Èèyàn tó pàdánù ẹ̀mí wọn sínú ìjàmbá ọkọ̀ òfurufú South Korea di 179

Ọkọ̀ òfurufú tó jóná

Oríṣun àwòrán, EPA

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Àwọn èèyàn tó ti bá ìṣẹ̀lẹ̀ ìjàmbá ọkọ̀ òfurufú tó gbiná ní South Korea ti di mọ́kàndínlọ́gọ́sàn-án (179) báyìí.

Iléeṣẹ́ tó ń rí sí ọ̀rọ̀ ilẹ̀ àti ètò ìrìnnà ní orílẹ̀ èdè náà ní àwọn ti ní àǹfàní sí ọọ̀ ofurufú náà àti pé ẹ̀rọ agbohùnsílẹ̀ yóò ṣe ìrànwọ́ fáwọn lati mọ okùnfà ìjàmbá náà.

Iléeṣẹ́ ìròyìn abẹ́lé kan sọ pé ọ̀kan lára àwọn èrò inú ọkọ̀ òfurufú náà ti ṣaájú fi àtẹ̀jíṣẹ́ ránṣẹ́ sí ẹbí rẹ̀ kan pé ẹyẹ kan ń ṣe ìdàmú fún ọkọ̀ àwọn láti bà sílẹ̀.

"Ṣé kí ń sọ ọ̀rọ̀ ìkẹyìn mi ni," èrò náà kọ sí ìbátan rẹ̀.

Ó ní lati ìgbà náa ni àwọn kò ti ri bá sọ̀rọ̀ lórí ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ rẹ̀ mọ́.

Ní ṣe ni ọ̀pọ̀ àwọn ẹbí àti ọ̀rẹ́ àwọn èèyàn tó wà nínú ọkọ̀ òfurufú náà kún pápákọ̀ fọ́fọ́ láti ṣàwárí àwọn èèyàn wọn.

Ìjàmbá ọkọ̀ òfurufú gbẹ̀mí èèyàn 127 ní South Korea

Ọkọ̀ òfurufú tó jà

Oríṣun àwòrán, Reuters/YONHAP

Ọkọ̀ òfurufú Boeing 7-3-7 ọ̀hún, tó ń rin ìrìnàjò bọ̀ láti Bangkok, orílẹ̀-èdè Thailand, ló ti bà sílẹ̀ tán ní pápákọ̀ òfurufú Muan International Airport kí ìjàmbá náà tó wáyé.

Èèyàn mọ́kànlélọ́gọ́sàn-án, tó fi mọ́ àwọn èrò márùndínlọ́gọ́sàn-án àtàwọn òṣìṣẹ́ mẹ́fà ló wà nínú ọkọ̀ òfurufú náà kí ìjàmbá náà tó wáyé. Òṣiṣẹ́ bàálù méjì ni wan ri yọ láàyè.

Ìròyìn tó tẹ̀ wá lọ́wọ́ ní, bí ọkọ̀ náà ṣe yà bàrà kúrò lójú ọ̀nà to yẹ kó rìn lẹ́yìn tó balẹ̀ tán ni ó lọ kọlu ògiri kan to sì gbiná lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀.

Àwọn tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣojú wọn ní àwọn kàn déédéé dé gbọ́ ìbúgbàmù lójijì.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Apá kan ọkọ̀ náà ni ó jóná pátápátá, tí èéfín sì gbalẹ̀ ní agbègbè tí ìjàmbá náà ti wáyé.

Iléeṣẹ́ panápaná ní èèyàn méjì ni wọ́n ti rí yọ láàyè báyìí, tí akitiyan sì ń lọ lọ́wọ́ láti yọ àwọn èèyàn tó wà nínú ìjàmbá náà.

Wọn kò tíì lè fi ìdí ohun tó ṣokùnfà ìjàmbá náà múlẹ̀, àmọ́ àwọn iléeṣẹ́ ìròyìn abẹ́lé ní ó ṣeéṣe kó jẹ́ pé ẹyẹ ló kó sínú ẹngiini ọkọ̀ òfurufú náà.

Iléeṣẹ́ panápaná South Korea ní òkú èèyàn mẹ́rìnlélọ́gọ́fa ni àwọn ti yọ báyìí, tí mẹ́rìnléláàdọ́ta nínú wọn jẹ́ ọkùnrin, táwọn mẹ́tàdínlọ́gọ́ta sì jẹ́ obìnrin.

Bákan náà ni wọ́n ní àwọn mẹ́tàlá ló jóná kọjá mímọ̀, tí wọn kò sì dá wọn mọ̀ bóyá ọkùnrin tàbí obìnrin ni wọ́n.

Ìjàmbá ọkọ̀ òfurufú ni ó jẹ́ tó burú jùlọ tó máa wáyé ní South Korea ati ìgbà àkọ́kọ́ tí ọkọ̀ òfurufú Jeju Air yóò ní ìjàmbá láti bíi ogún ọdún tí wọ́n ti ń ṣiṣẹ́.

Adelé ààrẹ South Korea, Choi Sang-mok ti kéde Muan gẹ́gẹ́ bí ìṣẹ̀lẹ̀ ìjàmbá ńlá ti wáyé.

Adarí iléeṣẹ́ ọkọ̀ òfurufú Jeju Air ti tọrọ àforíjì lọ́wọ́ àwọn aráàlú tí ìjàmbá náà mú ẹ̀mí àwọn èèyàn wọn lọ.