Mọ̀ nípa ìrìnàjò Olorì Naomi láti ìgbà èwe títí di olùtọrẹ àánù

Oríṣun àwòrán, Naomi Silekunola/Instagram
Ní ọdún 2018 ni òkìkí Olori Silekunola Moronke Naomi kàn káàkiri ilẹ̀ Yorùbá àti Nàìjíríà lápapọ̀ nígbà tí Ooni Ile-Ife, Ọba Enitan Ogunwusi, Ojaja Kejì kéde rẹ̀ bí ẹni tí yóò di olorì láàfin lẹ́yìn tí ìyàwó rẹ̀ kọ̀ ọ́ sílẹ̀ nígbà náà.
Olorì Naomi ni ìyàwó alárédè kejì tí Ooni gbé ní ìyàwó níṣu lọ́kà lásìkò náà.
Ṣáájú ìgbéyàwó wọn lọ́dún 2018 ni Ooni fi ojú Naomi hàn gẹ́gẹ́ bí olólùfẹ́ rẹ̀, tó sì ní òun ti rí ààyò ọkàn òun.
Ọ̀pọ̀ èèyàn nígbà náà ló ń bèèrè pé taa ni arẹwà, ọ̀dọ́bìnrin tí Ooni fẹ́ gbé níyàwó nígbà náà nítorí Naomi kìí ṣe gbajúmọ̀ àti pé báwo ni òjíṣẹ́ Ọlọ́run tó máa ń ṣe àwọn ètò ìgbàgbọ́ onírúurú pẹ̀lú iṣẹ́ àmì àti ìyànú yóò ṣe yàn láti fẹ́ Ọba níbi tí àṣà àti ìṣẹ̀ṣe ilẹ̀ Yorùbá ti gbilẹ̀?
Ta ni olorì Silekunola Naomi?
Ní ọdún 1993 ni wọ́n bí, tí wọ́n si sọ ọ́ ní Naomi Oluwaseyi.
Ọmọ bíbi ìlú Akure, olú-ìlú ìpínlẹ̀ Ondo ni Naomi.
Òun ni olùdásílẹ̀ Iléèṣẹ́ ìránṣẹ́ En-Heralds tó wà ní ìlú Akure.
Ọdún 2018 ló fẹ́ Ooni Ile-Ife, tó sì kéde ìpínyà wọn lọ́dún 2021 lẹ́yìn ọdún mẹ́ta tí wọ́n fẹ́ra.
Ọdún 2020 ni ó bí ọmọ rẹ̀ kan ṣoṣo fún Ooni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Tadenikawo.
Ẹní ọdún mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n ló wà nígbà tó di Olorì Ile-Ife.
Òun náà ni olùdásílẹ̀ àjọ ẹlẹ́yinjú àánú, Women In Need Of Guidance and Support (WINGS).
Ìgbéyàwó Naomi pẹ̀lú Ooni Ogunwusi

Oríṣun àwòrán, Others
Ìdùnnú àti ayọ̀, tó fi mọ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ayẹyẹ ni wọ́n fi ṣègbéyàwó lọ́dún 2018 àmọ́ kò ju ọdún mẹ́ta tí ìgbéyàwó Olorì Naomi àti Ooni fi forí ṣọ́pọ́n.
Ní oṣù Kejìlá, ọdún 2021, Naomi ya ọ̀pọ̀lọpọ̀ lẹ́nu nígbà tó kọ sójú òpó Facebook rẹ̀ lọ́dún náà lọ́hùn-ún pé òun kìí ṣe olorì Ile-Ife mọ́ bíkòṣe olorì gbogbo èèyàn.
Ó ní òun ti kọ Ooni sílẹ̀ àti pé òun ti ń dá ṣe ìyá ọmọ òun.
Olorì Naomi sọ nínú àtẹ̀jáde tó kọ náà pé ọ̀tọ̀ ni ojú tí àwọn èèyàn fi ń rí Ooni níta àti pé ìhà tó kọ sí òun nínú ilé yàtọ̀ gédégédé síra wọn.
Láàárín ọdún mẹ́ta yìí, wọ́n bí ọmọkùnrin kan lọ́dún 2020 tí wọ́n sọ ní Tadenikawo.
Iṣẹ̀ wòlíì
Ní ọdún 2011, lẹ́ni ọdún méjìdínlógún ni olorì Naomi Silekunola padà sí ìdí iṣẹ́ ìránṣẹ́ lẹ́kùnrẹ́rẹ́ gẹ́gẹ́ bíi wòlíì ní iléeṣẹ́ ìránṣẹ́ En-Heralds Ministries.
En-Heralds Ministries jẹ́ ìpéjọpọ̀ tó da gbogbo ìjọ pọ̀ èyí tó kalẹ̀ sí ìlú Akure ní ìpínlẹ̀ Ondo.
Ó jẹ́ olùdarí ẹ̀mí tó sì tún jẹ́ ajíyìnrere tó máa ń ṣe ìsọjí tí èrò sì máa ń pọ̀ níbẹ̀.
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òjíṣẹ́ Ọlọ́run ni Naomi, gbogbo àṣà àti ìṣe tó rọ̀ mọ́ ìgbéyàwó olorì Ile-Ife ni ó kópa níbẹ̀ nígbà tó ṣe ìgbéyàwó pẹ̀lú Ooni.
Lára ètùtù tó ṣe nígbà náà ni títẹ ẹ̀jẹ̀ ẹranko kọjá wọ ààfin gẹ́gẹ́ bí ìyàwó Ooni.
Ṣíṣe ìtọrẹ àánú dé ọgbà ẹ̀wọ̀n

