Olórí ológun Niger sọ pé Nàìjíríà àti France gbìmọ̀ pọ̀ láti da orílẹ́èdè náà rú, ìjọba Tinubu fèsì

Aarẹ Bola Tinubu ati OLori ologun Niger

Oríṣun àwòrán, ORTN/Bola Tinubu/X

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ijọba orilẹede Naijiria ti fesi si awọn ẹsun ti olori ijọba ologun orilẹede Niger, Ọgagun Abdourahmane Tchiani, fi kan Naijiria pe ijọba Aarẹ Bola Tinubu n gbimọ pọ pẹlu France lati da orilẹede Niger ru.

Ọgagun Tchiani ṣalaye ninu ifọrọwerọ wakati meji ati aabọ to ṣe ni ede Hausa pe orilẹede France n ṣe ajọṣepọ pẹlu awọn ikọ ajijagbara kan lẹkun Lake Chad.

O ni orilẹede Naijiria mọ si ohun ti France n ṣe yii lati le din agbara ileeṣẹ ologun Niger ku.

Awọn ẹsun ti olori ijọba ologun Niger fi kan Naijiria yii tun jẹ ọna tuntun ti aawọ to wa laarin Niger ati Naijiria tun bayọ lati igba tawọn ologun ti doju ijọba Aarẹ Mohamed Bazoum Niger bolẹ lọdun 2023.

Ẹwẹ, ajọ Ecowas ti Tinubu jẹ alaga rẹ ti fofin de Niger tẹlẹ lori ọrọaje.

Koda ajọ Ecowas ṣeleri lati lo awọn ọmogun ti ijọba ologun to wa lori oye ko ba tẹle iwe ofin orilẹede naa.

Amọ, orilẹede Niger ti binu kuro ni ajọ Ecowas, ijọba ologun nibẹ si sọ fun France ati awọn orilẹede to ti goke agba lagbaaye mii lati wa ko awọn ọmogun wọn kuro ni Niger.

Lẹyin naa ni ijọba ologun Niger ṣe idasilẹ ọmogun apapọ pẹlu awọn orilẹede to wa lẹgbẹ wọn bii Mali ati Burkina Faso nibi tawọn ologun ti gbajọba bakan naa.

Esi ijọba apapọ Naijiria si ẹsun ti Niger fi kan ijọba Tinubu

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ninu ọrọ rẹ, oludamọran lori ọrọ eto aabo, Nuhu Ribadu, sọ fun BBC Hausa wi pe awọn ẹsun ti olori ologun Niger fi kan Naijiria ko lẹsẹ nlẹ.

Ribadu ni irọ to jina si ootọ ni gbogbo ọrọ ti Ọgagun Tchiani sọ nipa Naijiria, ati pe Naijiria ko ni ṣe aburu si Niger laelae tabi gbẹyin bẹbọ jẹ fun orilẹede naa.

''Koda, ilẹ Gẹẹsi to ko Naijria lẹru gan an ko tii ko ọmogun rẹ wa si Naijiria ri.

Ile Gẹẹsi gbiyanju lati ko ọmogun wọn wa Naijiria, orilẹede France naa gbiyanju lati ṣe bẹẹ.

Ṣugbọn ijọba Naijiria ko gba pẹlu wọn, ki ni yoo wa mu wa pada sori ọrọ naa?''

Minisita eto iroyin ni Naijiria, Mohammed Idris, naa sọ pe ọna lati bo ijakulẹ ijọba rẹ mọlẹ ni gbogbo ọrọ ti Ọgagun Tchiani n sọ nipa Naijiria.

Minisita eto iroyin tun sọ pe irọ nla ni ọrọ mii ti ijọba ologun Niger sọ pe Naijiria n ṣakoba fun fun eto ọgbin ati ọpa epo rọ orilẹede naa.

O ni Naijiria gan an ti ṣe iranwọ fun Niger nigba ṣiṣe ọpa gaasi lọ sibẹ ati ọkọ oju-irin lati Kano lọ si ilu Maradi ni Niger.