Kò ṣe é má gbọ̀ ọ́
Afaimọ kọrọ APC ati ijọba Osun ma di o dele ko dele, o doko ko doko, o toko iroko doko irokoto
Ah ah! iru ọrọ wo niyẹn?
Amofin Yomi Aliyu, SAN lo maa sọ bẹẹ lori ifanfa to n waye lori idajọ ile ẹjọ Kọtẹmilọrun
Agba amofin naa ni agbọye idajọ naa ni ko si fun ijọba Osun ati APC
O ni o yẹ ki wọn ti pada sile ẹjọ Kotẹmilọrun
Fun ki tun ni yẹn o?
xxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxx
Idajọ ododo la n fẹ lori iku ọmọ wa
Awọn obi Hafsat Yetunde Lawal ti wọn ni Alfa kan Abdulrahman Bello ṣekupa niluu Ilorin lo n beere bẹẹ
Iya Yetunde ni inu ibanujẹ ni awọn wa lati igba ti iṣẹlẹ naa ti waye
Ati pe ohun to le tu awọn ninu ni kawọn ri idajọ ododo lori iku ọmọ awọn
xxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxx
Niṣe lọrọ di bo o lọ o yago lagọ ọlọpaa ilu Ifon, ipinlẹ Ondo
Nigba tawọn ọdọ kan dana sun agọ ọlọpaa naa lopin ọsẹ lori iku Tobi Bobade
Wọn fẹsun kan pe awọn ọlọpaa lo lu Tobi ti ẹmi rẹ fi bọ
Amọ ileeṣẹ ọlọpaa ní bẹẹ kọ lọrọ ri














