Kí ló wà nínú lẹ́tà tí àwọn ẹgbẹ́ òkùnk̀un tún kọ sí Ákárìgbò Rẹ́mọ?

Aworan Akarigbo Remo

Oríṣun àwòrán, Oba Babatunde Adewale Ajayi/Facebook

Lẹta kan to ni akọle ẹgbẹ okunkun ‘Aye ati Ẹyẹ’ lori lo ti tun gbode kan bayii, eyi ti wọn dari ẹ si Akarigbo Rẹmọ, nipinlẹ Ogun, Ọba Babatunde Ajayi.

Wọn ko yọ awọn ọba yooku ati awọn agbaagba Rẹmọ silẹ pẹlu.

Oṣu kejila ọdun 2023 ni awọn eeyan naa ti kọkọ kọ lẹta si Akarigbo.

Ninu lẹta kinni, ati ikeji to ṣẹṣẹ jade yii, ni wọn ti tọrọ aforiji, wọn si ṣeleri lati dẹkun dida Ṣagamu ati agbegbe rẹ laamu.

Ọjọ Iṣẹgun, ọjọ kẹtalelogun, oṣu Kinni, ọdun 2024 ni wọn kọ lẹta keji.

Iyatọ wo lo wa ninu lẹta keji ati t’akọkọ?

Lẹta keji yii, ẹgbẹ meji ti i ṣe Aye ati Ẹyẹ ni wọn jọ kọ ọ papọ soju kan naa.

Bẹẹ, ọtọọtọ ni wọn kọ ti ọdun to kọja.

Wọn ṣalaye ninu lẹta tuntun yii pe, awọn jọ kọwe naa pọ ki aridaju le wa pe awọn ko ja mọ.

Wọn sọ pe awọn kọ lẹta yii lati ṣeleri lẹẹkan si i pe awọn ko ni i da rogbodiyan silẹ ni Ṣagamu ati agbegbe rẹ mọ.

Wọn lawọn ko lọwọ ninu iku ojiji to pa Oloye Abiọdun Fọlarin, Baṣọrun Akarigbo t’awọn kan pa sinu ile rẹ ni Itunṣokun, Ṣagamu, lọjọ kẹjọ oṣu kin-in-ni ọdun 2024.

EYE AYE

Oríṣun àwòrán, GOOGLE

Àkọlé àwòrán, leta keji

Ki lohun ti Aafin Akarigbo sọ lori awọn lẹta naa?

Baamofin ilẹ Rẹmọ, Ọtunba Bayọ Ọnafuwa, sọ fun BBC Yoruba pe, kabiyesi Akarigbo ko mọ awọn to n kọ lẹta yii, bẹẹ ni ẹnikẹni ko mu lẹta wa a ba wọn laafin.

"Loootọ, ẹ le maa ri lẹta ti wọn kọ orukọ Akarigbo si lori ayelujara, emi naa ri i, ṣugbọn ko si ẹni to mọ awọn to n kọ ọ, a o si le maa ba awọn ti a ko mọ ṣe."

Ọtunba Bayọ Ọnafuwa sọ pe aafin ko le gbe igbesẹ kankan lori rẹ nigba to jẹ awọn to n kọ ọ ko yọju sita.

‘’Ẹyin naa mọ pe ẹnikẹni le kọ ohun to ba wu u lasiko yii, ko gbe e sori ayelujara.

‘’Awọn eleyii ti wọn pe ara wọn lọmọ ẹgbẹ okunkun yii, a o mọ wọn, wọn o si mu lẹta wa s’aafin.’’

Otuna Ọnafuwa tẹsiwaju pe, bi ẹnikẹni ba ṣetan lati tọ ọna alaafia, to ba yọju saafin, awọn ṣetan lati ba a ṣe papọ.

O ni ẹgbẹ yoowu ko jẹ, to ba ṣeleri alaafia to si ṣe e ri soju, ko si bawọn ko ṣe ni i faaye gba a ki alaafia le jọba.

Ki lohun to ti ṣẹlẹ ṣiwaju?

OLOOGBE ABIODUN FOLARIN

Rogbodiyan ọlọkan-o-jọkan to mu ẹmi awọn eeyan lọ, waye ni Ṣagamu lọdun 2023.

Awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun Aye, Ẹyẹ atawọn yooku wọn ni wọn n da wahala naa silẹ bi iroyin ṣe n gbe e.

Wahala naa pọ debii pe ileeṣẹ ọlọpaa Ogun n ko awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun naa logun-lọgbọn ni.

Bẹe ni wọn n ṣafihan wọn ni olu ileeṣẹ ọlọpaa to wa ni Eleweeran, l’Abẹokuta.

Ẹyin wahala naa ni lẹta akọkọ jade nipari oṣu Kejila ọdun to kọja.

Ki wọn too kọ ẹlẹkeeji yii bi oṣu Kinni ṣe n pari lọ.