Kà nípa àìsàn ọgbẹ́-inú àti ohun tó ń fà á

Aworan ẹni to fi ọwọ di inu mu

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Nigbakigba ti inu ba n da eeyan laamu, tabi ti inira kan ba n ṣẹlẹ ni inu eeyan, ọpọ eeyan lo maa n ro pe aisan ọgbẹ inu ti oyinbo n pe ni 'Ulcer' ni.

Awọn onimọ nipa ilera ti fidi ẹ mulẹ, pe eyi ki i fi gbogbo igba ri bẹẹ.

Ṣugbọn aisan ọgbẹ-inu ti n daamu awọn eeyan mi-in fun igba pipẹ, to bẹẹ to maa n fa iku nipasẹ ẹjẹ ti yoo maa danu lara ẹni to kọlu.

Ohun ti ọpọ eeyan maa n ro pe o n fa ọgbẹ-inu ni ai ri ounjẹ jẹ, tabi aijẹun lasiko, awọn dokita si tun tako ero yii, wọn ni ko ri bẹẹ rara.

Bakan naa lo jẹ pe bi ẹnikan ba ni ọgbẹ-inu n yọ oun lẹnu, awọn to ba wa nibẹ yoo ni ko sare mu miliiki, ki ara le ba a tu u.

Eyi ti mu ki ọpọ eeyan nigbagbọ pe wara mimu jẹ ilana itọju ọgbẹ-inu, lai tẹle alaye dokita kankan.

Kí ni ọgbẹ́-inú?

Lati tan imọlẹ si awọn igbagbọ ti ko ri bẹẹ, ṣugbọn ti awọn eeyan ni nipa aisan ọgbẹ-inu, BBC kan si Dokita Yusuf Musa, onimọ nipa aisan inu, lati ileewe ẹkọṣẹ iṣegun oyinbo ni Katsina.

Dokita Yusuf ṣalaye pe inu nikan kọ ni ọgbẹ n wa. O ni ọgbẹ le wa ninu ifun, o si le wa lẹnu eeyan pẹlu.

O ni ṣugbọn awọn nnkankan wa to maa n fa ki eeyan maa ni iṣoro ọgbẹ inu.

" Ọgbẹ tumọ si nigba ti ibi kan ba là, tabi ni iho ninu, o le jẹ ikun eeyan, o le jẹ ifun nla tabi kekere, yoo si maa dun eeyan."

Bẹẹ ni Dokita Yusuf ṣalaye.

O fi kun un pe bi ọgbe ita ṣe n san ti ko ni i dun eeyan mọ, bẹẹ ni ọgbẹ inu paapaa le san, afi bi eeyan ko ba ṣe ohun to yẹ lo ku.

Kí ló ń fa ọgbẹ́-inú?

Aworan inu

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Gẹgẹ bi Dokita Yusuf ṣe ṣalaye, awọn idi kan wa ti iwadii ti fi han pe wọn n fa ọgbẹ-inu ati ki ikun maa dun eeyan.

Lara awọn nnkan naa ni:

*Helicobacter pylori:Eyi jẹ kokoro bacteria kan to maa n jà, paapaa ni awọn ilu kereje.

* Lilo oogun ara riro: Dokita Yusuf sọ pe ọpọ oogun ara riro to le fa ọgbẹ-inu lo wa lode.

*Lilo awọn oogun ibilẹ: O ni idi ni pe ọpọ igba ni a ki i mọ ohun ti wọn po pọ fi ṣe awọn oogun yii.

Dokita ni pupọ ninu ohun tawọn eeyan n ro pe o n fa ọgbẹ-inu ko tiẹ ni nnkan kan lati ṣe pẹlu aisan naa, nitori ko si afijọ kankan to wa pẹlu ulcer ninu awọn nnkan naa.

" O o le mọ boya o ni ọgbẹ-inu tabi o ko ni, afi ti o ba lọ sileewosan.

Ọpọ eeyan yoo ṣaa maa sọ pe awọn ni 'ulcer', bẹẹ ki i ṣe ọgbẹ-inu lo n yọ wọn lẹnu."

Dokita Yusuf Musa lo ṣalaye bẹẹ.

Ṣé lóòótọ́ ni pé mílíìkì mímu lè wo ọgbẹ́-inu sàn?

Lati ayebaye ni igbagbọ yii ti wa, pe bi inu ba n da eeyan laamu tabi to n da bii pe eeyan fẹẹ bì, pe miliiki lo yẹ ko mu ti alaafia yoo fi de.

Ṣugbọn Dokita Yusuf ṣalaye pe:

"To ba jẹ ti ọgbẹ-inu la n sọ, awọn irọ kan rọ mọ ọn, ọkan lara awọn irọ naa ni ti miliiki mimu si ulcer yii."

O ni miliiki ki i ṣe oogun ọgbẹ-inu.

"Awọn iṣoro inu mi-in wa ti ki i ṣe ọgbẹ-inu rara.

"Lara awọn ohun ti a si maa n sọ pe kawọn eeyan ti inu ba n yọ lẹnu, dinku ni miliiki ati mimu ẹlẹridodo.

"Emi mọ pe miliiki ki i ṣe oogun ọgbẹ-inu. Igbagbọ to rọ mọ ọkan eeyan lasan ni.

"O da bii ki ẹ fun eeyan lomi mu fun ohun to n ṣe e, ara yoo tu u pe o mu omi, ṣugbọn omi yẹn kọ ni iwosan ohun to n ṣe e gan-an."

Kí ló yẹ kó o ṣe bí inú bá ń yọ ọ́ lẹ́nu?

Nipa ohun to yẹ ki eeyan ṣe bi inu ba n daamu rẹ, Dokita Yusuf sọ pe ileewosan ni ki onitọhun gba lọ.

O gba awọn eeyan nimọran lati lọ sọdọ dokita to kọṣẹ nipa itọju inu nikan, alaafia yoo si de gẹgẹ bo ṣe wi.

O ni oniruuru ni aisan inu, nigba ti eeyan ba de ileewosan, wọn yoo ṣe ayẹwo ohun to n ṣe e, wọn yoo si fun ni itọju to yẹ.