Orí kó àwọn ìlúmọ̀ọ́ká mẹ́wàá yọ nínú ìjàmbá bàlúù tó wáyé ní Ibadan

Oríṣun àwòrán, Lere Olayinka/Facebook
Baluu aladani kan pẹlu awọn eekan ilu bii mẹwaa ninu ti yọ kuro loju opo ibalẹsi awọn baluu ni papakọ ofurifu Ladoke Akintọla to wa nilu Ibadan tii ṣe olu ilu ipinlẹ Ọyọ, lẹkun iwọ oorun gusu orilẹede Naijiria.
Ohun ti a gbọ ni pe nnkan bii agogo mọkanla owurọ ọjọ Ẹti ni iṣẹlẹ naa waye.
Baluu naa, ti nọmba idanimọ rẹ jẹ N580KR, yọ gẹrẹ kuro loju ọna wọ inu igbo lọ.
Awọn panapana at’awọn oṣiṣẹ adoola ẹmi tete ya bo ibẹ amọ ko si ẹnikẹni to ku tabi fi ara pa.
A gbọ wi pe agbẹnusọ ajọ amojuto papakọ ofurifu ni Naijiria, FAAN, Carol Adekotujọ ṣalaye fun awọn akoroyin kan pe lootọ ni iṣẹlẹ naa waye ati wi pe, “ilu Abuja ni baluu aladani naa ti n bọ. o balẹ nirọwọrọsẹ ki o to yọ kuro loju opo ibalẹsi awọn baluu. Ko si ẹnikẹni to ku nibẹ.”
Gbọnmọgbọnmọ iṣẹlẹ ijamba ọkọ baluu lẹnu lọwọlọwọ yii ti n kọ ọpọ lominu. Bi ẹ ko ba gbagbe, laipẹ yii ni irufẹ iṣẹlẹ yii pẹlu ṣẹlẹ si baluu kan to gbe minisita fun ohun amuṣagbara, Adebayọ Adelabu ni oṣu kọkanla ọ











