Sikiru Ayinde Barrister, Barry wonder gbajúmọ̀ olórin Fuji tó ṣiṣẹ́ sọ́jà, tẹ̀wé-tẹ̀wé àti akọ̀wé iléèṣẹ́

Oríṣun àwòrán, twitter/ayinde barrister
Ọjọ Iṣẹgun, ọjọ kẹrindinlogun oṣu kejila ọdun 2025 lo pe ọdun karundinlogun ti eekan akọrin Fuji, Sikiru Ayinde Barrister jade laye.
Owurọ ọjọ kẹrindinlogun oṣu kejila ọdun, 2010, ni okiki iroyin iku Sikiru Ayinde Barrister wọle wẹrẹ eyi to sọ ọpọ awọn ololufẹ rẹ, atawọn ololufẹ Fuji lapapọ sinu ibanujẹ nla.
Ni ileewosan St. Mary's Hospital niluu London ni agba akọrin naa dakẹ si lẹyin aisan ọlọjọ pipẹ.
Gbajumọ olorin naa ti ọpọ mọ si Alaaji Agba ni ọpọ gbagbọ pe o da ẹya orin Fuji silẹ.
Sikiru Ayinde Barrister dakẹ!

Oríṣun àwòrán, twitter/ayinde barrister
Iku n pani, ilẹ n jẹyan. Oni lo pe ọdun mẹwaa geerege ti ilumọọka olorin Fuji, Alhaji Sikiru Ololade Ayinde Balogun Barrister jade laye.
Ọjọ kẹrindinlogun, oṣu kejila, ọdun 2010 ni Barrister dagbere faye ni ile iwosan kan nilu London.
Ẹbi. ọrẹ ati awọn ololufẹ rẹ ni wọn n ṣeranti Barrister lẹyin ọdun marundinlogun to jade laye.
Ibẹrẹ igbe aye Sikiru Ayinde Barrister?
Ogbeni Salawu Balogun, alapata ẹran lo jẹ baba to bi Sikiru Ayinde Barrister nigba ti iya rẹ jẹ oniṣowo pẹẹpẹẹpẹ.
Wọ̀n bi Barrister ni ọjọ kẹsan-an, oṣu Keji, ọdun 1948 sinu ẹbi Salawu Balogun nilu Ibadan.
Iṣẹ alapata ẹran ni baba rẹ n ṣe, iya rẹ si jẹ oniṣowo.
Sikiru Ayinde lọ si ile ẹkọ alakọbẹrẹ Muslim Mission School, ati Model School ni Mushin, nipinlẹ Eko.
Lẹyin naa lo k nipa bi iwe titẹ ati awọn iṣẹ ọfiisi mii nile ẹkọ giga Yaba Polytechnic.
Lati ọdọ ni Ayinde Barrister ti bẹrẹ orin kikọ pẹlu ẹka ori 'Were'. Asiko awẹ Ramadan ni wọn ma n kọ iru orin yii lati ile kan si ile mii.

Oríṣun àwòrán, twitter/ayinde barrister
O siṣẹ atẹwe nileeṣẹ to n ṣe ọti, Nigeria Breweries. Lẹyin naa lo ṣiṣẹ akọwe nileeṣẹ ologun Naijiria lasiko ogun abẹle.
O jẹ ọmọ ogun labẹ idari Ọgagun Adeniran, o si jagun nilu Akwa, Abagana ati Onitsha.
Nigba to pada de lati oju ogun, wọn gbe e lọ si olu ileeṣẹ ologun to n ṣe ifimufinlẹ, ni Apapa nilu Eko, ko to o tun lọ si Army Resettlement Centre ni Oshodi.
O kuro ninu iṣẹ ologun, lo fi di olorin Fuji patapata, to si da ẹgbẹ akọrin rẹ 'Supreme Fuji Commanders' silẹ.
Irianajo rẹ gẹgẹ bi olorin Fuji
Lọdun 1966, Sikiri ayinde Barrister gbe rẹkọọdu orin rẹ akọkọ jade. Lasiko naa, ibi ariya ni oun ati awọn ọmọ ẹgbẹ rẹ ti ma n kọrin ni awọn agbegbe Ebute Meta, ati fun awọn ololufẹ rẹ ni Mushin.
O pada gbe awọn rẹkọọdu mii jade labẹ ileeṣẹ African Songs Ltd, ko to o da ileeṣẹ ti ẹ, Silky-Oluyole Records, silẹ.
Nigba ti yoo fi di ọdun 1980, Ayinde Barrister ati orin Fuji ti di itẹwọgba laarin gbogbo ẹsin to wa ni Naijiria.
Lọdun 1982, ija nla waye laarin Kollington Ayinla, to jẹ ọrẹ rẹ, ati olorin Fuji mii.

