ.















