Ẹlẹ́wọ̀n 1,500 sálọ kúrò lọ́gbà ẹ̀wọ̀n lásìkò ìwọ́de èsì ìbò, èèyàn 21 jáde láyé

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Nnkan bii ẹgbẹrun kan abọ ẹlẹwọn ti sa kuro ninu ẹgba ẹwọn kan lorilẹede Mozambique lẹyin ti rogbodiyan oṣelu bẹ silẹ nibẹ..
Iroyin niṣe lawọn ẹlẹwọn ọhun lo anfani rogbodiyan to n lọ lọwọ nilẹ naa latari ifẹhonuhan to tẹle eto idibo to waye nibẹ ṣaaju.
O kere tan, eeyan mẹtalelọgbọn lo padanu ẹmi nigba ti eeyan marundinlogun mii farapa lasiko ti araalu kọju ija si awọn agbofinro.
Olori ileeṣẹ ọlọpaa, Bernadino Rafael sọ fun awọn akoroyin pe ọwọ awọn ti tẹ ẹlẹwọn 150 pada.
Ọjọ Aje ni ifẹhonunan bẹrẹ lẹyin ti ile ẹjọ to ga julọ nilẹ ọhun fidi rẹ mulẹ pe ẹgbẹ oṣelu Frelimo to ti wa lori oye lati ọdun 1975 lo jawe olubori ninu eto idibo to waye ninu oṣu Kẹwaa.
Rafael ṣalaye pe awọn oluwọde atawọn to n tako ijọba ṣe iwọde lọ si agbebe ti ọgba ẹwọn naa wa, ti iwọde naa si fun awọn ẹlẹwọn lanfani lati bi ogiri ẹwọn naa wo lọna ati salọ.
Lati igba ti wọn ti kede esi ibo to waye loṣu Kẹwaa lawọn eeyan ti bẹrẹ si n fẹhonuhan ni Mozambique latari bi ajọ eleto idibo ṣe kede pe Daniel Chapo lo wọle ibo ọhun.
Ṣaaju ni awọn iroyin kan ti kọkọ fi han pe Deniel Chapo lo ni ida 71% ibo ti awọ araalu di, nigba ti alatako rẹ, Venâncio Mondlane ni ida 20%.
Lẹyin ti ọrọ naa dele ẹjọ ni ile ẹjọ sọ pe ida 65% ni Chapo ni.
Akọroyin BBC to yọju silẹ Mozambique jabọ pe ṣe ni ilu Maputo da paroparo lọjọ aisun ọdun Keresimesi latari bi ọpọ araalu ṣe ti ara wọn mọle nitori rogbodiyan naa.
Awọn araalu ti lọ ja ọpọ ile itaja, ṣọọbu, ile ifowopamọ, agọ ọlọpaa, ti wọn si sọ ina si.
Lati ọjọ Aje ti wahala ọhun ti bẹ silẹ, eeyan mọkanlelogun lo ti padanu ẹmi wọn.















