Kò sí ohun tí mo fẹ́ ju kí wọ́n ju àwọn ọlọ́pàá tó pa ọmọ mi sí ẹ̀wọ̀n igbere lọ - Ìyá Sulyman Ayeyemi pariwo

Aworan Sulyman ati iya rẹ, Alhaja Fausat.

Oríṣun àwòrán, Others/BBC

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ni ọjọ ti ikọ BBC de ile Sulymana Ayeyẹmi, ọdọmọkunrin akẹkọọ ileẹkọ gbogbniṣe Kwarapoly, gbogbo rẹ lo dakẹ paroparo ti ọpọ awọn ero to nlọ tabi bọ si n kawọ gbera ni idaro. Bẹẹni awọn miran n kawọ mọ ori ti wọn si n fi ẹsẹ janlẹ.

Omije loju, ohun ọfọ lẹnu ni Alhaja Fausat Ayeyemi Kareem fi n ṣalaye bi ọrọ iku ọmọ rẹ, Sulyman Ayeyẹmi, ti iroyin gbe sita lọjọ diẹ sẹyin pe awọn ọlọpaa kan lu pa ni ilu Ilọrin ṣe jẹ.

Ṣe wọn ni ko si ẹni to mọ okolo lode Ọyọ ko toi di wi pe o jo ile ọba, ko fẹrẹ si ẹnikẹni, yatọ si awọn eeyan olugbe agbegbe Adabata ni ilu Ilorin, ipinlẹ Kwara to mọ Sulyman ati iya rẹ ko to di wi pe iṣẹlẹ buruku yii ṣẹ.

Alaja Ayeyẹmi ni owo ati ẹbẹ latọdọ ẹnikẹni ko le tan ọgbẹ ti iku naa da si oun lọkan, nitori naa idajọ ododo nikan lo le nu omije naa kuro ki awọn to pa ọmọ oun jẹ iya ẹsẹ wọn ki awọn naa le mọ bo se n ri lara.

O ni ọmọ oun kẹkọ yege ninu imọ kọmputa (Computer Science) to si yẹ ko lọ fun eto agunbanirọ NYSC rẹ loṣu kinni ọdun 2025, sugbọn wọn o jẹ ki oun jere rẹ.

Iya oloogbe naa tun ni ọmọ ohun o ni aisan asthma gẹgẹ bi awọn ọlọpaa ṣe sọ, o ni irọ ni nitori ọmọ oun o lee ni iru aisan bẹẹ ki oun iya rẹ ma mọ si.

O fi kun un pe lilu ti wọn lu u lo fa iku ojiji ọmọ oun ati pe ọna ati da ọwọ ododo bi wọn ṣe ṣokunfa iku rẹ lo mu ki wọn maa sọrọ aisan ti ko si lara ọmọ oun.

Ọmọbinrin kan lawọn ọlọpaa naa fi dẹ panpẹ fun Sulyman – Alhaja Fausat Ayeyẹmi Kareem

Alhaja Fausat Ayeyemi, Iya Sulyman.

Ninu ọrọ rẹ, o salaye pe, Abuja ni oun n gbe sugbọn alaye ti wọn se fun oun ni pe, Sulyman wa nibi to ti n gẹrun ori rẹ nigbati ọmọbinrin kan pe e, wi pe ibo lo wa?

"Ọmọbinrin naa ni ko wa ba oun ni orita Tanke, igba to de bẹ, wọn o ri arawọn, obinrin yẹn bi lere pe ko sapejuwe aṣọ to wọ ki o baa le ri.

Iya Sulyman ni Ọmọbinrin yi ni wọn fi dẹ panpẹ fun ọmọ oun, nitori pe alaye aṣọ rẹ to ṣe tan fun ọmọbinrin naa ni awọn ọlọpaa ba he e laṣọ mu.

Gbogbo bi awọn eeyan to wa lagbegbe naa ṣe n pariwo pe ki wọn fi silẹ lawọn agbofinro naa kọ eti ikun si, gẹgẹ bi alaye ti iya Sulyman ṣe fun BBC.

O ṣalaye siwaju sii pe ohun ti awọn ti iṣẹlẹ naa ṣoju wọn sọ ni pe bi wọn ṣe n lu u ni wọn n la idi ibọn mọ ọ lori.

Ṣe lootọ ni pe gbese N200, 000 lawọn ọlọpaa wa sin Sulyman ki o to jade laye?

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

"Ọmọ ti mo ti n re lati kekere, to wa di igba to kawe yege, awọn ọlọpaa kan wa lu pa, nkan to n pariwo nipe ki wọn maa gbe ohun lọ si ilu Ganmo nitori pe ọlọpaa Ganmo o lasẹ lati wa mu eyan ni Tanke, tori Tanke naa ni agọ ọlọpaa tirẹ.

Iroyin ti o n lọ kaakiri ni pe gbese ẹgbẹrun lọna igba Naira ti wọn ni Sulyman jẹ ọrẹ rẹ kan loni tọun lọ pe awọn ọlọpaa lati wa ba a gba eyi to ja si iku fun un.

Amọṣa nigba ti BBC gbiyanju lati mọ okodoro ọrọ yii lẹnu iya rẹ, awn mọlẹbi ni ko daa le lori ọrọ naa ni.

Amọṣa, Alhaja Fausat Ayeyẹmi ni bi o ti wu ko jẹ, ‘ki wọn wa ki n fun wọn lowo wọn, ki awọn naa si da ọmọ mi pada fun mi’.

O tun ṣe alaye wi pe ọga agba ileeṣẹ ọlọpaa lẹkun Ganmọ ti wa lati rawọ ẹbẹ si awọn ẹbi oloogbe naa, paapaa oun ti oun jẹ iya rẹ. O ni ohun ti oun fọ lesi fun un, ti ko si yipada.

“O wa bẹ mi, emi o gbẹbẹ o, ọmọ temi ni mo fẹ o, kan ko awọn to pa a jade ki n ri wọn.

“Ọmọ mi kii jale, kii mọti, ko si iwa jagidi jagan kankan lọwọ rẹ, nọmba ọmọbinrin to pe e jade ati chat wọn moti ri, mo fẹ ri gbogbo wọn.”

Ariwo idajọ ododo ni iya Sulyman n pa bayii. O ni oun fẹ ki kẹkẹ idajọ rin lori ọrọ naa ki wọn si fi ijiya to ba tọ jẹ gbogbo awọn ti o ba lọwọ ninu iku ọmọ rẹ naa.

“Unknown person” ni wọn lẹ mọ oku Sulyman lara nigba ti a rii ni ilewosan - Ẹ̀gbọ́n ìyá Sulyman

Bakanna, ẹgbọn iya Sulyman, Alhaja Iyabọ Lawan ba wa sọrọ lori iṣẹlẹ naa, o ni ohun loun wa ni Ilorin pe igba ti awọn n wa kakiri ni awọn gbọ pe awọn ọlọpaa lu eyan kan ti wọn gbe inu kẹkẹ Marwa lọ si Ganmo.

"Igba ta de Ganmọ, wọn ni ko si lọdọ awọn, a lọ si olu Ileesẹ ọlọpaa ni Ilorin, ibẹ lati gbọ pe awọn ọlọpaa ti lu ọmọ pa.

"Ibi ti wọn n gboku si nileewosan gbogbogbo ni Ilorin lati pada ri ti wọn kọ "Unknown person" sii lara.

"Ẹ bawa bẹ awọn ọlọpaa Kwara ki wọn saanu wa o, o ti n pọ ju o.