Ohun tó yẹ kí ìjọba Adeleke àti APC ṣe lórí ìdájọ́ ilé ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn tó ń fa awuyewuye ní Osun rèé - Yomi Aliyu, SAN

Ademola Adeleke àti Gboyega Oyetola

Oríṣun àwòrán, Ademola Adeleke/Gboyega Oyetola/Facebook

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 6

Láti ọ̀sẹ̀ tó kọjá ni ìfaǹfà ti ń wáyé láàárín ìjọba ìpínlẹ̀ Osun àti ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress, APC lórí ìdájọ́ ilé ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn lórí ọ̀rọ̀ àwọn alága ìjọba ìbílẹ̀ tí ilé ẹjọ́ gíga yọ nípò lọ́dún 2020.

Láti ìgbà tí adájọ́ ti gbé ìdájọ́ kalẹ̀ ni ẹgbẹ́ òṣèlú APC ti ń fò fáyọ̀ pé àwọn ti gba ipò àwọn padà àti pé àwọn ti ṣetán láti lọ gba ipò àwọn láwọn ìjọba ìbílẹ̀ padà.

Ọ̀kan lára àwọn alága náà, Abiodun Idowu tó bá BBC News Yorùbá sọ̀rọ̀ ní àwọn ti ṣetán láti padà sí ọ́fíìsì, pé ilé ẹjọ́ ti dá àwọn láre.

Ó ní àwọn kò ní fi ààyè gba ètò ìdìbò sípà alága ìjọba ìbílẹ̀ àti káńsílọ̀ gẹ́gẹ́ bí ìjọba ìpínlẹ̀ Osun ṣe ti ń gbèrò.

Àmọ́, ìjọba ìpínlẹ̀ Osun lábẹ́ ìdarí gómìnà Ademola Adeleke ní ìdájọ́ ilé ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn náà kò sọ wí pé kí àwọn alága tí wọ́n yọ nípò náà padà sí ipò tí wọ́n wà tẹ́lẹ̀.

Gómìnà Adeleke nígbà tó ń bá àwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀ lọ́jọ́ Àìkú sọ pé ìdájọ́ ilé ẹjọ́ náà kò sọ pé kí àwọn alága náà padà sí ipò gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe ń gbe kiri.

Ó ní lóòótọ́ ni pé APC bèèrè lọ́wọ́ ilé ẹjọ́ pé kí wọ́n fi ààyè gba àwọn alága náà láti padà sípò wọn àmọ́ ilé ẹjọ́ kò sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀.

Èyí ti wá ń fa awuyewuye láti igun méjéèjì tó jẹ́ pé èàyàn kò mọ èyí tó jẹ́ òótọ́ nínú rẹ̀.

BBC News Yorùbá wá kàn sí àgbà amòfin nnì, Yomi Aliyu láti bá wa tan ìmọ́lẹ́ sí ìdájọ́ náà.

Ó yẹ kí APC àti ìjọba ìpínlẹ̀ Osun padà sílé ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn fún àgbọ́yé ìdájọ́

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Gẹ́gẹ́ bí Yomi Aliyu ṣe sọ, ó ní àgbọ́yé ìdájọ́ ilé ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn ló ń da ẹgbẹ́ òṣèlú APC àti ìjọba ìpínlẹ̀ Osun láàmú ló fa gbogbo awuyewuye tó ń wáyé lórí ìdájọ́ náà.

Ó ní ó yẹ kí agbẹjọ́rò àgbà ìpínlẹ̀ Osun àti APC ti gba ilé ẹjọ́ lọ, láti ìgbà tí ìdájọ́ náà ti ń fa awuyewuye, láti bèèrè fún ohun tí ìdájọ́ náà túmọ̀ sí gan-an.

Aliyu ní gẹ́gẹ́ bí òfin Nàìjíríà, ìdájọ́ tó bá dé kẹ́yìn ni olúborí àti pé tí ìdàjọ́ kò bá èèyàn, òfin fi ààyè gba àwọn tí wọ́n dájọ́ fún láti lọ bèèrè àgbọ́yé lórí ìdájọ́ náà.

"PDP àti APP ló gbọ́dọ̀ lọ sí ilé ẹjọ́ láti bèèrè pé níbò ni wọ́n dúró, ṣé ẹ ti da ẹjọ́ nù ni, èwo lẹ fẹ́ ka mú níbẹ̀?

"òfin kò fààyè fún èèyàn láti ṣe èyí jẹ èyí ò jẹ lórí ìdájọ́, ohun tí ìjọba PDP ìpínlẹ̀ sun le ṣe ni pé kí wọ́n lọ sílé ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn láti bèèrè fún ìtumọ̀ ìdájọ́ náà ní kíákíá."

Ó wòye pé ó yẹ kí PDP lọ sí ilé ẹjọ́ láti bèèrè fún àláyé lórí ìdájọ́ náà kí wọ́n tó ṣètò ìdibò sípò alága àtàwọn káńsílọ̀ tí wọ́n ń gbèrò.

Ó ní òfin ti fààyè sílẹ̀ pé ilé ẹjọ́ gbọdọ̀ gbọ́ ẹjọ́ tó bá ti jọ mọ́ ọ̀rọ̀ òṣèlú ní kíákíá àti pé ìtumọ̀ náà kò ní gbà wọ́n ní ọjọ́ méjì láti gbọ́ àgbọ́yé ìdájọ́ náà.

Ó fi kun pé àti ẹgbẹ́ òṣèlú APC àti PDP ló rí nǹkan dì mú lórí ìdájọ́ náà àmọ́ ìdájọ́ tó bá ti wá kẹ́yìn ni olúborí lábẹ́ òfin.

