''Àwọn jàndùkú darandaran àtàwọn tó ń jí màálù ló tún dá rògbòdìyàn sílẹ̀ ní Plateau''

Aworan igberiko ipinlẹ Plateau

Oríṣun àwòrán, Red Cross

Ileeṣẹ ologun ni Naijira ti sọ pe awọn janduku darandaran atawọn to n ji maalu gbe lo wa nidi rogbodiyan to ṣẹṣẹ bẹ silẹ ni ijọba ibilẹ Mangu ni ipinlẹ Plateau.

Ọgagba eto iroyin nile iṣẹ ọmogun, Ọgagun Edward Buba lo fidi ọrọ yii mulẹ ni Ọjọbọ niluu Abuja.

Amọ, ko ṣai sọ wi pe ileeṣẹ ologun to ko awọn sọja lọ si ibi ti rogbodiyan tun ti bẹ silẹ lati daabo bo awọn eeyan.

Ọgagun Buba ni rogbodiyan bẹ silẹ lẹyin tawọn janduku to n ji maalu gbe tun fẹ ji maalu gbe lọ ati bi wọn ti ṣekupa ọkunrin kan ni Mangu.

O ni ọkunrin kan to gun alupupu lo ṣadeedee wọ aarin agbo ẹran ti wọn kọja loju titi lọjọ kejilelogun oṣu kinni ọdun 2024 yii.

Ọgagun Buba ni ‘’lẹsẹkẹsẹ ni wọn ṣekupa ọkunrin naa, lẹyin naa lawọn janduku darandaran ko ara wọn jọ ti wọn si sẹ ikọlu sawọn olugbe ijọba ibilẹ Mangu lọjọ kẹtalelogun oṣu Kinni.’’

Buba tun sọ pe ileeṣẹ ologun yoo ṣe ipade pọ pẹlu alaga ajọ awọn ọmọlẹyin kristẹni, CAN, Ẹniọwọ Timothy Daluk lori ọrọ to sọ pe awọn ologun lo n dari iṣepani awọn ọmọlẹyin kristẹni ati fifi dukia ṣofo ni ipinlẹ Plateau.

O kere tan bii ọgbọn eeyan lo padanu ẹmi wọn ti ọpọ dukia si ṣofo nigba tawọn janduku agbebọn ṣe ikọlu si abule Kwahaslalek ni ijọba ibilẹ Mangu.

Wọn tun ṣe ikọlu si abule Kinat ati Mairana to wa ni ibode ijọba ibilẹ mangu ati Barkin Ladi lalẹ ọjọ kan naa.

Àwọn agbébọn tún ṣekúpa èèyàn 30 ní Plateau; àwọn ọmọdé, obìnrin pọ̀ nínú wọn

Aworan ikọlu ni Plateau

Oríṣun àwòrán, Red Cross

O kere tan ọgbọn eeyan ti obinrin atawọn ọmọde pọ ninu wọn lo ti dero ọrun lẹyin tawọn janduku agbebọn ṣe tun ṣe ikọlu si abule Kwahaslalek ni ijọba ibilẹ Mangu nipinlẹ Plateau.

Aarẹ ajọ to n ri si idagbasoke Mwaghavul, Joseph Gwankat, ṣalaye pe alẹ ọjọ Iṣẹgun ọjọ kẹtalelogun oṣu Kinni ni ikọlu naa waye nigba tawọn olugbe abule naa ko ara wọn jọ pọ sinu ile kan latari ofin konile o gbele to wa ni ijọba ibilẹ Mangu.

O ni ọpọ ile ati dukia ni o ṣofo ninu ikọlu ọhun.

Awọn janduku agbebọn naa tun ṣe ikọlu si abule Kinat ati Mairana to wa ni ibode ijọba ibilẹ Mangu ati Barkin Ladi lalẹ ọjọ Iṣẹgun kan naa.

Awọn kan tun sọ pe yatọ si ikọlu to waye ni Sabon-Gari ati Mangu, awọn janduku agbebọn yii tun ṣe ikọlu sawọn abule mii.

Ileeṣẹ ọlọpaa ti fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ, ọlọpaa ni lootọọ ni wọn ṣe ikọlu si abule Kwahaslalek ti wọn si tun dana sun ọja atawọn ile ijọsin niluu Mangu.

DSP Alfrewd Alabo sọ pe ileeṣẹ ọlọpaa ko tii le sọ ni pato iye eeyan to ku nibi ikọlu ọhun ati dukia to ṣofo, amọ, iwadii si n tẹsiwaju.

DSP Alabo ko ṣai fi da awọn eeayn ipinlẹ Plateau loju pe awọn ẹṣọ eleto abo yoo daabo bo wọn.

O ni nkan ti n pada bọ sipo diẹ diẹ ni Mangu pẹlu bawọn ẹṣọ eleto abo ti pọ nibẹ bayii ati pẹlu bi awọn ẹṣọ naa ṣe n lo ẹlikopita lati maa fi ṣe ami.

