Agbálẹ̀ ojú pópó pàdé ikú òjijì lópin ọdún lásìkò tí Dáńfó tó ń rìfáàsì lójú ọ̀nà márosẹ̀ kọlù ú

Oríṣun àwòrán, LASTMA/X
Obinrin agbalẹ titi kan tó ń ṣiṣẹ́ pẹlu àjọ to ń ṣàkóso ẹ̀gbin nipinlẹ Eko, LAWMA, tí ṣe àgbákò ikú òjijì lẹ́nu isẹ.
Ìṣẹ̀lẹ̀ náà wáyé nígbà tí ọkọ̀ bọọsi Danfo kan ń wá ọkọ rẹ sẹ́yìn, to si ṣàdédé kọlu obìnrin náà laimọ.
Opopona Meran, lójú ọna Iyana Ekoro, nipinlẹ Eko ni ìṣẹ̀lẹ̀ náà ti wáyé.

Oríṣun àwòrán, LASTMA/X
Nígbà tó ń fìdí ìṣẹ̀lẹ̀ nàá mulẹ, àjọ to ń ṣàkóso eto irinna lójú popo nipinlẹ Eko, LASTMA, tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà soju rẹ, salaye bí ọ̀rọ̀ náà ṣe jẹ́ àtẹ̀jáde kan tó fisita loju opo ayelujara X rẹ.
LAWMA ni obìnrin gbalẹ̀ titi náà lọ ń ṣiṣẹ́ oojọ rẹ láti ṣe afọmọ ojú pópó lọ́wọ́ idọti nígbà tí ọkọ̀ náà gba a.
Wọn ní ọkọ èrò kan tó jẹ Ford, alawọ búlúù, tí nọmbà rẹ jẹ BDG 495 YH, to ń rifaasi lórí òpópónà maṣọṣẹ, lo kọlu obìnrin agbalẹ̀ naa.
"Agbára tí bọọsi náà fi kọlu obìnrin agbalẹ náà lágbára púpọ̀, èyí tó muss kò dágbére fáyé lójú ẹsẹ.
Àwọn oṣiṣẹ wa, to ń ṣàkóso eto irinna lójú popo lásìkò náà, lo tètè da si iṣẹlẹ naa, ni kété tí wọn fi to wọn létí."
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
LASTMA sísọ lójú rẹ pé awakọ̀ bọọsi náà tí salọ ni kété tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà wáyé, kò máa bàa fojú wina òfin.
Àmọ́ wọn fikùn pe awon òṣìṣẹ́ LASTMA náà sáré tẹ́le awakọ̀ náà, tí wọn sì rí mú.
LASTMA ni ati awakọ̀, àti ọkọ bọọsi to pa obìnrin agbalẹ náà, ní wọ́n da pada síbi tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ti wáyé.
Atẹjade náà fikùn pe wọn ti fà awakọ̀ náà àti ọkọ rẹ le ọlọ́pàá to wa ni àgọ́ Ọlọ́pàá Meran lọ́wọ́ fún ìwádìí tó yẹ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà, kí wọn sì gbé awakọ̀ náà lọ sílé ẹjọ́.
Ajọ LASTMA wá bù ẹnu atẹ lu ìṣẹ̀lẹ̀ náà pẹlu àfikún pé ìwà ẹsẹ to lágbára ni lábẹ́ òfin to de eto irinna nipinlẹ Eko ti ọdún 2018, pé kí awakọ̀ máa rifaasi lójú ọna marosẹ.












