Ọlọ́pàá South Africa mẹ́rin yìnbọn pa ọmọ Nàìjíríà, ariwo sọ

Awọn ọlọpaa South Africa

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ọmọ Naijiria kan, Osinakachukwu Onu ti padanu ẹmi rẹ lẹyin ti ọlọpa yinbọn fun loju ọna N12 to wa ni Klerksdorp, lagbegbe North West, ni South Africa.

Ileeṣẹ iroyin abẹlẹ orilẹede naa, Independent Online (IOL), sọ pe awọn alasẹ ti mu awọn ọlọpaa mẹrin ti wọn fura si lori ọrọ naa.

Ileeṣẹ ọlọpaa North West ni awọn afurasi ọhun na papa bora nibi ti iṣẹlẹ naa ti waye lẹyin ti wọn gbẹmi ọkunrin naa tan.

Atẹjade naa pe "Ọwọ wa ti tẹ awọn ọlọpaa ti wọn n dari ọkọ loju popo ti ọjọ ori wọn wa laarin ọdun marundinlọgbọn si ọdun mẹridinlogoji lori ipa ti wọn ko ninu iku ọmọ Naijiria loju ọna N12 ni Klerksdorp.

"Awọn ọtẹlẹmuyẹ Klerksdorp ti mu awọn ọlọpaa naa lori ẹsun ipaniyan lẹyin iku ọmọ Naijiria ẹni ọdun mẹtadinlogoji kan, Osinakachukwu Marcus."

Atẹjade naa sọ siwaju si pe ninu iwadii ni wọn ti tọpinpin awọn afurasi naa si ibi ti wọn farapamo si ni Klerksdorp.

Gẹgẹ bii ohun ti ọlọpa sọ, wọn ti gba ibọn ilewọ awọn afurasi naa, iwadii yoo si waye lori ibọn ọhun lati mọ ẹni pato to yinbọn fun oloogbe.

Atẹjade ọlọpaa tẹsiwaju pe "awọn mẹrin naa ti a fẹsun kan yoo foju bale ẹjọ majistreeti to wa ni Klerksdorp lori ẹsun ipaniyan ati aṣilo ipo."

Nigba to n sọrọ, kọmiṣọna agbegbe North West, ọgagun Ryno Naidoo ni inu oun dun bi ọwọ ṣe tete tẹ awọn afurasi naa.

Iṣẹlẹ yii ti kun pupọ ninu iṣekupani awọn ọmọ Naijiria ni South Africa lati ọpọ ọdun sẹyin.

Ti ẹ ba ranti, ninu oṣu Keje ọdun yii ni wọn ṣekupa ọmọ Naijiria meji, Austin ati Ayo niluu Durban.

Lọjọ kẹsan an, oṣu Keje ọdun yii ni iṣẹlẹ naa waye nigba ti awọn ọkunrin mẹta ti wọn bo oju wọn ya bo ọọfisi Austine, ti wọn si sina ibọn bolẹ lọwọ kan naa, eyii to yọri si iku ọkunrin meji ọhun.