Baálẹ̀ Esu ìlú Osogbo Kayode Esuleke wọ káà ilẹ̀ sùn

Aworan Baalẹ Kayode Esuleke
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Baalẹ Eṣu ti iluu Osogbo Oloogbe Kayode Eṣuleke ti wọ kaa ilẹ nilana isẹse lonii ọjọ Kẹẹdogun osu Kejì ọdun 2025.

Kayode Eṣuleke dagbere faye ni ọjọ Karunlelogun osu kinni ọdun yii, oloogbe naa lo ọdun marundinlaadọrun-un loke eepẹ.

Wọn sin Oloogbe Eṣuleke si agboile Olugun to wa ni agbegbe Ọja Ọba niluu Osogbo.

Nigba to sabewo ibanikẹdun si awọn mọlẹbi Oloogbe Kayode Eṣuleke, Gboyega Oyetola, to jẹ gomina fun ipinlẹ Osun tẹlẹ to tun jẹ Minisita fun ọrọ okowo oju omi lọwọ lọwọ sọ wí pe ọkan pataki ati opo ni oloogbe Eṣuleke jẹ ninu ẹgbẹ oselu APC nipinlẹ Ọsun.

Minisita Oyetola, tun fi kun wi pe, Oloogbe Kayode Eṣuleke jẹ ọkan pataki laaarin awọn ẹgbẹ onisẹse ati ilu Osogbo lapapọ.

O ni iru eeyan bi Oloogbe Kayode Eṣuleke sọwọn lawujọ onisẹse ati lawujọ oloselu tori o jẹ olotitọ ati oniwa irẹlẹ.

Ifakayode Ifaniyi to jẹ agbọngbọn awo ti ilu Osogbo naa sọ pe Oloogbe Kayode Eṣuleke jẹ ẹni to mọ Ifa to si tun mọ nipa Eṣu ati awọn ikan to rọ mọ ọ.

O ni Oloogbe Kayode Eṣuleke Baalẹ Eṣu jẹ ongbotarigi ninu onisẹse niluu Osogbo ati kakiri agbaye.

Ifaniyi tun sọ wi pe, awọn ẹlẹsin ibilẹ ti padanu ongbotarigi onisẹse, olooṣa ati Ọmọwe ninu ajọ onisẹse nipinlẹ Ọsun ati lorile-ede Naijiria.

Ifaniyi wa rọ awọn ọmọ Oloogbe Kayode Eṣuleke, lati moju to orisa ti baba wọn fi silẹ daadaa ko mọ baa parun.

Iku Baba mi Kayode Eṣuleke da bi idan loju mi - Ifasola Eṣuleke

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Babatunde Eṣuleke to jẹ ọkan lara ọmọ Oloogbe sọ fun BBC Yoruba pe ''nigba ti Baba mi Kayode Eṣuleke ku ni mo to gba pe iku maa n pa eeyan.''

Babatunde salaye wi pe oun ko mọ wi pe iku le pa baba oun rara.

''Igba ti wọn iransẹ pe mi wi pe baba mi ti ku, iyalẹnu lo jẹ fun mi pe iku le pa Kayode Eṣuleke alaanu gbogbo eeyan.

Baba mi jẹ ọkan gboogi ninu awọn onisẹse, bakan naa lo jẹ Baalẹ Eṣu ti iluu Osogbo ti gbogbo eeyan mọ kakiri.

Ifasola Eṣuleke ni tiẹ sọ pe iku baba oun da bi idan loju oun.

Ifasola to tun jẹ olori Eleegun Eṣu niluu Osogbo ṣalaye fun BBC Yoruba wi pe oun ko ni fi orisa baba oun silẹ rara.

Oni ki oloogbe Kayode Eṣuleke to ku ni oun naa ti n ṣe iṣẹ babalawo ti oun si jẹ oye Elegun Eṣu fun iluu Osogbo.

O ni baba awọn ti kọ gbogbo ọmọ rẹ ni isẹ isegun ati bi wọn n ṣe bọ Eṣu.

Ifasola ni gbogbo awọn ọmọ ti oloogbe Kayode Eṣuleke bi ni wọn mọ nipa isẹ awo ati bi wọn ṣe le bọ Eṣu.

Lara awọn to peju pesẹ si bi eto isinku oloogbe Baalẹ Eṣu ilu Osogbo la ti ri awọn ẹgbẹ Ogboni agba, ẹgbẹ iya Osun ati awọn alawo.