'Ọmọ̀ mi ni Ọlọ́run rán láti jẹ́ kí ìyá ẹ̀ wà l'áyé di òní'

Lẹyin ọsẹ kan ti ibugbamu nla waye ni agbegbe Bodija niluu Ibadan, awọn onile ati olugbe agbegbe naa ṣi n ka awọn nnkan ti wọn padanu.
Nibi ipade kan ti awọn onile ati awọn eeyan ti o fi ara gba nibi ibugbamu naa ṣe l’Ọjọru, ni diẹ lara awọn to padanu dukia ti ba BBC sọrọ.
Ọkan lara awọn to padanu dukia wọn nibi iṣẹlẹ naa, Arakunrin Taiwo Salami ṣe alaye fun akọroyin wa wi pe igboro ni oun wa, ki ọkan lara awọn oṣiṣẹ to n ba oun ṣiṣẹ nile itaja kan to dede pe ago oun wi awọn gbọ ariwo ibugbamu kan to dun lojiji, o si ti ba gbogbo gilaasi ileeṣẹ naa jẹ.
Eyii ni Salami n ro lọwọ, ki o to gba ipe pajawiri mii lati ọdọ iyawo rẹ. Ni adugbo Dẹjọ Oyelẹsẹ, nibi ti ibugbamu yẹn ti waye gan an ni ile wọn wa.
Ipe ijaya ti o gba lati ọwọ aya rẹ lo fi idi ọrọ mulẹ wi pe wahala ti ṣẹlẹ.
O ni, "Ile ikẹta si ibi ti iṣẹlẹ yii ti ṣẹlẹ ni a n gbe. Lọjọ ti a n sọ yii, mi o si nile ṣugbọn iyawo mi wa nile ati ọmọ mi obinrin.
Ọlọrun ti o ni ki ọmọ mi wa nile gan an lo jẹ ki iyawo mi ṣi wa laaye, nitori ọmọ wa ni Ọlọrun lo lasiko iṣẹlẹ pajawiri naa.
Igba ti iṣẹlẹ yii ṣẹlẹ, ṣe ni iya rẹ ṣubu, ti o si fi ara pa. Ọmọ yẹn lo wọ ọ jade ninu ile naa, ti o si gbe e lọ si ibi ti o ti ri itọju."
Botilẹ jẹ wi pe iyawo Ọgbẹni Salami tete ri itọju gba, ile wọn ko ṣe e pada si mọ bayii, nitori nnkan ti bajẹ kọja ala.
O ṣe alaye fun BBC Yoruba pe ọdọ arakunrin oun kan ni awọn n gbe bayii, bẹẹ si ni ojoojumọ ni awọn n ra aṣo tuntun ati awọn oogun ti awọn n lo nitori gbogbo ẹru to wa ninu ile to wo ti bajẹ.
Panapana ni mo n pe lọwọ, ni ibugbamu to o gba foonu danu mọ mi l’eti

Ẹlomii ti iṣẹlẹ naa kan, Arabinrin Arinọla Adegoke Ọlanipẹkun ṣe alaye fun akọroyin wa wi pe lọjọ ti iṣẹlẹ naa waye, ipe kan lo kọkọ wọle si ori foonu oun lati ọdọ ọkan lara awọn ara adugbo naa to fi igbe bọ ẹnu wi pe ina n jo ni ile kan l'adugbo.
Igbiyanju lati pe awọn panapana lo n ṣe lọwọ ki ibugbamu naa to dun, ti o si gba foonu sọnu lọwọ rẹ.
Ọlanipẹkun ni, "lọjọ to ṣẹlẹ, inu ile ni mo wa. Ẹni kan pe mi wi pe ṣe mo le ba wọn pe panapana wi pe ile kan n jo.
Mo mu foonu pe ki n pe panapana. Ko ju bii ọgbọn iṣẹju aaya, nnkan naa kan lọ firi si ibi foonu, o si gbọn foonu bọ lọwọ mi, awa bẹrẹ sini sare kaakiri.
Mo wa ni ki n ṣi ilẹkun ki n wo nnkan to n ṣẹlẹ.
Nigba ti maa ṣi ilẹkun, mo kan rii pe kinni yẹn bu wa si inu ile ni. Oju bẹrẹ sini ta wa, oorun si pọ, mo wa fa awọn ọmọ mi pe ki a ma lọ ku si inu ile".
"Igba ti a maa fi jade, a ko riran mọ, gbogbo ibi lo ti dudu, awọn eeyan ti n sa kaakiri.
Onikaluku tan ina foonu. A ṣaa de geeti wa, awọn kan wa nibẹ ti wọn ti ṣubu, awọn kan wa nibẹ ti ori wọn ti fọ, awọn kan wa nibẹ ti ẹjẹ ti bo mọlẹ".
Arabinrin Ọlanipẹkun fi kun ọrọ rẹ pe awọn gbiyanju lati doola awọn arugbo kan ati awọn ẹlomii ti o fi ara pa ki awọn oṣiṣẹ adoola ẹmi to de.
‘Mo jade lọ, amọ ile mi di aiwọ fun mi mọ nigba ti mo de’

Ni adugbo kan naa, a ba ẹlomii ti iṣẹlẹ naa kan sọrọ. Arakunrin Ọlagoke Ọdia ti ile wọn jẹ ile akọkọ ni ẹnu ọna abawọle adugbo ti iṣẹlẹ naa ti ṣẹlẹ.
O ṣe alaye wi pe oun jade ni nnkan bii aago meje alẹ ọjọ naa, ṣugbọn nigba ti oun yoo fi pada de ni bii aago mọkanla, ni oun rii pe "ile ti oun ti jade ti wo lulẹ, ti gbogbo ẹru inu ile si ni ko ṣe e lo mọ".
Eeyan mẹwaa la ṣi n wa a

Ipade ti awọn onile l'adugbo naa ṣe l'Ọjọru da lori apero lati ṣe onka awọn eeyan ti wọn ṣi n wa lẹyin iṣẹlẹ naa.
Nibi ipade naa ni wọn ti sọ pe eeyan mẹwaa lo si sọnu ti ẹnikẹni ko ri oku tabi aaye wọn lẹyin iṣẹlẹ naa titi di asiko yii.
Bakan naa ni awọn ara adugbo naa ke gbajare wi pe awọn ko mọ ẹni ti o wa ko gbogbo mọto to bajẹ nibi iṣẹlẹ naa ati ibi ti wọn ko wọn lọ.
Aarẹ ẹgbẹ awọn onile ni agbegbe ti ibugbamu ti waye, Arakunrin Muyiwa Bamgbose lo fi idi ọrọ naa mulẹ fun awọn akọroyin.
Bakan naa ni wọn ṣe ifilọlẹ iwe kan lati ṣe atunto agbegbe naa ati lati dẹkun iru iṣẹlẹ aburu naa lọjọ iwaju.













