Ilé ẹjọ́ sọ dókítà tó ń po májèlé pọ̀ mọ́ oògùn fáwọn aláìsàn sí ẹ̀wọ̀n gbére

Oríṣun àwòrán, ARNAUD FINISTRE/AFP
- Author, Hugh Schofield
- Reporting from, Paris
- Author, Laura Gozzi
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4
Ilé ẹjọ́ kan ní orílẹ̀ èdè France ti rán onímọ̀ ètò ìlera kan ló sẹ́wọ̀n gbére lẹ́yìn tí wọ́n ló jẹ̀bi ẹ̀sùn pé ó mọ̀ọ́mọ̀ fi májèlé sínú oògùn fáwọn aláìsàn ọgbọ̀n.
Méjìlá nínú àwọn èèyàn náà ni wọ́n ní ó burú gidi.
Ní ọjọ́ Ẹtì ni ilé ẹjọ́ sọ Frédéric Péchie sí ẹ̀wọ̀n gbére lẹ́yìn tí wọ́n parí ìwádìí olóṣù mẹ́rin tó wáyé ní ìlà oòrùn ìlú Besançon.
Ìṣẹ̀lẹ̀ yìí jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ìwà kò tọ́ tó ń wáyé lẹ́ka ìmọ̀ ìlera ni France.
Àwọn olùpẹjọ́ sọ pé Péchier máa ń fi àwọn kẹ́míkà bíi potassium chloride tàbí adrenaline sínú àpò oògùn àwọn aláìsàn.
Ọ̀kan lára àwọn èèyàn tó forí ṣọ̀tà ìwà Péchier ni ọmọ ọdún mẹ́rin tó móríbọ́ lọ́wọ́ ìkọlù àìsàn ọkàn níbi iṣẹ́ abẹ kan lọ́dún 2016 tí ẹni tó sì dàgbà jùlọ jẹ́ ẹni ọdún mọ́kàndínláàádọ́rùn-ún.
"Dókítà ikú ni ìwọ, ẹlẹ́wọ̀n, apààyàn. O ti kó ìtìjú bá àwọn dókítà yòókù," àwọn olùpẹjọ́ sọ lọ́sẹ̀ tó kọjá nílé ẹjọ́. "Ó sọ ilé ìwòsàn di itẹ́ òkú."
Àwọn kẹ́míkà tí Péchier ń pò mọ́ oògùn àwọn èèyàn ń dá kun àìsàn ọkàn tí wọ́n ní tàbí jẹ́ ìṣòro fún ẹ̀jẹ̀ wọn, tí wọ́n máa ń nílò iṣẹ́ abẹ fún ìtọ́jú pàjáwìrì.
Péchier ló máa ń fún àwọn aláìsàn ní abẹ́rẹ́ tí iṣẹ́ abẹ kò fi ní dùn wọ́n, tó sì máa ń ṣe bí ẹni pé òun ń gba àwọn aláìsàn náà là.
Àmọ́ àwọn ìgbà méjìlá tí kò tètè yọjú tàbí tó ti pẹ́ kó tó dáhùn, àwọn aláìsàn náà jáde láyé.
Olùpẹjọ́ sọ pé Péchier ṣe àwọn nǹkan yìí lójúnà àti tàbùkù àwọn akẹgbẹ́ rẹ̀ tí kò fẹ́ràn.
Fún ọ̀pọ̀ àwọn iṣẹ́ abẹ yìí ni Péchier kìí sábà jẹ́ dókítà alábẹ́rẹ́ ṣùgbọ́n tó máa ń tètè jí dé ilé ìwòsàn láti lọ ṣe jàmbá pẹ̀lú àpò abẹ́rẹ́ táwọn èèyàn náà fẹ́ lò.
Tí ọ̀rọ̀ bá yíwọ́ ló máa sáre yọjú, tó sì máa sọ ohun tó ṣeéṣe kó jẹ́ ìṣòro àti ohun tí wọ́n máa nílò láti fi ṣe àtúnṣe.
Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ní ṣe ìwádìí Péchier ní ọdún mẹ́jọ sẹ́yìn nígbà tí wọ́n fura pé ó fi májèlé sínú oògùn àwọn aláìsàn méjì ní ilé ìwòsàn ní Besançon láàárín ọdún 2008 àti 2017.