Oríṣun àwòrán, twitter/ayinde barrister
Barrister gbe orin kikọ de ilẹ okeere, to si ṣe ariya ita gbangba ni awọn ilu bi London lọdun 1990 ati 1993. Eyi lo bi orin Fuji Garbage.
Orin Fuji ti Sikiri Ayinde Barrister kọ nigba aye rẹ jẹ akojọpọ Apala, Sakara, Awurebe ati awọn mii.
Orin rẹ si ma n da lori aṣa, ikilọ iwa, ibọwọ f'agba, oṣelu ati igbokegbodo eeyan laye.
O si tun ma n fi orin ki awọn gbajumọ ni awujọ.
Ọpọlọpọ ami idanilọla ni Ayinde Barrister gba fun iṣẹ orin kikọ. Lara wọn ni idanilọla pẹlu Member of the Order of the Federal Republic (MFR), ti Aarẹ Olusegun Obasanjo fun lọdun 2006.
Awọn rẹkọọdu orin ti Sikiru Ayinde Barrister gbe jade nigba aye rẹ ni
Ejeka Gbo T'Olorun (1966)
Vol.1: Waya Rabi
Vol.2: Alayinde Ma De O
Vol.3: Mecca Special
Vol.4: Itan Anobi Rasao
Vol.5: E Sa Ma Mi Lengbe
Vol.6: Ori Mi Ewo Ninse / Majority Boy (1975)
Vol.7: Ile Aiye Dun Pupo / Love In Tokyo (India Sound) (1975)
Vol.8: Fuji Exponent (1976)
Vol.9
Vol. 10 (African Songs, 1977)
Bisimilai (African Songs, 1977)
Omo Nigeria (African Songs, 1977)
Olojo Eni Mojuba (Siky Oluyole, 1978)
Our Late Artistes (Siky Oluyole, 1978)
London Special (Siky Oluyole, 1979)
Fuji Reggae Series 2 (Siky Oluyole, 1979)
Eyo Nbo Anobi (Siky Oluyole, 1979)
Awa O Ja (Siky Oluyole, 1979)
Fuji Disco (Siky Oluyole, 1980)
Oke Agba (Siky Oluyole, 1980)
Aiye (Siky Oluyole, 1980)
Family Planning (Siky Oluyole, 1981)
Suru Baba Iwa (Siky Oluyole, 1981)
Ore Lope (Siky Oluyole, 1981)
E Sinmi Rascality (Siky Oluyole, 1982)
Iwa (Siky Oluyole, 1982)
Ise Logun Ise (No More War) (Siky Oluyole, 1982)
Eku Odun (Siky Oluyole, 1982)
Ijo Olomo (Siky Oluyole, 1983)
Nigeria (Siky Oluyole, 1983)
Love (Siky Oluyole, 1983)
Barry Special (Siky Oluyole, 1983)
Military (Siky Oluyole, 1984)
Appreciation (Siky Oluyole, 1984)
Fuji Vibration 84/85 (Siky Oluyole, 1984)
Destiny (Siky Oluyole, 1985)
Superiority (Siky Oluyole, 1985)
Fertiliser (Siky Oluyole, 1985)
Okiki (Siky Oluyole, 1986)
Inferno(Siky Oluyole, 1996)
America Special (Siky Oluyole, 1986)
Ile Aye Ogun (Siky Oluyole, 1987)
Maturity (Siky Oluyole, 1987)
Barry Wonder (Siky Oluyole, 1987)
Wonders At 40 (Siky Oluyole, 1988)
Fuji Garbage (Siky Oluyole, 1988)
Fuji Garbage Series II (Siky Oluyole, 1988)
Current Affairs (Siky Oluyole, 1989)
Fuji Garbage Series III (Siky Oluyole, 1989)
Music Extravaganza (Siky Oluyole, 1990)

Oríṣun àwòrán, twitter/ayinde barrister
Fuji Waves (Siky Oluyole, 1991)
Fantasia Fuji (Siky Oluyole, 1991)
Fuji Explosion (Siky Oluyole, 1992)
Dimensional Fuji (Siky Oluyole, 1993)
New Fuji Garbage (Siky Oluyole, 1993)
The Truth (Siky Oluyole, 1994)
Precaution (Siky Oluyole, 1995)
Olympics Atlanta '96 cassette (Siky Oluyole, 1996)
Olympics '96 London Version cassette (Zmirage Productions, 1997)
with Queen Salawa Abeni Evening Of Sound cassette (Zmirage Productions, 1997)
Barry On Stage cassette (Siky Oluyole, 1997)
Mr. Fuji (Barry Black, 1998)
"Millennium Stanza" (Fuji Chambers, 2000)
"Controversy" (2005)
' REALITY ' ( 2008).
Superiority
A ko le sọ daju pe gbogbo orin to kọ niyii. O ṣe e ṣe ki awọn mii wa ti a ko mọ.














