Wọ́n yìnbọn pa Ìmáàmù àkọ́kọ́ tó fojú hàn bíi olólùfẹ́ akọ-sákọ lágbàáyé

Oríṣun àwòrán, AFP
Awọn eeyan kan ti yinbọn pa Muhsin Hendericks to jẹ Imaamu akọkọ to foju han gẹgẹ bii oni-ibalopọ akọ-sakọ lagbaaye.
Laarọ ọjọ Abamẹta ọjọ kẹẹdogun oṣu Keji yii ni wọn pa Hendricks lẹyin tawọn eeyan kan da ọkọ ti o n rinrin ajo ninu rẹ lọna lẹgbẹ ilu Gqeberha lorilẹede South Africa.
Hendricks ẹni ọdun mẹtadinlọgọta ni mọṣalaaṣi kan niluu Cape Town nibi tawọn musulumi ololufẹ akọ-sakọ ti n maa n kirun.
Ileeṣẹ ọlọpaa ṣalaye pe awọn afurasi meji kan ti wọn fi aṣọ boju lo ṣadeede jade ninu ọkọ kan ti wọn si bẹrẹ si ni yinbọn mọ ọkọ ti Henricks wa ninu rẹ.
Iroyin iku Hendricks ti tan kaakiri papaa julọ laarin awujọ awọn eeyan ti wọn jẹ akọ-sakọ ati abo sabo.
Ọga agba ẹgbẹ awọn akọ-sakọ, abo sabo, awọn ọkunrin to n ṣe bii obinrin atawọn obinrin to ti di ọkunrin, Julia Ehrt, ti rọ awọn alaṣẹ ijọba South Africa lati ṣe iwadii finifini lori iṣẹlẹ iku Henricks.
Hendricks ṣe iranwọ fun ọpọlọpọ eeyan lorilẹede South Africa ati kaakiri agbaye nigba aye rẹ.
Ohun ti a gbọ ni pe wọn yinbọn pa Hendricks lẹyin to lọ ṣe alaga iduro nibi ayẹyẹ igbeyawo abo sabo kan, amọ, iwadii si n lọ lori ọrọ yii tori a ko tii le fidi rẹ mulẹ bayii.
Ṣugbọn fọnran ti kamẹra CCTV ka silẹ eyi to wa lori itakun ayelujara lo ṣafihan bi ikọlu naa sẹ waye.
Ẹrọ kamẹra naa ṣafihan bi ọkọ kan ṣe duro siwaji ọkọ ti Imaamu Hendricks wa ninu rẹ.
Aga to wa lẹyin ni Henricks jokoo si gẹgẹ bi nnkan ti ileeṣẹ ọlọpaa sọ.
Kamẹra CCTV tun ṣe afihan bi ẹnikan ṣe bẹ jade lati inu ọkọ kan ti o si sare lọ sibi ti ọkọ ti Henricks wa ninu rẹ wa, lẹyin naa ni o bẹrẹ si ni yinbọn soju ferese ilẹkun ọkọ naa to wa lẹyin.
Ọdun 1996 ni Hendricks kede faye wi pe ololufẹ akọ-sakọ loun
Ajọ Al-Ghurbaah to jẹ ti Hendricks eyi to n ṣagbatẹru mọṣalaaṣi Masjidul Ghurbaah ni agbegbe Wynberg niluu Cape Town sọ pe awọn eeyan kan lo wa ni idi ikọlu ti wọn fi ṣeku pa Hendricks.
Alaga ajọ naa, Abdulmugheeth Petersen, rọ awọn ọmọ ẹgbẹ naa pe ki wọn fara balẹ lasiko yii tori o ṣe pataki lati daabo bo ẹbi Hendricks.
Hendricks ṣiṣẹ takun takun lati ri pe ẹsin musulumi wa fun gbogbo eeyan to fi mọ awọn ololufẹ akọ-sakọ ati abo-sabo.
Lati ọdun 2006 gan an ni orilẹede South Africa ti faye gba ki ọkunrin fẹ ọkunrin ati ki obinrin fẹ obinrin ẹgbẹ rẹ.
South Africa si ni orilẹede akọkọ nilẹ Afirika ti yoo faye gba igbeyawo akọ-sakọ ati abo-sabo.
Lọdun 1996 ni Hendricks kede faye wi pe ololufẹ akọ-sakọ loun, eyi si jẹ nnkan iyalẹnu fawọn musulunmi niluu Cape Town ati lawọn ibomiran.
Ọdun 1996 yii kan naa ni Kendricks da ajọ kan silẹ lati maa daabo bo awọn musulumi ti wọn jẹ ololofẹ akọ-sakọ ati abo-sabo.
Lẹyin naa ni o si da mọṣalaaṣi Masjidul Ghurbaah silẹ nibi tawọn ololufẹ akọsakọ ati abo-sabo ti n kirun.
Ẹwẹ, Alufaa Jide Macauly, toun naa jẹ ololufẹ akọ-sakọ ti ṣapejuwe iku Hendricks gẹgẹ bi nnkan to bani ninu jẹ.
Sadiq Lawal toun naa jẹ ololufẹ akọ-sakọ ni Naijiria sọ fun BBC pe Hendricks ti ni ipa nla lori ọpọ eeyan nipa ẹsun islam.















