Ṣé lóòótọ́ ni pé oúnjẹ sọ ọ̀pọ̀ akẹ́kọ̀ọ́ Fáṣítì Covenant dèrò ilé ìwòsàn?

Aworan asia Fasiti Covenant

Oríṣun àwòrán, Intergram/covenantuniversityota

Ọpọ awọn akẹkọọ ile ẹkọ fasiti Covenant to wa niluu Ota nipinlẹ Ogun ni iroyin to jade lọsẹ to kọja salaye pe wọn dero ile iwosan lẹyin ti wọn jẹ ounjẹ kan ti o n run gbogbo wọn ni inu.

Iroyin nipa ounjẹ ti awọn akẹkọọ yii jẹ lo gbode lori ayelujara, ti ọpọ obi ati alagbatọ si ti n sure lọ wo alaafia awọn ọmọ wọn to jẹ akẹkọọ ni Fasiti naa.

Ṣugbọn ṣa, awọn alaṣẹ fasiti naa sọ pe ọrọ ko ri bẹẹ.

Iroyin sọ pe niṣe ni ọpọ awọn akẹkọọ naa n bi, ti wọn si yn agbẹ, eyi to wa pẹlu ara gbigbona.

Awọn alasẹ Fasiti fọhun sita

Awọn alasẹ fasiti Covenant ti atẹjade sita pe ko si nnkan to jẹ pe ọpọ akẹkọọ dero ile iwosan ninu ọgba fasiti.

Atẹjade naa sapejuwe iroyin to n lọ kaakiri ori ayelujara gẹgẹ iroyin ẹlẹjẹ, ti wọn si fọkan awọn obi ati alagbatọ balẹ pe ilera awọn akẹkọọ jẹ awọn alasẹ ile ẹkọ naa logun pupọ.

Ile ẹkọ fasiti Covenant ni, ko si nnkan to se awọn akẹkọọ ninu ọgba fasiti ọhun.

“Alaafia ni awọn akẹkọọ wa wa ati pe bayii a n gbajumọ bi igbaradi fun eto idanwo wọn yọ ṣe lọ ni alaafia, ti wọn yoo si yege.

“A n rọ awọn obi ati alagbatọ lati fọkan wọn balẹ nitori ko si ewu kankan, ki wọn si ma ṣe iye meji nitori alaafia awọn akẹkọọ naa."

Skip Instagram post
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of Instagram post

Bakan naa ni ijọba ipinlẹ Ogun sọ pe iwadii ti n waye lori iroyin ti oun gbọ.

Lasiko to n ba Ileeṣẹ iroyin abẹle, The Punch, sọrọ, kọmisanna fun eto ẹkọ nipinlẹ Ogun, Tomi Coker salaye pe iwadii ti bẹrẹ lori isẹlẹ naa.

Coke ni iroyin naa ti de eti ijọba sugbọn o ṣeese ko jẹ pe iroyin ẹlẹjẹ ni iroyin naa.

“A ni fọnran eyi to jẹ ẹri nigba ti a ṣe abẹwo si ẹka ilera ile ẹkọ naa, ti a yẹ awọn akọsilẹ wọn wo.

“Ẹ lọ fọkanbalẹ, ẹka eto ilera ipinlẹ Ogun yoo se iwadii to tọ.”