Iná sọ lọ́jà kan nílùú Akure, dúkìa àti ọjà ẹgbẹ̀lẹ́gbẹ̀ Naira run

Aworan ọkan lara awọn ṣọọbu to jona
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ijamba ina kan waye ni oru ọjọ Aiku mọju ọjọ Aje ni ilu Akurẹ ti i ṣe olu ilu ipinlẹ Ondo.

Gẹgẹ bi iroyin to tẹ wa lọwọ ṣe sọ, ọpọlọpọ ọja ati dukia olowo iyebiye lo sọnu sinu ijamba ina naa eleyi to kan ile itaja mẹfa, lagbegbe ijoka ni ilu Akurẹ.

Kayefi nla ni iṣẹlẹ yi jẹ fun awọn to ni awọn ile itaja naa, ati awọn olugbe agbegbe ọhun, nitori ko si ẹni to mọ ohun to fa ina yii. Ohun ti a gbọ ni pe kii ṣe gbogbo ile itaja yii lo ina manamana.

Aworan ọkan lara awọn ṣọọbu to jona
Aworan ara dukia ati ọja to jona.

Lasiko ti wọn n ba ileeṣẹ iroyin BBC sọrọ awọn to ni ile itaja naa sọ pe wọn ko lo ina manamana, ẹrọ to n lo oorun (Solar) ni wọn n lo ni gbogbo awọn ile itaja ọhun.

Omije ẹkun gba oju gbogbo awọn oniṣowo to ni awọn ṣọọbu itaja naa lasikoti akọroyin abewo BBC si ile itaja naa. Ariwo ti wọn n pa ni pe owo ele lawọn fi ra ọja, ki wọn le ta ọja ọdun.

Wọn wa n ra ọwọ ẹbẹ si ijọba lati se iranwọ fún wọn nitori gbogbo agbekele wọn lo di ofo bi ina ṣe sọsẹ, tó si jo gbogbo ọja wọn di eeru.

Aworan ọkan lara awọn ṣọọbu to jona.

Lara awọn ohun ti wọn n ta lawọn ṣọọbu itaja ọhun ni, Rice, Tolotolo, Aṣọ ati awọn ohun jíjẹ miran.

Gbogbo ṣọọbu itaja to wa nile itaja naa lo jona ti wọn ko si ri ohunkohun mu kuro ninu wọn.

Awọn olugbe agbegbe naa gboriyin fun ileeṣẹ panapana Ipinlẹ Ondo bi wọn ṣe ji giri lati ri daju pe ina naa ko tan kakiri agbagbe ọhun.