Kéré ó! Májèlé tó léwu fún àgọ́ ara ni oúnjẹ 'Indomie Vegetable Flavour', a ti ń kó o kúrò lọ́jà – NAFDAC kìlọ̀

Àwòrán ọra Indomie olóró àti èyí tí wọn ṣe

Oríṣun àwòrán, Indomie

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ajọ to n ri si ounjẹ ati oogun lilo ni Naijiria, NAFDAC, ti kede pe ounjẹ oniṣẹju aaya indomie kan, 'Indomie Vegetable Flavour' lewu fun jijẹ, ileeṣẹ to n pese ounjẹ naa si ti ni ki wọn ko kuro lọja.

Ninu atẹjade kan ti ọga agba ajọ naa, Ọjọgbọn Mojisola Adeyeye buwọlu, o fidi rẹ mulẹ pe ounjẹ ọhun ko wa lode fun tita ni Naijiria lọwọ yii nitori orilẹede France ni wọn ti n pese rẹ.

Amọ o fi kun pe awọn ti bẹrẹ iṣẹ lati ri daju pe ẹnikẹni ko ounjẹ ọhun wọ Naijiria.

"Noodles wa lara awọn ounjẹ ti ijọba apapọ ti gbẹsẹle pe wọn ko gbọdọ ko wọ Nàìjíríà"

Atẹjade naa sọ pe "fun idi eyii, NAFDAC ti bẹrẹ iṣẹ lati ri daju pe ounjẹ ti wọn ni ki wọn ko kuro lọja naa ko wọ Naijiria.

"A ti bẹrẹ itọpinpin kaakiri awọn ẹkun ati ipinlẹ wa, a si ti paṣẹ fun awọn adari ẹkun atawọn ipinlẹ ki wọn ko awọn ounjẹ naa kuro lọja ti wọn ba kofiri rẹ."

Adeyeye ni awọn ti ṣi ẹka ajọ naa to n ṣọ ẹti okun ni gbẹrẹ ipakọ lati dena ounjẹ ọhun atawọn ounjẹ mii ti wọn ko buwọlu ki wọn ma le wọ Naijiria.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, noodles wa lara awọn ounjẹ ti ijọba apapọ ti gbẹsẹle pe wọn ko gbọdọ ko wọ Naijiria.

O ni "O ṣe pataki lati sọ pe indomie wa lara awọn ounjẹ ti ijọba apapọ fofin de pe wọn ko gbọdọ wọ Naijiria, ko si aaye lati ko wọ Naijiria.

"Eyii n tumọ si pe yoo ṣoro fun ounjẹ ti a n sọ yii lati wọ Naijiria.

NAFDAC ni bo tilẹ jẹ pe ikede yii ti wa nita, oun ko ni dẹkun ati maa ṣọ awọn ounjẹ to n wọ Naijiria loju lẹsẹ lati ri daju pe ounjẹ ti wọn n sọ naa ko si nibẹ.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post