Ààrín òrú làwọn ọlọ́pàá ń pè láti wá gba béèlì Abdulkadir lai mọ̀ pé ó ti kú sí àtìmọ́lé wọn - Ẹbí ọ̀dọ́kùnrin tó kú sí àhámọ́ ọlọ́pàá ní Kwara

Àkọlé fídíò, Agogo méjì òrú làwọn ọlọ́pàá ń pè láti wá gba béèlì Abdulkadir lai mọ̀ pé ó ti kú sí àtìmọ́lé wọn
Ààrín òrú làwọn ọlọ́pàá ń pè láti wá gba béèlì Abdulkadir lai mọ̀ pé ó ti kú sí àtìmọ́lé wọn - Ẹbí ọ̀dọ́kùnrin tó kú sí àhámọ́ ọlọ́pàá ní Kwara

Ṣaaju ogunjọ oṣu kejila ọdun 2024, bi wọn ba sọ fun awọn mọlẹbi Jimoh Abdulkadir Ọlatunji pe agọ ọlọpaa ni yoo gbẹyin aye re si, wọn ko ni gbagbọ.

Lọjọ naa ni iroyin jade pe ọdọkunrin naa ku si agọ ọlọpaa ni ilu Ilọrin.

Oniruuru iroyin lo si ti n jade lori ohun to ṣe okunfa iku rẹ ni agọ ọlọpaa. Bi awọn ọlọpaa ṣe n kede pe Abdulkadir pokunso ni agọ awọn naa lawọn mọlẹbi rẹ n sọ pe irọ nla leyi nitori pe gbogbo apẹrẹ ti awọn n ri lo n fihan pe ọrọ ko ri bẹẹ.

Nitori naa wọn ni ayafi ki awọn ọlọpaa wa sọ otitọ ọrọ to rọ mọ iku ọmọ awọn.

Iya Abdulkadir

Lara idi ti awọn mọlẹbi rẹ fi n lọgun ni pe ni iwoye wọn wọn ni ko si bi ọdọmọkunrin naa ṣe le pokunso, gẹgẹbi ọlọpaa ṣe n sọ, ninu agọ ti wọn ti i mọ naa nitoripe arakunrin naa ga pupọ to bẹẹ to fi jẹ pe iduro rẹ ga ju atẹrigba ahamọ naa lọ.

Ninu ifọrọwerọ wọn pẹlu BBC, iya oloogbe naa Alhaja Morenike Olatunji ati ẹgbẹ rẹ pẹlu ṣalaye pe ilu Ọffa ni Abdulkadir ti n ṣiṣẹ, ọmọ meji to bi si wa lọdọ oun.

Bi iṣẹlẹ naa ṣe waye

Ile Awọn Abdulkadir

Lasiko to n ba BBC Yoruba sọrọ, iya oloogbe naa, Morike Olatunji ṣalaye pe inu ile ni ọmọ oun wa lasiko ti ọkan lara awọn ti wọn jọ n ṣiṣẹ papọ ti orukọ rẹ n jẹ Jelili pe e lati pade ohun ni opopona Balogun Fulani niluu Ilorin.

O ni bo ṣe de ibẹ lo ba awọn ọlọọpa meji ti wọn si gbe Olatunji sori ọkada lọ si olu ọọfisi wọn niluu Ilorin.

Iya Olatunji salaye pe oun lọ si agọ ọlọọpa lati gba ọmọ oun silẹ ṣugbọn awọn ọlọọpa kọ jalẹ, wọn ni ọga rẹ toun ba ṣiṣẹ ti orukọ rẹ n jẹ Gabriel lo jẹ lowo tawọn fi mu.

Ẹgbọn oloogbe to ba wa sọrọ, Ismail Olarewaju ni nnkan bii aagọ mẹwaa alẹ lawọn ọlọpaa pe awọn lati wa gba beli rẹ tawọn si sọ fun wọn pe ki wọn jẹ ki ilẹ mọ.

Ṣugbọn ni gba tawọn de agọ ọlọpaa lọjọ keji ọlọpaa ni Ọlatunji ti ku.

Ismail ni awọn bi ọlọpaa leere ohun to pa ọmọ wọn, wọn ni ṣe ni o pokunso.

O fi kun pe awọn ri ẹjẹ nilẹ.

Nigba ti wọn yoo fi de ile igbokupamọ si, wọn tun ri ẹjẹ ni imu oloogbe ọhun, gẹgẹ bii bii ohun to sọ.

Ọga agba ọlọpaa lorilẹede Naijiria ti da si ọrọ naa pẹlu ileri iwadi to rinlẹ

Ọga ọlọpaa Naijiria lasiko abẹwo si agboole Abdulkadir

Oríṣun àwòrán, nigeria police

Ninu atẹdaje kan, alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Kwara, ASP Adeyẹmi Ejirẹ sọ pe iwadii ti bẹrẹ lori iku ọdọkunrin naa.

Ẹwẹ, ọgba ileeṣẹ ọlọpaa Naijiria, IGP Kayode Adeolu Egbetokun, ti ṣabẹwo si awọn obi oloogbe naa lọjọ Aiku.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa Naijiria, ACP Olumuyiwa Adejobi lo fi ọrọ naa lede.

Adejobi sọ pe ileeṣe ọlọpaa ko ni gba ki awọn oṣiṣẹ rẹ maa ṣi agbara wọn lo, iwadii to peye ni yoo si tẹle iṣẹlẹ naa.

Ti ẹ ko ba gbagbe, nnkan bii oṣu meji ṣeyin ni awọn ọlọpaa lu ọdọkunrin kan pa nipinlẹ Kawara yii kan naa, ti awọn mọlẹbi rẹ ko si tii ri idajọ ododo gba titi di asiko yii.