Oríṣun àwòrán, Naomi Silekunola/Instagram
Ọ̀pọ̀ àwọn àkànṣe iṣẹ́ ìdàgbàsókè ni o ti kópa níbẹ̀ pàápàá àwọn tó ní ṣe pẹ̀lú ríró obìnrin lágbára.
Olorì Naomi kò jẹ́ kí gbogbo ìdojúkọ tó ti là kọjá kó àárẹ̀ ọkàn bá òun nídìí ṣíṣe ìtọrẹ àánú fún àwọn aláìní lábẹ́ àjọ ẹlẹ́yinjú àánù rẹ̀.
Irúfẹ́ ìtọrẹ àánú ni àjọ rẹ̀ gbé kalẹ̀ láti fi ran ẹgbẹ̀rún márùn-ún ọmọdé lọ́wọ́ ní ìlú Ibadan lọ́jọ́ kejìdínlógún, oṣù Kejìlá, ọdún 2024 àmọ́ tí ọ̀rọ̀ bá ibòmíràn yọ.
Ilé-ẹ̀kọ́ Islamic High School tó wà ní agbègbè Bashorun ni ètò náà ti wáyé àmọ́ èrò tó wà níbi ètò náà jẹ́ kí ọmọdé bíi màrúndínlọ́gbọ̀n di èrò ọ̀run.
Ọdọọdún ni olorì Naomi máa ń ṣe àríyá ọdún fún àwọn ọmọdé ní ìlú Akure tó ń gbé, tó sì pinnu láti ṣé ní Ibadan lọ́dún yìí àmọ́ tí ètò náà kò lọ bó ṣe yẹ.
Ìròyìn sọ pé èrò tó pọ̀ jù nínú ọgbà ilé ẹ̀kọ́ náà lo jẹ́ kí àwọn èèyàn máa tẹ ara wọn pa, tí ọmọdé tó sì ú níbi ètò náà jẹ́ márùndínlógójì.
Èyí fa ọ̀pọ̀lọpọ̀ awuyewuye pàápàá lórí ayélujára tí iléeṣẹ́ ọlọ́pàá sì nawọ́ gán Naomi àti olùdásílẹ̀ iléeṣẹ́ rédíò Agidigbo FM tó wà ní ìlú Ibadan, Oriyomi Hamzat gẹ́gẹ́ bíi agbátẹrù ètò náà.
Ní ọjọ́ kẹrìnlélógún, oṣù Kejìlá, ni Adájọ́ ilé-ẹjọ́ Májísíréètì tó wà ní Iyaganku ní ìlú Ibadan tí àwọn ọlọ́pàá gbé ẹjọ́ náà lọ ní kí olorì Naomi, Oriyomi Hamzat àti ọ̀gá àgbà ilé-ẹ̀kọ́ Islamic High School wà ní àhámọ́ ọgbà ẹ̀wọ̀n títí di ìgbà ti ìgbẹ́jọ́ wọn yóò tún wáyé.
Níṣe ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn ti ń rọ ìjọba láti bojú àánú wo Naomi lórí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí.















