Èrò méjìdínlógún tẹ ara wọn pa ní ibùdókọ̀ rélùwéè

Nibi ti awọn ero to fẹẹ wọ ọkọ oju irin reluwee ti n ti ara wọn lalẹ ọjọ Satide, ọjọ kẹẹẹdogun, oṣu Keji ọdun 2025 yii ni wọn ti tẹ ara wọn pa ni New Delhi, olu ilu India.
Yatọ si awọn to di oloogbe, o kere tan, eeyan mẹwaa mi-in tun fi ara pa nibi irọgiri naa.
Ọmọde mẹrin ati awọn obinrin mẹwaa, wa lara awọn to ba iṣẹlẹ naa lọ, gẹgẹ bi atẹjade awọn alaṣẹ ibẹ ṣe sọ.
Ohun ti a gbọ ni pe ọkọ oju irin pẹẹ de lalẹ ọjọ naa, awọn ero si ti n duro de e tipẹ.
Bi ọkọ naa ṣe de ni wọn bẹrẹ si i du u lati wọ, nibẹ si ni eleeru ti bẹrẹ si i sungi, ti oku n sun.
Olootu ijọba India, Narendra Modi, ti ba awọn tọrọ kan kẹdun, o ki wọn si oju opo X rẹ.
Titẹ ara ẹni pa wọpọ n'India, nibi ti wọn ti maa n pọ kọja aaye lode ẹ̀sìn, ayẹyẹ ọdun ati igboro.
Eyi to ṣẹṣẹ ṣẹlẹ yii n waye lẹyin ọsẹ meloo kan ti ọgbọn eeyan (30), ri sodo nibi ti wọn ti n wẹ iwẹ ọdun Kumbh Mela, ni Ariwa India.
Awọn ti iṣẹlẹ ọkọ oju irin yii ṣoju wọn, sọ fun BBC Hindi pe awọn ero naa n bọ lati ibi odo Kumbh Mela ni, bẹẹ ni awọn mi-in ṣẹṣẹ n lọ.
Awọn alaṣẹ sọ pe ọkọ oju irin meji lo pẹẹ de, nigba ti eyi to fẹẹ lọ si n mura lati gbera
Ọkunrin kan, Umesh Giri,ti iyawo rẹ ku sinu iṣẹlẹ yii, ṣalaye pe ero ti pọ ju ohun ti apa ka lọ
" Loju mi bayii ni wọn ti gbe awọn obinrin mẹfa si meje kọja lorii ibusun alagbeka"
Igbakeji ọlọpaa to n ri si ọrọ ọkọ oju irin, KPS Malhotra, ṣalaye pe iwadii ti bẹrẹ lori iṣẹlẹ naa.















