Àwọn orílẹ̀èdè mẹ́wàá tí wọ́n jẹ gbèsè jùlọ ní Afrika

Ọwọ ọkunrin alawọ dudu to n ka owo

Oríṣun àwòrán, Getty Images

    • Author, Abdou Aziz Diedhiou
  • Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Pupọ orilẹede ni Afrika ni wọn jẹ gbese, eyii si jẹ ohun to n ba ọpọ ọmọ ilẹ naa ninu jẹ.

Ninu oṣu Karun un, ọdun 2025 yii ni awọn ọmọ ẹgbẹ ajọ iṣọkan ilẹ Afrika, AU, ṣe ipade kan lori gbese wọn niluu Lomé.

Ọgbẹni Clever Gatete, to jẹ adari ajọ United Nations Economic Commission for Africa sọ pe apapọ gbese ti awọn oriẹede ni Afrikaj jẹ ti to $1.86 nigba ti yoo fi di ọdun 2024.

Lara awọn ti awọn orilẹede Afrika jẹ ni gbese ju ni banki agbaye, ajọ IMF, African Development Bank (AfDB), China ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Iwọyin ni akojoọpọ awọn orilẹde Afrika mẹwaa ti gbese ti n wọ lọrun.

1. Sudan

Fun ọpọ ọdun ni ogun abẹle ti n ba orilẹede Sudan finra, bẹẹ naa ni ko bọ loko ẹru gbese.

Lara awọn orilẹede ti Sudan jẹ ni gbese ni awọn arabu atawọn orilẹede to wa ninu ẹgbẹ Paris.

2. Senegal

Atẹjade kan lati ọwọ banki ilẹ Gẹẹsi, Barclays, ni iye gbese Senegal le ni $42.7b.

A gbọ pe orilẹede naa wa lara awọn to wa loke tente awọn onigbese ni Afrika.

3. Zambia

Nigba ti yoo fi di ipari ọdun 2024, iye gbese Zambia ti le ni $21b. Amọ ninu oṣu Kẹsan an ọdun yii ni ajọ IMF sọ pe o dabi pe nnkan ti n ṣe ẹnu ire fun wọn nilẹ naa.

4. Cape Verde

Ọmọ ẹgbẹ ECOWAS ni orilẹede naa, o si wa lara awọn orilẹede to jẹ gbese julọ nilẹ Afrika.

Iroyin ni pupọ ninu owo ti wọn n pa wọle nibẹ ni wọn fi n san gbese.

5. Republic of Congo

Bo tilẹ jẹ pe iye gbese ti orilẹede naa jẹ lati ọdun 2020 si ọdun 2024 ti dinkun, iye gbese wọn si n kọ awọn ọmọ orilẹede naa lominu.

Gẹgẹ bii ohun ti ajọ IMF sọ, iye owo ti wọn fi n san gbese ninu owo ti wọn n pa wọle pọ jọjọ.

6. Mozambique

Ni ipari ọdun 2024, iye gbese orilẹede naa ti le ni $16.238b, eyii to jẹ ida 93% owo ti wọn pa wọle labẹle.

Ninu oṣu Kẹta ọdun 2025, ijọba orilẹede ọhun sọ pe gbese ti wọ oun lọrun, o si ṣoro lati maa san awọn gbese naa lọwọ yii.

7. Egypt

Lọdun 2024, gbese Egypt gba ida 94% owo to pa wọle.

Banki apapọ ilẹ ọhun sọ pe owo ti iye rẹ jẹ $21.3b lo fi san gbese ni ibẹrẹ ọdun 2025.

8. Malawi

Malawi ni orilẹede kẹjọ to jẹ gbese julọ ni Afrika.

Ida 88% owo to n pa wọle lo fi n san gbese lọwọ yii.

Nnkan bii miliọnu mejilelogun eeyan lo n gbe lorilẹede naa ti ijọba to jẹ gbese to le ni $10b.

9. Mauritius

Ajọ IMF sọ pe ida 88% owo ti orilẹde yii n pa wọle lo fi n san gbese to jẹ.

Bo tilẹ jẹ pe gbese rẹ ko pọ to ti awọn orilẹede kan, gbese naa pọ diẹ.

10. Guinea-Bissau

Lara awọn ti Guinea-Bissau jẹ ni gbese to pọ julọ ni banki agbaye, BOAD ati banki idagbasoke ilẹ Afrika, AfDB.

Ida 82.3% owo ti wọn n pa wọle nibẹ ni wọn fi n san gbese ti wọn jẹ.