Anthony Joshua ti fi ẹ̀ṣẹ́ rán Jake Paul lọ sílé ìwòsàn, Paul ní Egungun ẹ̀rẹ̀kẹ́ òun ti yẹ̀ lásìkò ìjà ẹ̀ṣẹ́ kíkàn pẹ̀lú Joshua

Ẹṣẹ ọwọ ọtun Joshua dun lẹrẹkẹ Jake Paul.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Abẹṣẹkubioojo ọmọ Naijiria to n ṣoju fun ilẹ Gẹẹsi, Anthony Joshua ti bori idije ẹṣẹ laari noun ati Jake Paul.

Paul ko le ta putu rara ni gbogbo saa idije naa, koda ọpọ lo ri ija ẹṣẹ kikan naa gẹgẹbi eyi to waye laarin oludije meji ti wọn jina sira lori odinwọn ẹṣẹ kikan.

Igba meji ọtọọtọ ni Paul Jake dawo sis aa karun un idije ẹṣẹ kikan naa lọwọ arọọ̀rọda ojo ẹṣẹ ti Anthony Joshua rọ sii lori.

Ẹṣẹ Joshua tun re Paul bọ bi apo ẹwa ni saa, eleyii to mu idije ẹṣẹ kikan naa wa si opin.

Nigba to n sọrọ lẹyin ẹsẹ kikan naa, Joshua ṣalaye pe idije naa "Kii ṣe eyi ti oun ti jafafa julọ"

Ijan aa ni igba kọkandínlọgbọn ti Anthony Joshua yoo maa bori ninu mẹtalelọgbọn to ti ja.

Ọpọ lo ti mọ ibi ti esi idije ẹṣẹ kikan naa yoo bọ si ki wọn tilẹ tobẹrẹ rara.Nibayii, Joshua le wa maa fi oju sọna fun ija miran to le ju iya lọ lọjọ iwaju – boya bii ti ija oun ati Tyson Fury ti ọpọ ti n fi oju sọna fun lati ọpọ igba sẹyin.

Jake Paul di ero ileewosan lẹyin ija oun ati Anthony Joshua

Ẹṣẹ ọwọ ọtun Joshua dun lẹrẹkẹ Jake Paul.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Jake Paul ti di ero ile iwosan bayii lẹyin ti iroyin sọ pe Egungun ẹrẹkẹ rẹ ti kan lẹyin ti Anthony Joshua fi ẹṣẹ fọ ọ ni pari lasiko ija wọn to waye ni ilu Miami lorilẹede Amẹrika.

Jake Paul ko le ba awọn akọroyin sọrọ lẹyin ija naa, ti ọkan lara awọn to si ṣe agbatẹru ija ẹṣẹ kikan laarin oun ati Anthony Joshua naa, Nakisa Bidarian si kede pe, o nilo lati yọju si ileewosan.

"O dabi ẹni pe Egungun pari ẹrẹkẹ rẹ ti kan, amọṣa alaafia lo wa.

Bidarian ṣalaye siwaju sii pe, "O funrarẹ wẹ, o si wa ara rẹ lọ si ile iwosan. Ki Egungun ẹrẹkẹ kan kii ṣe tuntun lagbo ere idaraya, paapaajulọ ẹṣẹ kikan tabi ija ijakadi MMA. Yoo gba a to ọsẹ mẹrin si mẹfa ki ara rẹ to ya pada".