Kò ṣe é má gbọ̀ ọ́

Àkọlé fọ́nrán ohùn, Àkójọpọ̀ ìròyìn káàkiri Nàìjíríà
Kò ṣe é má gbọ̀ ọ́

Loju mi bayii ni baba ati iya mi atawọn aburo mi mẹta ti jona

Ha! Eyi ma pọju u.

O lagbara o, ọdọbinrin kan Hauwa'u lo ṣalaye fun BBC bi ado oloro lati ara baalu ṣe ṣekupa ẹbi rẹ laisun ọdun Keresimesi

Iṣẹlẹ ọhun to waye labule meji kan nijọba ibilẹ Silame

Ni gomina ipinlẹ Sokoto sọ pe awọn ọmogun Naijiria lo ṣeeṣi yi ado oloro naa

'''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''

Ọmọ Naijiria, ẹ gbami o, ẹ ma jẹ ki wọn pa Naomi!

Naomi ewo n bẹ, ṣe Naomi Olori Ooni Ile Ife tẹlẹ?

Bẹẹ ni, iya rẹ lo ke gbajare pẹlu omije loju wi pe

Kawọn ọmọ Naijiria ran oun lọwọ lori ọrọ Naomi ti ilẹ ẹjọ ju sọgba ẹwọn

Lẹyin iku ọmọde marundinlogoji nibi apejẹ to ṣe agbatẹru rẹ n'Ibadan

Ẹkunrẹrẹ wa loju opo BBC.Com/Yoruba

'''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''

N jẹ o mọ idi ti wọn fi n pe ọjọ keji ọdun Keresimesi ni Boxing Day?

Rara o, abi ọjọ ẹṣẹ kikan ni?

Ko ribẹ o, ọjọ yii ko ni nnkan kan ṣe pẹlu ẹṣẹ kikan, ti ẹ fẹ mọ idi abajọ...