Dele Farotimi jáde lọ́gbà ẹ̀wọ̀n l'Ekiti lẹ́yin tí wọ́n parí ètò béèlì rẹ̀

Dele Farotimi

Oríṣun àwòrán, Dele Farotimi. A victim of Nigeria/X

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Gbajugbaja agbẹjọro ajafẹtọọ ọmọniyan to n foju wina ẹsun ibanilorukọjẹ lọwọ, Dele Farotimi ti jade kuro lahamọ ọlọpaa lẹyin ti wọn ri beeli rẹ gba.

Ọjọ meloo sẹyin ni ileẹjọ Majisireeti to wa niluu Ado-Ekiti, ipinlẹ Ekiti fun Farotimi to n jẹjọ ibanilorukọjẹ, eyi ti agba agba amofin, Afe Babalola fi kan an.

Omoyele Sowore lo fidi iroyin naa mulẹ lojo opo 'X' rẹ laipẹ yii, to si jẹ ko di mimọ pe Farotimi ti wa loju ọna ile rẹ.

Ẹgbẹrun lọna ọgbọn naira ni ile ẹjọ sọ pe ki Farotimi lọ wa, latri le fi gba beeli ara rẹ, pẹlu oniduro meji ọtọọtọ ti wọn ni dukia to nii ṣe pẹlu ilẹ n iluu Ado-Ekiti.

"Ọkan mi balẹ lati sọ fun un yin pe Dele Farotimi ko si lọgba ẹwọn ipinlẹ Ekiti mọ, o si ti n pada sile rẹ l'Ekoo. Ijangbara naa ṣi n tẹsiwaju!," Sowore kọ ọ soju opo 'X'.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post