Jimmy Carter: Àgbẹ̀ ẹlẹ́pà tó di ààrẹ America, jáde láyé lẹ́ni ọgọ́rùn-ún ọdún

Àkọlé fídíò, Watch: A look back on the life of former US President Jimmy Carter
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ààrẹ tẹ́lẹ̀ rí ní orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà, Jimmy Carter ti dágbére fáyé lẹ́ni ọgọ́rùn-ún ọdún.

Òun ní ẹni àkọ́kọ́ tó ti jẹ ààrẹ Amẹ́ríkà rí tí yóò lò to ọgọ́rùn-ún ọdún lórí òkè eèpẹ̀.

Ní oṣù Kẹwàá ọdún yìí ló ṣe ayẹyẹ ọgọ́rùn-ún ọdún rẹ̀.

Àjọ rẹ̀, Carter Center, to wà fún pípolonogo ètò ìjọba àwaarawa àti jíjà fún ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn káàkiri àgbáyé tó kéde ikú rẹ̀ ní ọ̀sán ọjọ́ Àìkú ni ààrẹ tẹ́lẹ̀ rí náà jáde ní ilé rẹ̀ tó wà ní Plains, Georgia.

Lẹ́yìn Watergate ni Jimmy Carter gba àkóso ìjọba Amẹ́ríkà tó sì ṣèlérí nígbà náà pé òun kò ni parọ́ fáwọn èèyàn orílẹ̀ èdè náà.

Òun ni ààrẹ Amẹ́ríkà àkọ́kọ́ tó mu ọ̀rọ̀ àyípadà ojú ọjọ́ ní òkúnkúndùn.

Lórí ọ̀rọ̀ ilẹ̀ òkèrè, Carter nígbà ìṣèjọba rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ààrẹ Amẹ́ríkà ṣokùnfà bí àlááfíà ṣe jọba láàárín Egypt àti Israel.

Látara àwọn ìbáṣepọ̀ tó dán mọ́rán láàárín ọdún 1970, Carter kéde ní ọdún 1979 ní Amẹ́ríkà yóò bẹ̀r.ẹ̀ ìbáṣepọ̀ pẹ̀lú Beijing.

Èyí túmọ́ sí pé Amẹ́ríkà yóò pa gbogbo ìbáṣepọ̀ tó ní pẹ̀lú Taiwan wà rẹ́, tí wọ́n sì ti iléeṣẹ́ US tó wà ní Taiwan rẹ́.

Sáà kan ni Carter lò lórí ipò gẹ́gẹ́ bí ààrẹ Amẹ́ríkà kí Ronald Reagan tẹgbẹ́ òṣèlú Republican tó gba ipò náà mọ́ lọ́wọ́ níbi ètò ìdìbò tó wáyé lọ́dún 1980.

Ìpínlẹ̀ mẹ́fà péré ni Carter ti borí ìbò níbi ètò ìdìbò ààrẹ tó wáyé náà.

Lẹ́yìn tó kúró nípò ààrẹ, Carter tẹ̀síwájú láti máa pè fún àlááfíà káàkiri àgbáyé, àyíká àti jíjà fún ẹ̀tgọ́ ọmọnìyàn ní èyí tí wọ́n fi fun ní àmì ẹ̀yẹ "Noble Peace Prize".

Jimmy Carter ni oko ẹ̀pà rẹ̀ lọ́dún 1976

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Jimmy Carter ni oko ẹ̀pà rẹ̀ lọ́dún 1976

Ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ Jimmy Carter

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ní ọjọ́ Kìíní, oṣù Kẹwàá ọdún 1924 ni wọ́n bí James Earl Carter ní ìlú Plains, Georgia.

Òun ni àkọ́bí ọmọ mẹ́rin táwọn òbí rẹ̀ bí.

Iṣẹ́ àgbẹ̀ ẹlẹ́pà ni bàbá rẹ̀ ń ṣe, tí ìyá rẹ̀ sì jẹ́ akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ nọ́ọ̀sì.

Ìgbàgbọ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọmọ ìjọ Onítẹ̀bọmi ṣe atọ̀nà àwọn ìwà àti òun to gbàgbọ́ nípa òṣèlú.

Ó máa ń gbá bọ́ọ̀lù aláfọwọ́jùsáwọ̀n nígbà tó wà ní ilé ẹ̀kọ́ girama.

Ọdún méje ló fi ṣiṣẹ́ pẹ̀lú iléeṣẹ́ ọmọ ogun orí omi níbi tó ti fẹ́ ìyàwo rẹ̀ Rosalynn, ẹni tí Carter jùwe bíi olùrànlọ́wọ́ òun pàtàkì nínú gbogbo ohun ti òun jẹ́ láyé.

Ọdún mẹ́tàdínlọ́gọ́rùn-ún ni òun àti ìyàwó rẹ̀ fi jọ wà papọ̀ kó tó di pé ìyàwó rẹ̀ jáde láyé nínú oṣù Kọkànlá ọdún 2023.

Lẹ́yìn ikú bàbá rẹ̀ lọ́dún 1953, ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ àgbẹ̀ ẹ̀pà tí babá rẹ̀ ń ṣe.