Àwọn aláṣẹ bẹ̀rẹ̀ ìwádìí lọ́dún 2017 nígbà tí wọ́n ṣàwárí ọ̀pọ̀ kẹ́míkà potassium chloride nínú àpò obìnrin kan tó ní àìsàn ọkàn lẹ́yìn tí wọ́n ṣe iṣẹ́ abẹ lórí ẹ̀yìn tó ń dùn-ún fún-un.
Àwọn olùwádìí ṣàwárí irúfẹ́ ìṣẹ̀lẹ̀ bẹ́ẹ̀ tó pọ̀ níilé ìwòsàn aládàni Saint-Vincent ní Besançon. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé èèyàn tó máa ń ní ìṣẹ̀lẹ̀ àìsàn ọkàn tí wọ́n bá abẹ́rẹ́ bẹ́ẹ̀ ní orílẹ̀ èdè náà jẹ́ ẹyọ̀kan nínú 100,000, èèyàn tó lé ní mẹ́fà nínú 100,000 ló máa ń ni ní ilé ìwòsàn náà.
Ní ọ̀pọ̀ ìgbà, ìṣẹ̀lẹ̀ yìí máa ń ní ohun tó fà á àmọ́ ti ilé ìwòsàn Saint-Vincent máa ń jẹ́ kàyééfì.
Wọ́n ṣàwárí rẹ̀ pé àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ yìí dópin nígbà tí Péchier kúrò ní ilé ìwòsàn náà láti ló ṣiṣẹ́ ní ilé ìwòsàn míì táwọn ilé ìwòsàn tuntun tó wà náà sì bẹ̀rẹ̀ sí ní irú ìṣẹ̀lẹ̀ náà.
Nígbà tó tún padà sí ilé ìwòsàn Saint-Vincent, àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ náà tún bẹ̀rẹ̀ padà, lẹ́yìn tí wọ́n da duró lẹ́nu iṣẹ́ lọ́dún 2017, àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ náà tún dúró.
Ẹni tí wọ́n kọ́kọ́ mọ̀ pé ó ní irú ìnira bẹ́ẹ̀ ni obìnrin kan Sandra Simard tó ṣà déédéé ní àìsàn ọkàn lásìkò tí iṣẹ́ abẹ ń lọ lọ́wọ́ àmọ́ tó móríbọ́ lọ́wọ́ ikú lẹ́yìn tí Péchier báwọn dási.
Àyẹ̀wò tí wọ́n ṣe sí àpò abẹ́rẹ́ rẹ̀ ṣàfihàn pé potassium tó lé ní ìdá ọgọ́rùn-ún ohun tó yẹ kó wà níbẹ̀, táwọn aláṣẹ sì tètè pe àwọn olùpẹjọ́ lórí rẹ̀.
Lásìkò tí ìwádìí fi ń lọ lọ́wọ́, Péchier gbà pé ó ṣeéṣe kó jẹ́ pé ohun tí òun bù sínú àwọn àpò náà ló ṣokùnfà ikú àwọn tó pàdánù ẹ̀mí wọn ṣùgbọ́n tó ní òun kò ṣàbúrú kankan.
Péchier yóò lo ó kéré tán, ọdún méjìlélógún ní ọgbà ẹ̀wọ̀n bó ṣe jẹ́ pé kò sí ní àhámọ́ ní gbogbo ìgbà tí ìgbẹ́jọ́ rẹ̀ ń wáyé.
Ó jiyàn gbogbo àwọn ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn-án, tí agbẹjọ́rò rẹ̀ sì ní kò sí ẹ̀rí kankan láti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé ó lọ́wọ́ nínú ikú àwọn èèyàn náà, tó sì padà jẹ́wọ́ pé ó ṣeéṣe kí ẹni tó ń fi májèlé sínú abẹ́rẹ́ àwọn èèyàn náà ṣì wà ní ilé ìwòsàn náà ṣùgbọ́n kìí ṣe òun.
Péchier jẹ́ bàbá ọlọ́mọ mẹ́ta, tó sì sọ fún ilé ẹjọ́ pé ohun tó jẹ òun lógún ni bí òun ṣe máa dá ààbò bo ẹbí òun.
Sandra Simard sọ pé ìdájọ́ náà jẹ́ òpin sí ohun tó máa ń da oorun òun láàmú.
Ẹlòmíràn tí òun náà móríbọ́ lọ́wọ́ ikú, Jean-Claude Gandon sọ pé òun máa ṣọdún Kérésì pẹ̀lú ayọ̀ báyìí.