Àgbà amòfin náà àti ẹgbẹ́ APC àti PDP ni wọ́n wà lórí afẹ́fẹ́, tí wọ́n sì nílò àgbọ́yé tó yẹ lórí ìdájọ́ náà tí wọn kò bá fẹ́ kí ọ̀rọ̀ àwọn dàbí ó délé kò délé, ó dóko kò dóko, ó ti oko ìrókó dóko ìrókòto.

Kí ló ń fa ìfàǹfà láàrin Gómìnà Adeleke àti Oyetola lórí ọ̀rọ̀ àwọn alága àti kánsílọ̀ ìjọba ìbílẹ̀ l'Osun?

Aworan Ademola Adeleke ati Gboyega Oyetola

Oríṣun àwòrán, Senator Ademola Adeleke/Adegboyega Oyetola/X

Gomina Ademola Adeleke ipinlẹ Osun ti fẹsun kan Minisita ohun alumọni inu omi, Gboyega Oyetola, wi pe o n gbimọ pọ pẹlu awọn agbofinro lati dawọn alaga ati kansilọ ijọba ibilẹ ti wọn dibo yan lasiko ijọba ẹgbẹ oṣelu APC pada, lẹyin ti ileẹjọ ti fagile eto idibo to gbe wọn wọle.

Gomina Adeleke to sọrọ yii lasiko to n bawọn akọroyin sọrọ lọsan ọjọ Aiku ọjọ kẹtadinlogun oṣu Keji yii sọ pe Oyetola n gbero lati da rogbodiyan silẹ nipinlẹ Osun pẹlu igbesẹ rẹ.

Sẹnẹtọ Adekeke sọ ninu ọrọ rẹ pe Oyetola to jẹ gomina ipinlẹ Osun tẹlẹri fẹ lo ipo rẹ gẹgẹ bii ibatan Aarẹ Bola Tinubu lati da wahala silẹ nipinlẹ Osun.

Nigba to n bawọn akọroyin sọrọ, Sẹnẹtọ Adeleke ni ''mo n fi anfaani yii sọ fun gbogbo eeyan kaakiri agbaye nipa awọn eeyan kan ti wọn n gbero lati da omi alaafia ipinlẹ Osun ru.

Mo pe ẹyin akọroyin lati sọ fun yin nipa awọn eeyan ti ko gbagbọ ninu ijọ awarawa ti wọn fẹ ki idajọ ileẹjọ ti ko si mọ di mimuṣẹ.

Iyanlẹnu lo jẹ wi pe awọn eeyan yii fẹ gbe awọn alaga atawọn kansilọ ti ileẹjọ ti wọgile eto idibo wọn pada pẹlu idajọ ileẹjọ mii ti ko lẹṣẹ nlẹ.

Mo fẹ sọ fun gbogbo eeyan wi pe ileẹjọ ti yọ awọn alaga atawọn kansilọ yii nipo ki n to di gomina rara.

Eyi tako irọ tawọn eeyan kan n gbe kiri pe emi ni mo paṣẹ iyọnipo wọn.''

Adeleke ni oun mọ pe Aarẹ Tinubu ko ni fọwọ si igbesẹ kigbẹsẹ to ba tako iwe ofin Naijiria eyi to si tun le da omi alaafia ipinlẹ Osun ru.

Gomina Adeleke wa kepe ijọba apapọ, ẹka eto idajọ ati gbogbo eeyan tọrọ kan lati dasi ọrọ naa.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post

Ẹgbẹ oṣelu APC fesi sọrọ Adeleke

Ẹwẹ, ẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ Osun ti fesi sọrọ ti Gomina Adeleke sọ nibi to ti bawọn akọroyin sọrọ.

Agbẹnusọ ẹgbẹ oiṣelu APC, Kola Olabisi, sọ pe gbogbo ẹsun ti Adeleke ka si Oyetola ati ẹgbẹ oṣelu APC lọrun ko lẹsẹ nlẹ.

O ni ọna lati doju idajọ ileẹjọ bolẹ ni gbogbo nnkan ti gomina ipinlẹ Osun n gbiyanju lati ṣe.

Ẹgbẹ oṣelu APC wa rọ Adeleke lati morile ileẹjọ to ga julọ ni Naijiria, ti idajọ ile ẹjọ kotẹmilọrun ko ba tẹ ẹ lọrun.

Ọgbẹni Olabisi fikun ọrọ rẹ pe irọ to jina si ootọ ni ọrọ ti Adeleke sọ pe Oyetola n gbimọ pọ pẹlu awọn agbofinro lati da ipinlẹ Osun ru.

Agbẹnusọ APC ni gomina ipinlẹ Osun sọ eyi lati ba Oyetola lorukọ jẹ ni.

O ni Oyetola ko bawọn agbofinro sọrọ kankan lori ọna lati ṣiṣẹ wọn.

Ọgbẹni Olabisi sọ pe o ṣe pataki fun Gomina Adeleke lati mọ pe gbogbo ọrọ to n sọ ko le yi idajọ ileẹjọ pada.

O ni lọna aitọ ni wọn fi yọ awọn alaga atawọn kansilọ APC kuro nipo lọdun 2022, ṣugbọn ile ẹjọ ti dawọn pada bayii.

''Ileẹjọ ti dajọ, Oyetola gẹgẹ bii olori ẹgbẹ APC nipinlẹ Osun si gbọdọ ri wi pe igbẹjọ naa wa si imuṣẹ,'' Ọgbẹni Olabisi lo sọ bẹẹ.

Agbẹnusọ ẹgbẹ oṣelu APC ni ijọba to wa lode npinlẹ Osun gbọdọ bọwọ fun idajọ ile ẹjọ.