Ẹwẹ, ofin konile o gbele to wa ni ijọba ibilẹ Mangu ṣi wa sibẹ.

Ìjọba Plateau kéde kónílé ó gbélé ní Mangu, àwọn ọlọ́pàá yin tajútajú sí àwọn aṣòfin tó fẹ́ fi típátipá gba ìjòkó ilé padà

Iwaju ile aṣofin Plateau

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Afẹfẹ tajutaju ‘tear gas’ ni awọn ọlọpaa fi tu awọn aṣofin ipinlẹ Plateau mẹrindinlogun nibi ti wọn ti n gbero ati wa joko si ile aṣofin ipinlẹ naa lẹyin ti ile ẹjọ ti yẹ aga mọ wọn ni idi pe awọn kọ lo wọle ibo.

Abẹ aṣia ẹgbẹ oṣelu PDP lawọn aṣofin naa ti jade du ipo ti ajọ INEC si kede wọn wọle ki ile ẹjọ to sọ pe ofutufẹtẹ ni ikede naa nitori pe awọn kọ lo wọle si ipo aṣofin ipinlẹ ọhun.

Awọn aṣofin naa gbimọ̀ran lati pada si ile naa lai naani idajọ ile ẹjọ.

Lọwurọ ọjọ Iṣẹgun ni awọn atawọn ololufẹ wọn gunlẹ si gbagede ile aṣofin ipinlẹ naa pẹlu ireti ati darapọ mọ ijoko ile lọjọ naa.

Awọn ọlọpaa atawọn ẹka oṣiṣẹ alaabo miran kun gbogbo ayika ile ijọba ipinlẹ naa nibi ti ile igbimọ aṣofin ipinlẹ naa wa ni ilu Jos ti wọn si di awọn aṣofin naa lọna pe wọn ko le wọle.

Bi awọn aṣofin mẹrindinlogun naa ṣe n faake kọri pe awọn ko ni ibi kankan an re ni awọn ọlọpaa ba tu afẹfẹ tajutaju silẹ nigba ti awọn atawọn ololufẹ wọn fẹ maa da wahala silẹ nibẹ.

atẹjade ti ijọba ipinlẹ Plateau fi sita

Oríṣun àwòrán, others

Ile ẹjọ kotẹmilọrun lo yọ awọn aṣofin naa nipo ni oṣu kọkanla ọdun to kọja

Ile ẹjọ yọ awọn aṣofin naa, titi kan olori ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Plateau, Ishaku Maren lori ẹsun pe ẹgbẹ oṣelu PDP to fa wọn kalẹ ko laṣẹ lati fa oludije kalẹ fun idibo to waye lọdun 2023 ni ipinlẹ Plateau.

Ile ẹjọ naa wa kede awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC mẹrindinlogun ti wọn ṣe ipo keji ni idibo naa lati lọ gba ipo wọn.

Bi o tilẹ jẹ wi pe inu awọn aṣofin naa ko dun si igbesẹ yii, amọṣa igboya de fun wọn lẹyin ti ile ẹjọ to ga julọ lorilẹede Naijiria paṣẹ ninu idajọ to gbe kalẹ lori ibo gomina ni ipinlẹ Plateau kan naa pe Caleb Mutfwang, lati ẹgbẹ oṣelu PDP kan naa ti awọn aṣofin yii ti wa, lo bori ipo gomina.

Ile ẹjọ to ga julọ ni Naijiria ni aṣiṣe gba a ni ile ẹjọ kotẹmilọrun ṣe lati wọgile esi ibo gomina nibẹ.

Ijọba ipinlẹ Plateau kede konile o gbele ọlọjọyipo ni ijọba ibilẹ Mangu

Gomina Caleb Mutfwang

Oríṣun àwòrán, governors plateau state/facebook

Gomina ipinlẹ Plateau, Caleb Mutfwang ti kede konile o gbele ọlọjọyipo ni ijọba ibilẹ Mangu.

Aṣẹ naa bẹrẹ lẹyẹ o ṣọka.

Adari eto iroyin ni ofisi gomina ipinlẹ naa, Gyang Bere ṣalaye ninu atẹjade kan to fi sita pe bi ọrọ abo ṣe ti dẹnu kọlẹ lagbegbe naa lo fa a ti ijọba fi gbe igbesẹ naa.

Atẹjade naa tẹsiwaju lati sọ pe “Gomina Mutfwang gbe igbesẹ naa lẹyin ifikuluku pẹlu awọn ajọ alaabo gbogbo ni ipinlẹ naa”.

Ipenija abo n fojojumọ buru sii ni ipinlẹ Plateau. Koda laipẹ yii ni oniruuru ikọlu ti waye nibẹ eyi to ti sọ eeyan to le ni ọgọrun di ero ọrun ti ọpọ miran si tun fi ara ṣeṣe.