Nǹkan kò lọ dédé fún Carter ní ọdún àkọ́kọ́ tó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ àgbẹ̀ naà nítorí ọ̀gbẹlẹ̀ tó wáyé nígbà náà ṣùgbọ́n tó ṣe àyípadà iṣẹ́ náà tó sì ti ara bẹ́ẹ̀ di ọlọ́lá.

Ó darapọ̀ mọ́ òṣèlú láti ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀, níbi tí wọ́n ti yàn-án sawọn ipò ní ilé ẹ̀kọ́ kó tó di pé wọ́n yàn-án sípò aṣòfin fún Georgia.

Jimmy Carter ní Georgia pẹ̀lú bàbá Martin Luther King

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Jimmy Carter ní Georgia pẹ̀lú bàbá Martin Luther King.

Ajàfẹ́tọ̀ọ́ ọmọnìyàn

Jimmy Carter

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Jimmy Carter kó ẹ̀pà dání lásìkò tó ń polongo láti díje fún ipò ààrẹ

Níṣe ni agbo òṣèlú Amẹ́ríkà bẹ̀rẹ̀ sí ní gbóná janjan lẹ́yìn ilé ẹjọ̀ tó ga jùlọ kéde láti da àwọn ilé ẹ̀kọ́ papọ̀ nígbà náà.

Àwọn èèyàn gbàgbọ́ pé Carter kò ní faramọ́ ètò náà nítorí pé bàbá rẹ̀ wá láti gúúsù àmọ́ Carter kò tẹ̀lé ipa bàbá rẹ̀.

Sáà mejéèjì tó lò ní ilé aṣòfin, Carter gbìyànjú láti yàgò fún gbogbo àwọn nǹkan tó le fa wàhálà láàárín àwọn tó ń pè fún àyípadà yìí.

Nígbà tó di gómìnà Georgia lọ́dún 1970 ló fi ihà tó kọ sí ìjàfẹ́tọ̀ọ́ ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn hàn dáadáa.

Ó ri dájú pé àwọn ọmọ ilẹ̀ Áfíríkà tó jẹ́ ọmọ Amẹ́ríkà dé ipò òṣèlú lọ́pọ̀lọpọ̀.

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Carter ṣe àtìlẹyìn fún àwọn obìnrin tó bá fẹ́ ṣẹ́ oyún, ìgbàgbọ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ ẹlẹ́sìn ìgbàgbọ́ kò jẹ́ kó le mú àlékún bá owó tó wà fún ètò náà lásìkò rẹ̀.

Nígbà tó ń díje fún ipò ààrẹ lọ́dún 1974, ó pe ara rẹ̀ ní ọmọ àgbẹ̀ ẹlẹ́pà tí kò ní àbàwọ́n kankan lórí ọ̀rọ̀ òṣèlú.

Nígbà tó fi máa kúrò lórí ipò, ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ààrẹ tí wọn kò gbádùn dáadáa àmọ́ tó ṣe àtúnṣe orúkọ rẹ̀ lẹ́yìn tó kúrò lórí ipò.

Ó bẹ̀rẹ̀ ètò pípè fún àlááfià lórúkọ ìjọba Amẹ́ríkà káàkiri àgbàyé.

Ní ọdún 2002 ló di ààrẹ Amẹ́ríkà kẹta lẹ́yìn Theodore Roosevelt àti Woodrow Wilson tó gba àmì ẹ̀yẹ Nobel Peace Prize.

Ìgbé ayé lẹ́yìn ìfẹ̀yìntì

Jimmy Carter níbi ètò ìsìnkú ìyàwó rẹ̀ lọ́dún 2023

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Jimmy Carter níbi ètò ìsìnkú ìyàwó rẹ̀ lọ́dún 2023

Lẹ́yìn tí Carter fẹ̀yìntì lẹ́nu iṣẹ́, ó gbé ìgbé ayé tó rọrùn.

Ó padà sí Plains, Georgia níbi tí wọ́n ti bí òun àti ìyàwó rẹ̀ láti lọ máa gbé.

Òun ààrẹ kan ṣoṣo lóde òní tó padà sí ilé rẹ̀ tó ń gbé tẹ́lẹ̀ kó tó wọ òṣèlú, ilé alájà kan tó ní yàrá méjì péré.

Ní ọdún 2015 ló kede pé wọ́n ń ṣe ìtajú òun fún àìsàn jẹjẹrẹ, àìsàn tó pa àwọn òbí rẹ̀ àtàwọn àbúrò rẹ̀ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta.

Ọdún 1984 ni òun àti ìyàwó rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ ṣíṣe ìtọrẹ àánú tí wọ́n sì ṣe àtúnṣe ilé tó lé ní ẹgbẹ̀rún mẹ́rin láti ìgbà náà.

Ó tẹ̀síwájú láti máa ṣe ìdánilẹ́kọ̀ọ́ ìmọ̀ bíbélì ní ilé ìjọsìn Maranatha Baptist Church ní Plains.

Ní oṣù Kọkànlá, ọdún 2023 ni ìyàwó rẹ̀, Rosalynn jáde láyé lẹ́yìn ti wọ́n lo ọdún mẹ́tàndín lọ́gọ́rin papọ̀.

Níbi ètò ayẹyẹ ọjọ́ ìbí ọgọ́rùn-un ọdún rẹ̀ lóké èèpẹ̀, Carter ní òṣèlú ṣì wà nínú ẹ̀jẹ̀ òun àti pé òun máa dìbò fún Kamala Harris.