Ọkọ̀ ojú omi tó kó àwọn aṣàtìpó rì ní Morocco, èèyàn 69 jáde láyé

Migrant boat

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

O kere tan, eeyan mọkandinlaadọrin lo ti jade laye ni Morocco lẹyin ti ọkọ oju omi to n ko awọn aṣatipo lati Mali danu laarin agbami okun.

A gbo pe orilẹede Spain lawọn eeyan naa n lọ ki ọkọ oju omi wọn to ri ni Morocco.

Nnkan bii ọgọrin eeyan lo wa ninu ọkọ oju omi ọhun lasiko ti wọn gbera, ṣugbọn eeyan mọkanla pere lo moribọ ninu ijamba naa.

Ninu awọn marundinlọgbọn ọmọ orilẹede Mali to wa ninu ọkọ naa, mẹsan an ninu wọn ni ori ko yọ.

Bo tilẹ jẹ pe ọṣẹ to kọja ni ọkọ naa danu, ana ni ijọba ṣẹṣẹ fidi iroyin ọhun mulẹ.

Atẹjade kan lati ileeṣe to n ri si ọrọ awọn ọmọ Mali nilẹ okere sọ pe awọn adoola ẹmi ti n bojuto iṣẹlẹ naa.

Fun ọpọ ọdun lawọn ẹgbẹ agbesunmọmi fi n kogun ja Mali, eyii to mu ki ologun gbajọba lọdun 2020 ati 2021.

Awọn aditẹgbajọba naa ṣeleri lati ṣeto idibo lọna ati gbe ijọba pada fun awọn oloṣelu, amọ wọn ko tii mu ileri ọhun ṣẹ.

Airiṣẹṣe awọn ọdọ, to fi mọ ebi ọpagba to n kọlu ilẹ naa latari ayipada oju ọjọ tunbọ mu ki nnkan nira siwaju si fun awọn eeyan nibẹ.

Lara awọn ipenija yii lo n mu ki awọn ọmọ orilẹede naa tẹkọ leti lọ ilẹ mii.

Lara wọn lawọn to n gbiyanju lati wọ Spain lati ori alagbalugbu omi okun.

Gẹgẹg bii atẹjade ajọ Caminando Fronteras ni Spain, o ti le ni ẹgbẹrun mẹwaa eeyan to ti jade laye ninu igbiyanju wọn lati rekọja si Spain lati Afrika latari pe wọn n gba ori omi okun kọja.

Ajọ ọhun sọ pe nnkan bii eeyan mẹwaa lo n ku lojumọ ninu igbiyanju wọn.