Wo iye àwọn ìgbà tí àwọn agbébọn ti kọlu àwọn ìletò ní Plateau lásìkò ọdún Kérésìmesì

Ibi ikolu kan

Oríṣun àwòrán, Channels TV

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ko din ni eeyan marundinlogun ti awọn agbebọn kan pa danu lagbegbe Ri Do ti wọn tun n pe ni Gidan Ado, ijọba ibilẹ Riyom, ipinlẹ Plateau lọganjọ oru.

Ọmọ ọwọ tọjọ ori rẹ ko tii ju ọdun kan lọ naa wa lara awọn ti wọn pa danu ninu ikọlu ọhun.

Awọn alakoso agbegbe ti wọn pe ni Irigwe Development Association ninu atẹjade ti wọn fi ranṣẹ sawọn akọroyin jẹ ko di mimọ pe iṣẹlẹ abami ni ikọlu ọhun jẹ.

Atẹjade ọhun ti akọwe ipolongo wọn, Sam Jugo buwọ lu jẹ ko di mimọ pe awọn ọmọ bibi Irigwe ti wọn wa lati Bassa ni wọn tẹ ilu naa do.

Wọn ni awọn ko tii le sọ pato awọn to ṣiṣẹ buruku naa, ati pe oniruuru nnkan ija oloro ti wọn gbe danu lati wa fi ṣe ikọlu, ti wọn si pa eeyan ti ko din ni marundinlogun nipakupa.

Aworan ikọlu.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Jugo sọ pe yatọ si awọn mẹẹdogun to pade iku ojiji yii, o ni ọpọ eeyan lo tun farapa yannayanna lasiko ikọlu naa.

Nigba ti wọn n kọminu lori ikọlu ọhun to waye lọjọ diẹ si ayẹyẹ ọdun Keresimesi, wọn rọ awọn ileeṣẹ eleto aabo kaakiri Naijiria lati dide iranwọ lati rii wọn daabobo awọn eeyan lọwọ iru ikọlu bẹẹ.

Bakan naa ni wọn sọ pe ki wọn ṣọra lati gbẹsan nitori pe o ṣee ṣe ko tun ṣakoba fun awọn lagbegbe naa.

"A ko tii da ẹnikẹni mọ ninu awọn to ṣe ikọlu naa lasiko ti a n pari atẹjade yii, o si ṣe pataki fawọn ileeṣẹ eleto aabo lati ṣe iwadii kikun," atẹjade ọhun sọ.

Ohun to yẹ ki o mọ

Aworan ikọlu.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Kii ṣe igba akọkọ ree ti irufẹ ikọlu bayii yoo maa waye nipinlẹ Plateau, paapaa lasiko ti ọdun Keresimesi bayii ba ti n wọle de.

Lọdun 2023 to kọja, laarin ọjọ kẹtalelogun si ọjọ karundinlọgbọn, oṣu Kejila, awọn agbebọn yawọ awọn abule ti ko din ni ọgọjọ lati ṣe ikọlu.

Awọn abule bii Bokkos, Barkin Ladi ati Magu to wa nipinlẹ Plateau ni awọn agbebọn naa ṣe ikọlu si, ti wọn si pa awọn eeyan ti ko din ni 335.

Awọn ẹlẹsin Kristiẹni to le ni igba ni wọn ba ikọlu ọhun lọ lọdun naa lọhun.

Ki ni ajọ iṣọkan ilẹ Yuroopu sọ?

Atejade ajo EU

Oríṣun àwòrán, EUR-Lex

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ninu akọsilẹ ati atẹjade ti ajọ iṣọkan ilẹ Yuroopu, EU gbe jade lọjọ kẹjọ, oṣu Keji, ọdun 2024, wọn jẹ ko di mimọ pe eto aabo ilẹ Naijiria mẹhẹ pupọ, leyi to fa a ti awọn ẹlẹsin kan fi n kọlu awọn ẹlẹsin Kristẹẹni.

Ajọ EU bu ẹnu atẹ lu bi awọn agbebọn ṣe kọlu awọn ẹlẹsin Kristẹẹni lọjọ diẹ ki wọn ṣayẹyẹ Keresimesi ọlọdọọdun.

"eto aabo ilẹ Naijiria ti mẹhẹ debi wi pe o ti n di ija ẹsin, ẹyamẹya ati ija agbegbe si agbegbe, paapaa lapa aarin gbungbun ilẹ naa, nibi ti a ti ri ija laarin awọn agbẹ ati darandaran lori fifi ẹran jẹko ati oku, leyi to ṣokunfa iku awọn eeyan lasiko Keresimesi.

"to fi jẹ pe laarin ọjọ kẹtalelogun ati ọjọ karundinlọgbọn, oṣu Kejila, ọdun 2023, awọn agbebọn ṣe ikọlu si abulẹ ti ko din ni ọgọjọ lawọn agbegbe to wa ni Bokkos, Barkin Ladi ati Magu nipinlẹ Plateau, leyi to ṣokunfa iku eeyan 335, to fi mọ awọn to le ni igba ti wọn jẹ ẹlẹsin Kristẹẹni."

Ajọ EU jẹ ko di mimọ pe ọpọ awọn ti iṣẹlẹ naa ba lojiji ni wọn wa nibi ti ijọba ko wọn si, nibi ti wọn n gbe lai ni anfaani si omi, itọju ara ẹni, ounjẹ, eto ilera ati bẹẹbẹẹlọ.

Bkan naa ni wọn tẹsiwaju pe gẹgẹ bi awọn ajọ Kristẹẹni ṣe sọ, ẹgbẹrun mejilelaadọta ẹlẹsin Kristẹẹni ati ẹgbẹrun mẹriinlelọgbọn ẹlẹsin Musulumi ni wọn ti pa lati ọdun 2009, ati pe ẹgbẹrun mejidinlogun ile ijọsin ati ẹgbẹrun mejilenigba (2,200) ile-ẹkọ ni wọn ti bajẹ.

Bi ajọ EU ṣe bu ẹnu atẹ lu awọn ikọlu wọnyii, naa ni wọn rawọ ẹbẹ sijọba Naijiria lati dide atunṣe to yẹ, lati le dẹkun irufẹ ikọlu bẹẹ lọjọ iwaju.