Ìjọba kéde ìgbà tí ìsọ̀rí àkọ́kọ́ ọmọ Nàìjíríà tí ìjọba Trump lé kúrò l'Ámẹ́ríkà yóò dé

Awọn ọmọ Naijiria

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ijọba apapọ ti kede igba ti isọri akọkọ awọn ọmọ Naijiria ti ijọba Aarẹ Donald Trump le kuro lorilẹede Amẹrika yoo de si Naijiria.

Minisita keji fun ọrọ okeere, Bianca Odumegwu Ojukwu, fi idi rẹ mulẹ loju opo Facebook rẹ pe lonii ọjọ Aje ọjọ kẹtadinlogun ni isọri akọkọ awọn ọmọ Naijiria ti ijọba Amẹrika ti le kuro yoo balẹ si Naijiria.

Arabinrin Ojukwu ṣalaye pe oun sọ fun aṣoju ijọba orilẹede Amẹrika si Naijiria, Richard Mills Jr, lasiko toun ṣe ipade pẹlu rẹ pe ijọba Naijiria n kọminu lori igbesẹ Aarẹ Donald Trump lati da awọn ọmọ Naijiria kan pada wa sile.

''Bi a ṣe n sọrọ lọwọ yii, 201 ọmọ Naijiria lo ti wa ni ahamọ ajọ to n ri si wiwọle si orilẹede Amẹrika.

Marundinlaadọrun ninu wọn lo ti gba itusilẹ lati pada wale lati orilẹede Amẹrika bayii.

Mo sọ fun aṣoju ijọba Amẹrika ni Naijiria pe o yẹ ki ijọba Amẹrika ṣe pẹlẹ papaa julọ pẹlu awọn ọmọ Naijiria ti wọn ko ni akọsilẹ iwa ọdaran.

Mo ni o yẹ ki ijọba fun wọn ni akoko to to lati ṣeto bi wọn ṣe fẹ ṣe dukia wọn, ko boju mu bi ijọba sẹ n ko wọn sinu baalu wi pe ki wọn pada si ibi ti wọn ti wa,'' Ojukwu lo sọ bẹẹ.

Minisita keji fun ọrọ ilẹ okeere loun sọ fun aṣoju ijọba ni Naijiria wi pe lile ọmọ Naijiria kuro l'Amẹrika gbọdọ wa ni ibamu pẹlu ofin to de awọn orilẹede agbaye.

O ni Ọgbẹni Mills fi da oun loju pe ijọba Amẹrika ko ni tabuku awọn ọmọ Naijiria ti ijọba Trump ti le kuro lorilẹede naa.

Gẹgẹ bii akọsilẹ kan ti ileeṣẹ tẹlifisan Fox ṣafihan rẹ, o le ni ẹgbẹrun mẹta ọmọ Naijiria to wa lorilẹede Amẹrika ti wọn ko ni iwe igbeluu.

Iroyin kan tun fidi rẹ mulẹ pe Naijiria ni orilẹede keji to lawọn eeyan ti Trump fẹ le kuro l'Amẹrika julọ l'Afirika eyi ti Somalia, Ghana, Senegal atawọn orilẹede mii tẹle.